Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí "gbogbo" àti "ènìyàn") jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ. Yíyára tànkálẹ̀ àrùn laarin ọ̀pọ̀ ènìyàn ní agbegbè tàbí ẹkùn fún ìwọ̀nba ìgbà diẹ ni wọ́n npe ni "àjàkálẹ̀-àrùn" (epidemic).[1] Ìtànkálẹ̀ àrùn tí ó jẹ́ wípé o ní iye ìwọ̀nba àwọn ènìyàn tí wọ́n ko o ni wọ́n ń pè ní "endemic" ki i se àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé. Àrùn endemic tí ó jẹ́ wípé o ní iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ko o tí kì í ṣe wípé ó tàn kaa kiri bi àjàkálẹ̀-àrùn ti o ma n ṣẹyọ ní àkókò ni a le yà sọ́tọ̀ nítorí pé àwọn àrùn bayi i ma n wáyé leekanna ni àwọn ẹkùn tí ó tóbi ní àgbáyé sùgbọ́n wọ́n ki i ràn kaa kiri àgbáyé.

Àjàkálẹ̀ àrùn ní Florence, ní ọdún 1348

Ìtunmọ̀ àti Ìpele

àtúnṣe

Àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn tí ó ń tàn kaa kiri gbogbo àgbáyé.[2] A kò lè pe àrùn tàbì àìsàn kan ní àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé nítorí pé ó wà kaa kiri tàbí pé o n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; àrùn yí gbọ́dọ̀ jẹ́ àkóràn. Fún àpẹrẹ, àrùn jẹjẹrẹ jẹ́ àrùn kan tí ó ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sùgbọ́n a kò lè pé e ní àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé nítorí pé ki i ṣe àrùn àkóràn tàbí àrùn tí ó lè ran ènìyàn.[3]

Àwọn òṣùwọ̀n tí àjàkálẹ̀-àrùn fi ma n ràn (Nibayi àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé) ma n wá sókè wá sílẹ̀ tí a bá gbe e sí orí àwọ̀nyà láti fi hàn iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fi ara kó àrùn yi ní àkókò kan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni lílọ sókè wá sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn yí ma n wáyé ní àkókò tí àjàkálẹ̀-àrùn yí ba n ràn kaa kiri. A\won àrùn àkóràn ma n sábà a tànkalẹ̀ ní ì̀pele mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú àwọ̀nyà ìsàlẹ̀ yí.

Ìpele ìkínní sẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ohun tí ó tẹ̀ yí. Tí a bá lo títànkàlẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rankòrónà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, eléyì ma a jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ títànkálẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn yí nígbàtí wọ́n bá fi ìdí ìwọ̀nba ìsẹ̀lẹ̀ die múlẹ̀.

Ìpele kejì ohun tí ó tẹ̀ yí n sàlàyé lórí àjàkálẹ̀-àrùn "Ìpele agbègbè"[4]. Èyí ma n wáyé nígbàtí àkóràn àrùn laarin àwọn ènìyàn bá ṣe n pọ si bi àwọn ènìyàn tuntun se n kó àrùn yí.

Ìpele kẹta ohun tí ó tẹ̀ yí n ṣe àfihàn pé wọ́n ko i ti kápá ìbújáde àjàkálẹ̀-àrùn yí tàbí pé ó se é se kí àkóràn àrùn tuntun ma si rárá.

Ìṣàkóso

àtúnṣe

Kò lóùnkà àwọn ìgbéṣẹ̀ ni àwọn Ìpínlẹ̀ le gbe làti dínwọ́ ìbújáde àjàkálẹ̀-àrùn tòkárí-ayé kù. Ní ọdún 2005, àjọ tí ó n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣẹ àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà ètò ìlera káríayé, èyí ti i se ìlànà òfin kan ti yio ṣe ídíwọ́, ìdarí, àti ìjígìrì sí ewu ìlera gbogbo ènìyàn ti o se e se ki o tànkálẹ̀ laarin àwọn orílẹ̀-èdè.[5] Àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization tún ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé aláfọwọ́kọ kan láti kojú àwọn àjàkálẹ̀-àrùn. Àlàyé aláfọwọ́kọ yi ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe àtẹ̀jáde rẹ ní ọdún 1999 tí wọ́n sì ṣe àtúnwò àti ìmúdójúìwọ̀n rẹ ní ọdún 2005 àti ọdún 2009. Èyí tí ó pọ̀jù lọ nínú àwọn ìlànà tí wọ́n lò láti fi kojú àjàkálẹ̀-àrùn kòrónà ni wọ́n mú jáde láti inú àwọn ìlànà ètò ìlera ti àgbáyé ti ọdún 2005 àti àwọn ìtọ́sọ́nà ìgbaradì fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ó jẹ́ ti àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization.

