Àjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020

Àjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020 tàbí Àjàkáyé-àrùn COVID-19 ni àjàkáyé-àrùn tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín ọdún 2019 sí 2020 tí ò ń tàn káàkiri orílẹ̀-èdè gbogbo àgbáyé lọ́wọ́lọ́wọ́. Kòkòrò àìfojúrí afàìsàn-kòrónà tí ó ń ṣàkóbá fún èémí ọ̀wọ́ kejì (SARS-CoV-2) ló ṣokùnfà àjàkálẹ̀-àrùn náà. Àgbègbè Wuhan, ní ìlú Hubei, ní orílẹ̀-èdè China ní àjàkálẹ̀-àrùn yìí tí kọ́kọ́ fara hàn lóṣù Kejìlá ọdún 2019, tí ó sì ti di nǹkan tí Àjọ Elétò-Ìlera Àgbáyé, World Health Organization tí kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àrùn pàjáwìrì gbogboògbò lágbàáyé tí wọ́n gbọdọ̀ mójú tó. Titi di ọjọ́ kẹwàá oṣù ọdún 2020, ó ti ju ènìyàn 118,000 tí ó ti kó àrùn yìí káàkiri gbogbo àgbáyé, tí 5,800 nínú wọn jẹ èyí tí wọ́n kà sí pé àrùn náà tí wọ̀ wọ́n lára jù.[1] Ó ti ju orílẹ̀-èdè àádọ́fà (115) tó ti kàgbákó ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún yìí, pàápàá jùlọ àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè China, Italy, South Korea àti Iran. Ó ti ju ènìyàn ìgbàlélẹ́gbẹ̀rúnmẹ́rin, 4,200 tí àrùn yìí ti pa ní ìfọnnáfòṣu, ó tó ènìyàn ọgọ́rùn-ún-lé-lẹ́gbẹ̀ta, (3100) tí wọ́n kú ní orílẹ̀ èdè China nìkan, àti ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn káàkiri àwọn orílẹ̀ èdè op kù káàkiri àgbáyé. Bẹ́ẹ̀ náà, ó ti ju ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ẹgbẹ̀rún (64,000) tí wọ́n ti mórí bọ́ nínú àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Ẹ̀rà yìí máa ń ràn láti ara enikan sí ẹlòmíràn nípa èémí amísóde bí a bá ń wúkọ̀ tàbí bí a bá ń sín.[2]

Àjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020

Àkókò tí ènìyàn bá kó àrùn yìí àti ìgbà tí ó máa farahàn sábà máa ń tó Ọjọ́ márùn-ún, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè tó nǹkan bí ọjọ́ méjì sí mẹ́rìnlá.[3] Àwọn àmìn ìfarahàn rẹ̀ sáà a máa ń wá bí, àìsàn ibà, ikọ́ wúwú, àti àìlèmí kánlẹ̀. Ìpeléke àrùn yìí máa ń fà àrùn ẹ̀dọ̀fóró, àti ìnira èémí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àrùn yìí kò gbóògùn kankan. Ṣùgbọ́n ìwádìí ìjìnlẹ̀ ń lọ lórí rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìgbìyànjú láti mójú tó àwọn àmìn ìfarahàn rẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ìwòsàn ń ṣe. Àwọn ọ̀nà tí wọ́n là kalẹ̀ láti dẹ́kun àrùn yìí fífọwọ́ déédé, jíjìnnà sí ara ẹni, pàápàá jùlọ ẹni tí ó bá ń ṣàìsàn tàbí fura sí pé wọ́n ní àrùn yìí àti ìyaraẹnisọ́tọ̀ ẹni tí ó fura pé òun ní àrùn yìí.[4]

Lára àwọn ọ̀nà ìdẹ́kun mìíràn tí wọ́n ń gbà láti dẹ́kun jíjàkálẹ̀ àrùn yìí káàkiri àgbáyé ni dídẹ́kun ìrìn-àjò, ìyà sọ́tọ̀ ẹni-afurasí, òfin kónílé-ó-gbélé, àti títi àwọn ilé-ìwé pa. Àwọn ìlú bíi Hubei lórílẹ̀ èdè China àti gbogbo orílẹ̀ èdè Italy ló wà ní ìyàsọ́tọ̀-àmójútó lọ́wọ́ báyìí, bẹ́ẹ̀ náà òfin kónílé-ó-gbélé ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀ èdè China àti South Korea; bẹ́ẹ̀ náà, àyẹ̀wò fínnífínní ní pápákọ̀-òfuurufú àti ìdíkọ̀ ọkọ̀ ojúrìn;àti ìmọ̀ràn ìrìn-àjò ní ìlú tàbí àgbègbè tí àrùn yìí bá ti ń jàkálẹ̀. Ilé-ìwé títìpa pátápátá ní gbogbo orílẹ̀-èdè tàbí àgbègbè tí àrùn yìí ti ṣẹ́yọ ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, èyí tí ṣe àkóbá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀ọ́dúnrún mílíọ́nù (300 million) àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò àgbáyé.[5] Àkóbá ńlá mìíràn tí Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 yìí ni ìfàsẹ́yìn ètò ọ̀rọ̀-aje àti ìbágbépọ̀,[6][7] bẹ́ẹ̀ náà Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 ti fa ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ìjà-aòfẹ́-ọ-nílùú wá sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China àti àwọn ọmọ ìran ìlà oòrùn Asia, bákan náà ìròyìn òfegè lórí ìkànnì ayélujára nípa Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 àti àwọn aríjẹ-nídìí ìbàjé lórí àjàkálẹ̀ àrùn náà kò gbẹ́yìn.[8][9]

