Àbójútó ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ni ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè gbà láti pagidínà tàbí dẹ́kun ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá yàgboro.[1][2] Omíyalé lè wáyé látàrí ẹ̀kún omi láti àwọn ojú odò tí wọ́n ti kún lẹ́mú lẹ́mú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kíkọ́ ilé sí ojúnà omi lè ṣokùnfà kí omi ó pàrọ̀ ọ̀nà tí ó ń gbà tẹ́lẹ̀ pàá pàá jùlọ ọ̀gbàrá ńlá lásìkò òjò. Àwọn ọ̀nà tí a lè gbà dẹ́kun ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ni kí a kọ́ àwọn kòtòdaminù tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì gbòòrò dára dára. A sì lè mọ odi gíga sí etídò tàbí etí kòtòdaminù láti lè lé ọ̀gbàrá padà sínú kòtò. A sì lè wo bí ilẹ̀ bá ṣe tẹrí láti ṣètò ìgbòkègbodò ọ̀gbàrá àti odò iṣàn.

Ṣíṣabójútó ọ̀gbàrá a máa jẹ́ ìtura fún ọmọnìyàn pàá pàá jùlọ lásìkò yí tí Ojú ọjọ́ ń yí padà tí òjò sì ń pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. [3]

Àwọn itọ́kasí àtúnṣe

  1. Paoletti, Michele; Pellegrini, Marco; Belli, Alberto; Pierleoni, Paola; Sini, Francesca; Pezzotta, Nicola; Palma, Lorenzo (January 2023). "Discharge Monitoring in Open-Channels: An Operational Rating Curve Management Tool" (in en). Sensors (MDPI) 23 (4): 2035. 10 February 2023. doi:10.3390/s23042035. ISSN 1424-8220. PMC 9964178. PMID 36850632. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=9964178. 
  2. "Flood Control", MSN Encarta, 2008 (see below: Further reading).
  3. "Strengthening climate resilience through better flood management". ReliefWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-04.