Àpérò nla kan ti wáyé lórí ìlànà "T" méta (Testing, Treatment and Tracing) èyí tí ó gba àwọn orílẹ̀-èdè láàyè láti ṣe àyẹ̀wò oríṣiríṣi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kí ó tó di wípé wọ́n yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú.[6] Ìlànà yí ló ní ṣe pẹ̀lú wíwá gbogbo ènìyàn tí eni tí ó ti fi ara kó àrùn yí ti se alábàpàdé pẹ̀lú kaa kiri kí wọ́n sí yà wọ́n sọ́tọ̀. Ìlànà yí jẹ́ èyí tí wọ́n mọ̀ kaa kiri nítorí àgbékalẹ̀ rẹ ti o múnádóko ní àwọn orílẹ̀-èdè bi i South Korea àti Singapore, bíòtilẹ̀jẹ́pé àwọn orílẹ̀-èdè yí ti wà ní ìmúrasìlẹ̀ tí ó dárajùlọ pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi ìlànà lẹ́hìn jamba tí SARS ti fa.

Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ tàbí ní kúkúrú jíjìnà sí ara ẹni jẹ́ àgbékalẹ̀ fún ìlera gbogbo ènìyàn láti mú kí àrùn àkóràn dínkù nípa ṣíṣe ìdíwọ́ fún àwọn ènìyàn láti súnmọ́ ara wọn nítorí àrùn àkóràn àti àwọn àìsàn tí ó lè ràn wọ́n. Aláṣẹ àti olùdarí, Dokita Michael J. Ryan ti àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World health Organization sọ níbi àpérò kan ní oṣù kẹta ọdún 2019 pe ìjìnnà-síra-ẹni "jẹ́ ìlànà fún ìgbà díẹ̀ láti dín ọwọ́ títànká ẹ̀rankòrónà yí kù ni sùgbọ́n ki i ṣe láti mú ìyanjú wá sí ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀rankòrónà. Lootọ ló jẹ́ wípé ìlànà yí jẹ́ ìlànà ti o na ni lówó sùgbọ́n a gbọ́dọ̀ lo o pẹ̀lú àwọn ìlànà míràn láti wá ìyanjú sí ìṣòro yi. Dokita Riyan sọ kedere pé ìjìnnà-siŕa-ẹni ko le mu àrùn yí kúrò.

Àwọn àjàkálẹ̀-àrùn tọ́kárí-ayé tí ó n ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́

àtúnṣe

HIV/AIDS

àtúnṣe

Bíòtilẹ̀jẹ́pé àjọ tí ó n rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization lo àkọlé "àjàkálẹ̀-àrùn àgbáyé" láti fi ṣe àpèjúwe HIV[7], àrùn yí jẹ́ àjàkálẹ̀-àrùn ti o n tẹ̀lé ìtunmọ̀ ọ̀rọ̀. Láti bí i ọdún 2018, ó tó 37.9 million àwọn éníyán tí wọ́n ti fi arakó àrùn HIV ní gbogbo àgbáyé.[8] Àwọn ènìyàn tí ó tó 770,000 ni ó ti jẹ́ aláìsí látipasẹ̀ àrùn AIDS ní ọdún 2018.[9] Lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹkùn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ sí jù ni ìha ìsàlẹ̀ asálẹ̀ Sahara ní ilẹ̀ Africa. Ní ọdún 2018, ìfojúsùn àrùn HIV tuntun tí ó tó 61% ni ó ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn yí.

