Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Djibouti
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Djibouti wá nì ára àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rànkòrónà 2019 (COVID-19) tí ó ń jà káàkíriayé èyí tí àrùn atẹ́gùn ẹ̀rànkòrónà 2 (SARS-CoV-2) ń fà.[2] Kòkòrò àrùn fáírọ́ọ̀sì yi tànkálẹ̀ dé orílẹ̀-èdè Djibouti ní oṣù kẹta ọdún 2020
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Djibouti | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Djibouti |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, Hubei, China |
Index case | Djibouti |
Arrival date | 14 March 2020 (4 years, 9 months and 3 weeks) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 5,003 (as of 18 July)[1] |
Active cases | 138 (as of 18 July) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 4,809 (as of 18 July)[1] |
Iye àwọn aláìsí | 56 (as of 18 July)[1] |
Ìpìnlẹ̀
àtúnṣeOríṣiríṣi àwọn orílẹ̀-èdè tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bi i alágbára ní àgbáyé ni àwọn ológun wọn ní ibùjókòó ti ológun sí orílẹ̀-èdè Djibouti, lára wọn ni orílẹ̀-èdè China, Faranse, Italy Japan àti United States of America. Ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ tí wọ́n fi múlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Djibouti ni ti ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ológun ti orílẹ̀-èdè Spanish èyí tí ó mú kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ológun lọ sí ìfipamọ́ ní ilé-ogun ti àwọn ológun Faranse tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Djibouti.[3]
Àwọn àkókò tí àrùn yí ń ṣẹ́yọ.
àtúnṣeOṣù Kẹta Ọdún 2020
àtúnṣeNí ọjọ́ kẹjìndínlógún oṣù kẹta, ni ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ ti COVID-19 wáyé ní orílẹ̀-èdè Djibouti látipasẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ológun ti ìlú Spanish ẹni tí ó báwọn dé fún iṣẹ́ Atalanta ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta tí àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún un ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta fihàn pé ó ní àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19.[4] Ọmọ ogun ttí ó ní ìkolù àrùn yí ko i ti ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn olùgbé ní agbèègbè.[5] Orílẹ̀-èdè Spain kéde wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun yi i ni wọn yí ò fipágbé padà sí ìlú wọn.[6] Alágbàṣe kan tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ẹ̀ẹ̀ka tí ó ń rí sí ààbò ti ilé-iṣẹ́ ológun ti ilẹ̀ Amerika èyí tí ó wà ní àgọ́ Lemonnier, tí í ṣe ìpàgọ́ ológun ilẹ̀ Amerika kan ṣoṣo tí ó tóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè Djibouti, ni àyẹ̀wò fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó ní àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní oṣù kanna.[7] Isele ogbon ni won fidi re mule ni opin osu keta.[8]
Oṣù Kẹrin Ọdún 2020
àtúnṣeNí ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, Banki Àgbáyé (World Bank) fi ọwọ́ sí milionu márùn ún dọ́là owó ilẹ̀ Amerika, láti inú àpamọ́ owó pàjáwìrì, fún orílẹ̀-èdè Djibouti gẹ́gẹ́ bí arapa iṣẹ́ àkànṣe fún àmójútó àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Djibouti.[9] Ní ọjọ́ karún ún oṣù kẹrin, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ́yọ ti gòkè lọ sí mọ́kàndínlọ́gọ́ta.[10]
Ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kẹrin, orílẹ̀-èdè Djibouti ṣe àkọsílẹ̀ ẹni àkọ́kọ́ tí àjàkálẹ-àrùn ẹ̀rànkòrónà pa. Àwọn ènìyàn ogóje (140) ni wọn ti kó àrùn COVID-19, nígbà tí àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n ti gba ìwòsàn.[11] Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin, ikọ̀ ọmọ ogun Amerika tí wọ́n wà ní Djibouti kéde ìlera pàjáwìrì fún gbogbo ènìyàn. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹrin, orílẹ̀-èdè Djibouti ni ó ní ìtànkálẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Afirikà.[12] Ìṣẹ̀lẹ̀ kejì tí ó ṣẹlẹ̀ ní àgo Lemonnier ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ ní òpin oṣù kẹrin,[13] eyi ti o fa isemole ailopin.[14]
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 1059 ni ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹrin, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ gòkè lọ sí 1089. Àwọn ènìyàn méjì ló ti jẹ́ aláìsí látipasẹ̀ COVID-19, nígbà tí àwọn ènìyàn 642 ti gba ìwòsàn tí àwọn ènìyàn 445 ṣi n gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ ní òpin oṣù kẹrin.
