Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Eritrea

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Ẹritrẹ́à ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta.

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Eritrea
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiEritrea
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, Hubei, China
Index caseAsmara
Arrival date21 March 2020
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn265 (as of 28 July)[1]
Active cases191 (as of 28 July)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá74 (as of 28 July)
Iye àwọn aláìsí
0

Ìpìnlẹ̀

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kíní ọdún 2020, àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) fìdí rẹ múlẹ̀ pé kòkòrò àrùn ẹ̀rànkòrónà ni ó ń fa àrùn atégùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan ní agbègbè Hube, orílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ tí ó ń ri sí ètò ìllera ní àgbáyé ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]

Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ti àrù́n SARS tí ó ṣẹ́yọ ní ọdún 2003[3][4] ṣùgbọ́n bí àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ṣe ń tàn káríayé pọ̀ púpọ̀ ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí.[5]

Àwọn àkókò tí àrùn yí ń ṣẹ́yọ

àtúnṣe

Oṣù Kẹta Ọdún 2020

àtúnṣe

NÍ ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta, ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Eritrea ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ ní Asmara, ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ sí ni ọmọ orílẹ̀-èdè Eritrea tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti orílẹ̀-èdè Norway.[6]

Ìṣẹ̀lẹ̀ márùndínlógún ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ ní oṣù kẹta tí gbogbo wọ́n sì ń gba ìtọ́jú títí di òpin oṣù kẹta yi.

Oṣù Kẹrin Ọdún 2020

àtúnṣe

Orílẹ̀-èdè Eritrea kéde ìsémọ́lé ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejì oṣù kẹrin. Ìsémọ́lé yi ni wọ́n tún ṣe àfikún rẹ síwájú si.[7]

Ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kẹrin, orílẹ-èdè Eritrea ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 tuntun méjì tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn an méjì tí wọ́n ti padà sí orílẹ̀-èdè Eritrea kí ó tó di wípé wọ́n fi òfin de lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ òfurufú. ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí èkejì si jẹ ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta. Àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ti wá kó àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Eritrea di mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.

Àpapọ̀ iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ di mọ́kàndínlógójì ní oṣù kẹrin, èyí tí ó fi mẹ́rìnlélógún ju ìṣẹ̀lẹ̀ ti oṣù kẹta lọ. Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú àwọn aláìsàn mọ́kàndínlógójì gba ìwòsàn ní oṣù kẹrin, ó wá ṣẹ́ku àwọn mẹ́tàlá tí wọ́n ń gba ìtọ́jú ní òpin oṣù kẹrin.

Oṣù Karùn ún Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù karùn ún, Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀-èdè Eritrea fìdí rẹ múlẹ̀ pé ẹni ìkọkàndínlógójì, tí ó tún jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn COVID-19 tí ó gbẹ́yìn ní orílẹ̀-èdè Eritrea, ti gba ìwòsàn pátápátá.[8] Títí di ìparí oṣù karùn ún, kò sí ẹnìkankan tí ó ń gba ìtọ́jú.

Oṣù Kẹfà Ọdún 2020

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹfà, ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ó tún ṣẹ́yọ: ọgbọ̀n nínú àwọn ènìyàn mọ́kànlélọ́gbọ̀n yí ni wọ́n padá dé láti orílẹ̀-èdè Sudan tí ẹnìkan tí ó kù si padá dé láti orílẹ̀-èdè Ethiopia.[9] Ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rìnlélọ́gọ́jọ ni ó ṣẹlẹ̀ nínú oṣù kẹfà, èyí ló mú kí iye àpapọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fìdí rẹ múlẹ̀ láti ìgbàtí àjàkálẹ̀-àrùn yí ti bújáde lọ sókè sí mẹ́tàlénígba. Àwọn aláìsàn mẹ́tàléláàdọ́ta ni wọ́n gba ìwòsàn nínú oṣù kẹfà ó wá ku ààdọ́jo àwọn aláìsàn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú títí di òpin oṣù kẹfà.

Àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19

àtúnṣe

Láti dènà àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19, ìjọba ti rọ àwọn ará ìlú làti má ṣe rin ìrìn-àjò lọ kúrò tàbí wá sí orílẹ̀-èdè Eritrea. Àwọn arìnrìn àjò tí wọ́n ń bọ̀ wá sí orílẹ̀-èdè Eritrea, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè China, Italy, Kòréà Gúúsù tàbí Iran láìpẹ́ yi ni ìjọba ti kọ lọ sí ibi ìfinipamọ́ láti ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2020.[10]

Lára àwọn ìlànà tí ìjọba gbé kalẹ̀ ni láti dènà gbígbé owó lórí àwọn ọjà làkòókò ìsémọ́lé. Àwọn àmúṣe ìgbésẹ̀ yí ni wọ́n ti kéde wọn ní àwọn agbègbè bi i Massawa.[11]

Bí àjàkálẹ̀-àrùn yí ṣe ń pọ̀si, ìjọba pinnu láti jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Eritrea wà ní ìsémọ́lé, wọ́n sì fi òfin de gbogbo ìrìn-àjò àwọn ọkọ̀ òfurufú, tí won kò ṣe pàtàkì, tí wọ́n jẹ́ ti agbègbè àti ti ilẹ̀ òkèèrè.[12] Lákòókò tí wọ́n fi òfin de àwọn ìrìn-àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Eritrea tí wọ́n ń padà bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n kàn án nípá fún láti lọ sí ibi ìfinipamọ́. Láti ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹfà, àwọn ènìyàn 3,405 ni wọ́n ṣì wà níbi ìfinipamọ́ káàkàkiri àwọn ibi ìfinipamọ́ mẹ́tàdínláàdọ́ta tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Eritrea.[13]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Eritrea Coronavirus - Worldometer". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-07-27. 
  2. Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-08-01. 
  3. "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-08-01. 
  4. "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-08-01. 
  5. Higgins, Annabel (2020-08-01). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-08-01. 
  6. Reuters (2020-03-21). "Angola, Eritrea, Uganda confirm first cases as coronavirus spreads in Africa". National Post. Retrieved 2020-08-01. 
  7. Mafotsing, Line (2020-05-14). "Covid-19 and Eritrea’s Response". Kujenga Amani. Retrieved 2020-08-01. 
  8. AfricaNews (2020-07-19). "Eritrea coronavirus: Expats repatriated, caseload at 251". Africanews. Retrieved 2020-08-01. 
  9. "Announcement from the Ministry of Health". 2020-06-14. Archived from the original on 2020-06-14. Retrieved 2020-08-01. 
  10. AfricaNews (2020-07-19). "Eritrea coronavirus: Expats repatriated, caseload at 251". Africanews. Retrieved 2020-08-01. 
  11. Mafotsing, Line (2020-05-14). "Covid-19 and Eritrea’s Response". Kujenga Amani. Retrieved 2020-08-01. 
  12. Hanane, Thamik (2020-06-15). "Eritrea records highest daily increase as 24 new COVID-19 cases confirmed". CGTN Africa. Retrieved 2020-08-01. 
  13. "Eritrea's confirmed COVID-19 cases pass 100-mark - English.news.cn". Xinhua (in Èdè Latini). 2017-03-21. Archived from the original on 2020-06-17. Retrieved 2020-08-01.