Àwọn ẹ̀rankòrónà

àtúnṣe

Àwọn ẹ̀rankòrónà (CoV) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí àrùn tí ó n fa àwọn àìsàn bẹ̀rẹ̀ láti orí otútù títí tí o fí dé orí àwọn àrùn tí ó lágbára bí i Middle East Respiratory Syndroms (MERS-CoV) àti Severe Acute Respiratory Syndroms (SARS-CoV). Ẹ̀yà ẹ̀rankòrónà tuntun tí ó n jẹ́ (SARS-CoV-2) ni ó ń fa àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 tàbí COVID-19.[10] Diẹ nínú àwọn ẹ̀rankòrónà ni Zoonitic, èyí tí ó túnmọ̀ sí wípé wọn ma n ṣe àtagbà láàrín àwọn eranko àti àwọn ènìyàn. Àyẹ̀wò kíkún fi yé wa wípé SARS-CoV jẹ́ èyí tí ó ti ara ológbò civeti civet cats jáde wá sí ara ènìyàn, àti wípé MERS-CoV jáde wá láti ara ràkúnmí wá sí ara ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rankòrónà tí a mò ni wọ́n wa kaa kiri nínú àwọn eranko tí wọn ko i ti ràn mọ́ ẹ̀dá ènìyàn.

Ìwọn ẹ̀rankòrónà tuntun kan èyí tí ìpìlẹ̀ rẹ bẹ̀rẹ̀ ní Wuhan, ní ìgbèríko Hubei, ní orílẹ̀-èdè China, ní òpin oṣù kejìlá ọdún 2019[11] ti fa onírúurú ̀ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn tí atẹ́gùn n gbé kiri tí wọ́n n tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bi i àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 (COVID-19). Gẹ́gẹ́ bi Johns Hopkins University Dashboard[12], o fẹ́rẹ̀ ẹ tó igba(200) àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbèegbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 ti ṣẹlẹ̀ sí, pẹ̀lú àwọn ìbújáde tí ó délédóko tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè United States, Central China, Western Europe, àti Iran.[13] Ní ọjọ́ kọkànlà oṣù kẹta ọdún 2020, àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣe àpèjúwe ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19 gẹ́gẹ́ bi i àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé.[14][15] Láti ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 2020, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kó àrùn ẹ̀rankòrónà ní àgbáyé ti tó 2.63 millino, iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí ti tó 184.249 àti iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn jẹ́ 722.055.[16]

Àkíyèsi àwọn ìbẹ́sílẹ̀

àtúnṣe

Àrùn ibà

àtúnṣe

Àrùn ibà jẹ àrùn tí ó wà ní ibigbogbo ní ẹkùn Tropical àti Subtropical tí ó fi mọ́ àwọn apákan ní orílẹ̀-èdè America, Asia àti Africa. Ní ọdọọdún, ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ibà tí ó ma ń ṣẹlẹ̀ ma n súnmọ́ 350-500 million[17]. Àtakò oogun jẹ́ ìṣòro ti o ń gbèrú si i nípa ìtọ́jú àrùn ibà ní orúndún kọkanlélógún (21st century) nígbàtí ó jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ oogun ibà ni kò ṣiṣẹ́ mọ deede yàtọ̀ sí artemisinins.[18]

Àrùn ibà wọ́pọ̀ ní ìgbàkan ní àwọn apá ilẹ̀ Europe àti ní Àríwá America níbití ó jẹ́ wípé kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yí mọ bayi [19]. Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé àrùn ibà yí lọ́wọ́ nínú ìṣubú ilẹ̀ Ọba Roomu (Roman Empire).[20] Àrùn yí ni wọ́n mọ̀ sí "Roman fever"[21]. Plasmodium flaciparum jẹ́ ǹ kan tí ó di ìrọ́kẹ̀kẹ̀ gidi sí àwọn amúnisìn àti àwọn ènìyàn ìlú bakanna nígbàtí wọ́n ṣe àfihàn rẹ sí àárín àwọn Americas pẹ̀lú ìṣòwò ẹrú.[22]