Oṣù Karùn ún Ọdún 2020
àtúnṣeNí oṣù karùn ún, ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 2265 ni ó ṣẹlẹ̀ èyí tí ó mú kí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ gòkè lọ sí 3354. Iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí lọ sókè sí mẹ́rìnlélógún. Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn gòkè láti 862 lọ sí 1504 tí ó sì wá séku àwọn ènìyàn 1826 tí wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ ní òpin oṣù karùn ún.
Oṣù kẹfà Ọdún 2020
àtúnṣeÀwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 1328 ni ó ṣẹlẹ̀ nínú oṣù kẹfà, eyi tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí wọn múlẹ̀ di 4682. Iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí ti di mẹ́rìnléláàdọ́ta (54). Iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn gòkè láti 3020 lọ sí 4524 tí ó sì wá ṣẹ́ku àwọn ènìyàn 104 tì wọ́n ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́.
Oṣù Keje Ọdún 2020
àtúnṣeÌgbésè Ìjọba láti dáwọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 dúró
àtúnṣeNí ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, orílẹ̀-èdè Djibouti ti kéde pé gbogbo àwọn ọkọ̀ òfurufú tí wọ́n ń rin ìrìn-àjò ni wọ́n má a dádúró bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta.[15] Wọ́n tún dá àwọn ọkọ̀ ojú-irin dúró ní ogúnjọ́ oṣù kẹta.[16] Àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) ti pèsè ohun èlò ààbò ti ara ẹni fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Djibouti.[17] Ìjọba ti kéde títìpa àwọn ilé-ẹ̀kọ́ àti àwọn ibi ìjọsìn ní ọjọ́ kọkàndínlógún àti ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta ní àtèlé. Wọ́n ti kọ́kọ́ kéde ìsémọ́lé fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Djibouti ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta kí ó tó di wípé wọ́n sún un síwájú di ọjọ́ kẹjọ oṣù karùn ún.[18]
Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Johns Hopkins CSSE. "Coronavirus COVID19 (2019-nCoV)" (ArcGIS). Coronavirus COVID-19 Global Cases. Retrieved 12 July 2020.
- ↑ "COVID-19 pandemic in Djibouti". Wikipedia. 2020-05-20. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Djibouti confirms first coronavirus case". The East African. 2020-03-19. Retrieved 2020-07-28.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Latest defence and security news". Janes.com. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Djibouti joins global action to prevent COVID-19 as first case is confirmed in the country - Djibouti". ReliefWeb. 2020-03-18. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Latest defence and security news". Janes.com. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "U.S. Army Halts Training Over Coronavirus but Then Changes Its Mind". The New York Times. 2020-03-26. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Coronavirus in Djibouti increases risk of China debt trap - Nikkei Asian Review". Nikkei Asian Review. 2020-04-26. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Djibouti: World Bank Approves US$5 Million in Urgent Support of Coronavirus Response". World Bank. 2020-04-02. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Ministere de la Santé de Djibouti". Facebook. 2020-07-27. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ Editorial, Reuters (2020-04-09). "Djibouti says records its first coronavirus death - ministry of health". U.S. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Coronavirus surges in Djibouti as population ignores measures". Al Jazeera. 2020-04-24. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "U.S. Military's Hub in Djibouti Works to Keep the Coronavirus Out While Still Fighting Terrorism in Africa". Foreign Policy – the Global Magazine of News and Ideas. 2020-05-01. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Lockdown at US military base in Djibouti as coronavirus spreads". RFI. 2020-04-29. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Djibouti confirms first coronavirus case". The East African. 2020-03-19. Retrieved 2020-07-28.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Djibouti joins global action to prevent COVID-19 as first case is confirmed in the country - Djibouti". ReliefWeb. 2020-03-18. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "Djibouti joins global action to prevent COVID-19 as first case is confirmed in the country - Djibouti". ReliefWeb. 2020-03-18. Retrieved 2020-07-28.
- ↑ "COVID-19 Information". U.S. Embassy in Djibouti. 2020-05-28. Retrieved 2020-07-28.