Àdéhùn igi aláwọ̀-ewé

Àdéhùn igi aláwọ̀-ewé Archived 2021-11-12 at the Wayback Machine. ní ìwé àdéhùn ìpẹ̀tùsáwọ̀ ìjà ilẹ̀ tí ó kún fún epo-rọ̀ ì àti afẹ́fẹ́ gáàsì ẹnubodè láàárín orílẹ̀ èdè Cameroon àti Nàìjíríà tí wọ́n ń pè ní Bakassi.[1] [2] 1981,[3] Ìjàkú-akátá àwọn ọmọ-oogun láàárín Nàìjíríà àti Cameroon lọ́dún 1994, àti 1996 wáyé ní Bakassi.[1] Wọ́n gbé aáwọ̀ ìjà yìí lọ sílè ẹjọ́ àgbáyé International Court of Justice, tí ilé-ẹjọ́ sìn dá orílẹ̀-èdè Cameroon láre lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 2002.[4] [5]

Àdéhùn igi aláwọ̀-ewé
Àdéhùn igi aláwọ̀-ewé
Signed
Location
Ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2006
Greentree, New York
Signatories Orílẹ̀-èdè Cameroon àti Nàìjíríà
Language Èdè Gẹ̀ẹ́sì

Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2006,Ààrẹ-àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Cameroon, Paul Biya, tọwọ́ bọ ìwé-àdéhùn Àdéhùn igi aláwọ̀-ewé lórí kíkó àwọn ọmọ ológun kúrò àti fífi ẹ̀tọ́ ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún orílẹ̀ èdè Cameroon. Nínú ìwé àdéhùn náà, Wọ́n fún Nàìjíríà ní gbèdeke ọgọ́ta ọjọ́ láti kó àwọn ọmọ-ogun wọn kúrò, pẹ̀lú àfikún ọgbọ́n ọjọ́ mìíràn, bákan náà, wọ́n fún Nàìjíríà ní àǹfààní láti ṣì ní àwọn olórí ìjọba àti ọlọ́pàá wọn ní Bakassi fún ọdún méjì mìíràn.[1]Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ̀lé àṣẹ ìdájọ́ Ilé-ẹjọ́ àgbáyé International Court of Justice, tí ó dá Cameroon láre kí wọ́n máa bá pàdánù ìrànlọ́wọ́ ìlẹ̀-òkèèrè, wọ́ sìn ló àwọn ọmọ ogun wọn kúrò.[6]

Nígbà náà, wọn gbé ìgbìmọ̀ kan tó kún fún aṣojú Nàìjíríà, Cameroon, àjọ àgbáyé UN, Germany, Amẹ́ríkà, Faransé àti orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti ṣàbójútó títẹ̀lé ìwé àdéhùn náà[1]

Lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹjọ ọdún 2013, àjọ kéréje lábẹ́ àjọ àgbáyé, UN, tí ó ń rí sí ààbò United Nations Security Council ṣàlàyé pé òun fara mọ́ ìpẹ̀tùsáwọ̀ náà lọ́jọ́ méjì sí ọjọ́ ìfàlélọ́wọ́ ìlẹ̀ Bakassi.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 Uppsala Conflict Data Program Conflict Encyclopedia, Cameroon, Peace Agreements, http://www.ucdp.uu.se/gpdatabase/gpcountry.php?id=28&regionSelect=2-Southern_Africa# Archived 2014-12-19 at the Wayback Machine.
  2. Implications of the Bakassi conflict resolution for Cameroon, Francis Menjo Baye, 2010, pg. 2, http://www.isn.ethz.ch/Digital-Library/Publications/Detail/?ots591=0c54e3b3-1e9c-be1e-2c24-a6a8c7060233&lng=en&id=119860
  3. Bassey & Oshita. Governance and Border Security in Africa. Malthouse. p. 231. ISBN 9788422071. https://books.google.com/books?id=wYZ6tQG9G9IC&pg=PA231&lpg=PA231&dq=cameroon+nigeria+bakassi+dead+soldiers+1981&source=bl&ots=m4c49HzK0e&sig=QeR2qMvdQNjas_xJpCf0ptISgTM&hl=en&sa=X&ei=I4mIVJP7CsmqggT684KQDg&ved=0CEwQ6AEwCg#v=onepage&q=cameroon%20nigeria%20bakassi%20dead%20soldiers%201981&f=false. Retrieved 10 December 2014. 
  4. Cameroun Bakassi peninsula - No war for oil, 12/11/2002, http://www.socialistworld.net/doc/403
  5. The Land and Maritime Boundary Between Cameroon and Nigeria (Cameroon v. Nigeria: Equatorial Guinea intervening) Archived 2014-11-11 at the Wayback Machine., Judgment, ICJ Reports 2002, p.303
  6. Whitaker Beth (2010). "Compliance among weak states: Africa and the counter-terrorism regime", Review of International Studies, pp639–662
  7. Library of Congress, Cameroon; Nigeria: Bakassi Peninsula Transition Completed, Aug 13 2013, https://www.loc.gov/lawweb/servlet/lloc_news?disp3_l205403677_text