Àìsàn Spanish

àtúnṣe

Àìsàn Spanish (tí ó wáyé ní ọdún 1018 si ọdún 1920) jẹ́ àkóràn àrùn tí ó ran àwọn ènìyàn tí ó tó 500 million ní gbogbo àgbáyé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó wá látọ̀nà jínjìn bi i Pacific Islands àti Arctic tí ó sì ti pà àwọn ènìyàn bi i ogún sí ọgọ́rùn ún millionu (20-200 million).[23] Àìbíkítà sí àjàkálẹ̀ àrùn yí ṣe ikú pa púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn arúgbó pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìwàláàyè tí ó pọ̀ jùlọ fún àwọn tí ó wà ní àárín, sùgbọ́n àìsàn Spanish yi pa púpọ̀ nínú àwọn àgbà ọ̀dọ́.[24] Iye ènìyàn tí àìsàn Spanish yi pa ju iye ènìyàn tí ó kú nígbà ogun àgbáyé ìkínní. Àìsàn yí pa àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ ní ọ̀sẹ̀ márùndínlọ́gbọ̀n ju àwọn ènìyàn tí àrùn AIDS pa ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n àkọ́kọ́.[25][26] Píparapọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti ibi gbogbo tí ó súnmọ́ ara wọn nígbà ogun àgbáyé íkínní lo fa a ki ìtànkálẹ̀ àrùn yi pọ̀ nítorí àìlágbára àwọn ọmọ jagunjagun lórí àìsàn yí le jẹ o un tí ó pọ̀ nítorí áápọn, àìní ìtọ́jú, àti ìkọlù pẹ̀lú kemikali. [27]. Ètò ìrìnnà tí ó dára si jẹ ki ó tún rọrùn fún àwọn jagunjagun, àwọn atukọ̀ àti àwọn ará ìlú tí ó ń rìnrìn àjò láti tan àrùn yí kaa kiri.[28]

Ìkọ́minú nípa ọjọ́ iwájú àwọn kòkòrò àrùn

àtúnṣe

Òògùn apakòkòrò to n dènà àrùn

àtúnṣe

Àwọn òògùn apakòkòrò ni wọ́n ma n sábà a tọ́ka sí nígbàmíràn gẹ́gẹ́ bi i "Superbus". Ó ṣe é ṣe kí wọ́n tún kó ipa lórí i bí àwọn àrùn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ n kápá lọ́wọ́lọ́wọ́ tún ṣe n fara han. [29]. Fún àpẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ọfee èyí tí agbára ọ̀nà ìwọ̀sàn rẹ kò ṣiṣẹ́ mọ́ jẹ́ ń kan tí ó n kan áwọn onímọ̀ nípa ètò ìlera lóminú.

O fẹ́rẹ̀ to ìdajì millionu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tí ó jẹ́ ti Multidrug-resistant tuberculosis (MDR-TB) tí ẃn fojúsùn pé o n ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún kaa kiri [30]. Orílẹ̀-èdè China àti ti India ni wọ́n ní òṣùwọ̀n ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ga jùlọ nípa Multoidrug-resistant TB.[31] Àjọ ti o n ri sí ètò ìlera ní àgbáyé sọ wípé ó fẹ́rẹ̀ súnmọ́ 50 million àwọn ènìyàn ní àgbáyé tí wọ́n ti kó àrùn MDR-TB pẹ̀lú 79% àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yí tí àwọn òògùn apakòkòrò bi i mẹ́ta tàbí jù bẹẹ lọ kò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú. Ní ọdún 2005, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ MDR-TS tí ó tó 124 ni wọ́n kéde wọn ní orílẹ̀-èdè America.Extensively drug-resistant tuberculosis (XDR TB) ni wọ́n ṣe ìdánimọ̀ re ní ilẹ̀ Africa ní ọdún 2006, lẹhinna ni wọ́n ṣe àwárí rẹ pe ó wà ní ọ̀kàndínláàdọ́ta (49) orílẹ̀ èdè tí ó fi mọ́ ilẹ̀ America. Àjọ ti o n ri sí ètò ìlera ,World Health Organisation ṣe ìṣirò rẹ pé ìṣẹ̀lẹ̀ XDR-TB tí ó tó 40,000 ni ó n ṣẹlẹ̀ ní ọdún [32].

Fún bi i ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn kòkòrò àrùn tí ó wọ́pọ̀ ni staphylococcus, aureus, seerratia marceseens àti Enterococcus tí ó n fa àtakò si onírúurú òògùn apakòkòrò bi i Vancomycin, àti gbogbo àwọn òògùn apakòkòrò bi i aminoglycosides àti cephalosporins. Àwọn kòkòrò tí ó n gbógun ti àwọn òògùn apakòkòrò jẹ́ ọ̀kan lára ̀awọn ǹ kan tó n fa àwọn àrùn tó ní i ṣe pẹ̀lú ìlera. Ní àfikún, àwọn àrùn ti o n gbógun ti òògùn apakòkòrò bi i methicillin-resistant staphylococcus aureus (MRSA) tí ó jẹ́ wípé wọn gbinlẹ̀ ní ǹ kan bi i ọdún mélò ó kan sẹ́yìn, ń ṣe àkóbá fún ẹni tí ó ti ní ìwòsàn tẹ́lẹ̀.

Àwọn kòkòrò ibà tí ń sọ ẹ̀jẹ̀ di omi

àtúnṣe

Ibà sẹ̀jẹ̀domi (viral hemorrhagic fever) jẹ́ àwọn àrùn ti o ma n ràn gidigidi tí wọ́n si n ṣe ikúpani. Àwọn àpẹẹrẹ ni Ebola, Lassa, Rift Valley, Marburg ati Bolivan hemorrhagic. Àwọn àrùn yí ní agbára láti pé kí wọ́n di àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé.[33] Agbára tí àwọn àrùn yí ni láti tètè tànkálẹ̀ di àjàkálẹ́-àrùn tókárí-ayé kò pọ̀ rárá nítorípé títànkálẹ̀ wọn ma nílò ìfarakanra pẹ̀lú ẹnití ó ti ní àrùn yí tẹ́lẹ̀ sùgbọ́n ẹnití ó ní àrùn yí tẹ́lẹ̀ kò ní àkókò púpọ̀ rárá tí yíò fi jẹ́ aláìsí tàbi ki o dùbúlẹ̀ àìsàn tó lágbára. Ìwọ̀nba àkókò tó wà láàrín ẹnití ó ní àrùn yí àti ìgbàtí àmì àrùn yí ma fi ara hàn ma n fún àwọn dọ́kítà laaye láti le tètè fi ẹni bẹ ẹ pamọ́ kí wọ́n sì di i lọ́wọ́ láti ma ba a gbé àrùn yi lọ sí ibòmíràn.

Kòkòrò zika

àtúnṣe

Ìbújáde kòkòrò zika bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2005 tí ó sì n tẹ̀síwájú kíkankíkan ní gbogbo ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2016 pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ju 1.5 million lọ jákè jádò àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ju méjìlá lọ ní ìlú America. Àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣe ìkìlọ̀ pé àrùn zika ní agbára láti di àjàkálẹ̀-àrùn tí yíò tàn ká gbogbo àgbáyé tí wọn kó bá tètè dènà rẹ.[34]

  1. "Principles of Epidemiology: Home - Self-Study Course SS1978". CDC. 2017-04-26. Retrieved 2020-07-13. 
  2. Unit, I.M.I.M.M.P.P.H.C.M.E.C.; Hill, P.E.U.N.C.C. (2008). A Dictionary of Epidemiology. Oxford University Press, USA. p. 4. ISBN 978-0-19-971815-3. https://books.google.com.ng/books?id=3Dr8dyuzvTkC&pg=PR4. Retrieved 2020-07-13. 
  3. "Robot Check". Robot Check. Retrieved 2020-07-13. 
  4. "The three phases of Covid-19 – and how we can make it manageable". The Spinoff. 2020-03-08. Retrieved 2020-07-13. 
  5. "International Health Regulations (2005)". World Health Organization. 2017-03-20. Retrieved 2020-07-15. 
  6. "The 3 T’s model: Hitting the nail on the head". Jordan Times. 2020-04-08. Retrieved 2020-07-13. 
  7. "Data and statistics". WHO. 2020-07-09. Retrieved 2020-07-15. 
  8. "Global HIV & AIDS statistics - 2020 fact sheet". UNAIDS. Retrieved 2020-07-13. 
  9. "UNAIDS data 2019". UNAIDS. 2019-12-04. Retrieved 2020-07-15. 
  10. "Coronavirus Opinion: When a danger is growing exponentially, everything looks fine until it doesn’t". Potato News Today. 2020-03-18. Retrieved 2020-07-15. 
  11. Experts, D. (2020). Quarterly Current Affairs Vol. 2 - April to June 2020 for Competitive Exams. Disha Publications. p. 197. ISBN 978-93-90152-15-5. https://books.google.com.ng/books?id=z5PuDwAAQBAJ&pg=PA197. Retrieved 2020-07-13. 
  12. "ArcGIS Dashboards". Retrieved 2020-07-15. 
  13. "Coronavirus Update (Live): 13,049,106 Cases and 571,807 Deaths from COVID-19 Virus Pandemic". Worldometer. Retrieved 2020-07-13. 
  14. "Director's Speeches - Pan American Health Organization". PAHO/WHO. 2018-02-01. Retrieved 2020-07-13. 
  15. "Coronavirus confirmed as pandemic". BBC News. 2020-03-11. Retrieved 2020-07-13. 
  16. "Coronavirus Update (Live): 13,049,106 Cases and 571,807 Deaths from COVID-19 Virus Pandemic". Worldometer. Retrieved 2020-07-13. 
  17. "Malaria Fact Sheet. No. 94. Updated March 2014 - World". ReliefWeb. 2014-03-31. Retrieved 2020-07-13. 
  18. White, Nicholas J. (2004-04-15). "Antimalarial drug resistance". Journal of Clinical Investigation 113 (8). doi:10.1172/JCI21682. PMID 15085184. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC385418/. Retrieved 2020-07-13. 
  19. Gratz, Norman G. [/core/books/vector-and-rodentborne-diseases-in-europe-and-north-america/CBB3750868705CC457D55918585334D7 "Vector- and Rodent-Borne Diseases in Europe and North America by Norman G. Gratz"] Check |url= value (help). Cambridge Core. doi:10.1017/CBO9780511541896. Retrieved 2020-07-15. 
  20. "DNA clues to malaria in ancient Rome". BBC News. 2001-02-20. Retrieved 2020-07-13. 
  21. "Robert Sallares". Radio National. 2003-10-10. Retrieved 2020-07-15. 
  22. "Center for the Study of the Pacific Northwest". UW Homepage. Retrieved 2020-07-15. 
  23. Taubenberger, Jeffery K.; Morens, David M. (2020-07-15). "1918 Influenza: the Mother of All Pandemics". Emerging Infectious Diseases 12 (1). doi:10.3201/eid1201.050979. PMID 16494711. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC3291398/. Retrieved 2020-07-15. 
  24. Gagnon, Alain; Miller, Matthew S.; Hallman, Stacey A.; Bourbeau, Robert; Herring, D. Ann; Earn, David JD.; Madrenas, Joaquín (2013-08-05). Digard, Paul. ed. "Age-Specific Mortality During the 1918 Influenza Pandemic: Unravelling the Mystery of High Young Adult Mortality". PLoS ONE (Public Library of Science (PLoS)) 8 (8): e69586. doi:10.1371/journal.pone.0069586. ISSN 1932-6203. 
  25. "The 1918 Influenza Pandemic". virus. Retrieved 2020-07-15. 
  26. "Spanish flu facts by Channel 4 news". Google Search. Retrieved 2020-07-15. 
  27. "Robot Check". Robot Check. Retrieved 2020-07-15. 
  28. "1918 Flu Pandemic That Killed 50 Million Originated in China, Historians Say". National Geographic News. 2014-01-24. Retrieved 2020-07-15. 
  29. Li, Bingyun; Webster, Thomas J. (2017-01-16). "Bacteria Antibiotic Resistance: New Challenges and Opportunities for Implant-Associated Orthopaedic Infections". Journal of orthopaedic research : official publication of the Orthopaedic Research Society 36 (1). doi:10.1002/jor.23656. PMID 28722231. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC5775060/. Retrieved 2020-07-15. 
  30. "Health ministers to accelerate efforts against drug-resistant TB". WHO. 2010-12-12. Retrieved 2020-07-15. 
  31. "Bill Gates joins Chinese government in tackling TB 'timebomb'". the Guardian. 2009-04-01. Retrieved 2020-07-15. 
  32. CNN, Patrice Poltzer For (2012-10-16). "Tuberculosis: A new pandemic?". CNN.com. Archived from the original on 2020-10-01. Retrieved 2020-07-15. 
  33. Bibbo, Barbara (2019-05-23). "Fears of Ebola pandemic if violent attacks continue in DR Congo". Al Jazeera. Retrieved 2020-07-15. 
  34. "Zika 'could become explosive pandemic'". BBC News. 2016-01-28. Retrieved 2020-07-15.