Ìṣẹ̀wọ́ tí àrùn yìí fi ń jàkálẹ̀

àtúnṣe

Titi di ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹta ọdún 2020, ó ti ju ènìyàn 126000 tí ó ti kó àrùn yìí káàkiri gbogbo àgbáyé, Ìwòye wà pé wọn kò jábọ̀ tó bí àrùn yìí ṣe ń ṣọsẹ́ pàápàá jùlọ àwọn tí àmìn ìfarahàn ṣì ṣẹ̀pẹ̀rẹ̀ [10][11]

Ní àtiparí oṣù Kejìlá lọ́dún 2019, àwọn onímọ̀ ìlera kéde pé àìsàn ẹ̀dọ̀fóró ṣẹ́yọ sí àwọn ènìyàn ní Wuhan, lágbègbè Hubei, lórílẹ̀-èdè China ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ ohun tí ó ṣòkùnfà rẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àjàkálẹ̀ àìsàn yìí, wọ́n tọpinpin rẹ̀ ọjà kan tí wọ́n ti wọ́n ń pè ní Huanan Seafood Wholesale Market, wọ́n sìn ṣàkíyèsí pé láti ara zoonotic ní kòkòrò àìfojúrí tí ó ń fa àìsàn náà ti ṢẸ̀ wá. Kòkòrò Àìfojúrí yìí tí ó fa àjàkálẹ̀ àìsàn ni wọ́n ń pè ní SARS-CoV-2, kòkòrò àìfojúrí tuntun tí ó fara pẹ́ kòkòrò àìfojúrí kòrónà láti ara àdán,[12] pangolin coronaviruses[13] and SARS-CoV. Ìgbàgbọ́ wà pé, ó ṣeé ṣe kí kòkòrò àìfojúrí yìí wá láti ara àwọn ẹ̀yà àdán tí wọ́n pè ní Rhinolophus.[14]

Àjàkálẹ̀ àìsàn yìí kọ́kọ́ ṣẹ́yọ ní Ọjọ́ kìíní Oṣù Kejìlá ọdún 2019, láti ara ẹnìkan tí kò dé ọjà oúnjẹ òkun, (Huanan Seafood Wholesale Market) tàbí ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn ogójì àwọn mìíràn tí àyẹ̀wò ọ̀wọ́ àkọ́kọ́ fihàn pé wọ́n ní kòkòrò àìfojúrí náà. Nínú àyẹ̀wò ọ̀wọ́ àkọ́kọ́, ìpín méjì nínú mẹ́ta ni àyẹ̀wò fihàn pé wọ́n ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú wet (wet market), tí ó máa ń ẹran lóòyẹ̀.

Àjọ ìlera àgbáyé World Health Organization (WHO) kéde àjàkálẹ̀ àìsàn náà gẹ́gẹ́ bí àjàkálẹ̀ àrùn gbogboògbò tí ó nílò ìmójútó pàjáwìrì ní ọgbọ̀njọ́ oṣù kìíní ọdún 2020. Olùdarí àjọ ìlera àgbáyé, Who, Ọ̀gbẹ́ni Tedros Adhanom, gbóríyìn fún ìjọba orílẹ̀ èdè China fún akitiyan àti ìgbésẹ̀ wọ́n láti rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn tí kòkòrò àìfojúrí kòrónà ń fà kò tàn kálẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ lórílẹ̀-èdè naa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń jà rànyìnrànyìn ní àwọn àgbègbè orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àrùn yìí, iye àwọn ènìyàn tí ó ń lùgbàdì àìsàn yìí tó ìlọ́po méjì láàárín Ọjọ́ méje àti àbọ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kìíní ọdún 2020, kòkòrò àìfojúrí yìí ti jàkálẹ̀ dé àwọn àgbègbè China, ọdún Chunyun, tí ó jẹ́ ayẹyẹ àìsùn ọdún tuntun ní China, tí wọ́n ṣe ní ìlú Wuhan lo ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n lùgbàdì àìsàn yìí, nítorí pé ìlú Wuhan ni ìlú tí ìgbòkègbodò ọkọ́ tí gbòde jù ní China. Àsìkò yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fara kàṣà àrùn náà.[15] Lógúnjọ́ oṣù kìíní ọdún 2020, orílẹ̀-èdè China kéde ogóje ènìyàn tí wọ́n lùgbàdì àrùn yìí lọ́jọ́ kan ṣoṣo, àti ènìyàn méjì mìíràn ní Beijing, pẹ̀lú enikan ní Shenzhen.

Lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020, àjọ ìlera àgbáyé, WHO kéde ìdí kù nínú àwọn tí ó ń kó àrùn yìí ní China, ṣùgbọ́n tí àjàkálẹ̀ àrùn náà gbìnàyá ní orílẹ̀-èdè Italy, Iran àti South Korea. Iye àwọn ènìyàn tuntun tí ó ń kó àrùn náà ní orílẹ̀ èdè mìíràn tí ju ti China lọ.

Pínníṣín ni iye àwọn ọmọdé tí àyẹ̀wò ti fihàn pé wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn yìí títí di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020. Ìkéde kan láti ọwọ́ àjọ ìlera àgbáyé WHO fihàn pé ìdá 2.4 ni àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ju mọ́kàndínlógún lọ ló ní àrùn COVID-19 yìí káàkiri àgbáyé.[16]

Iye àwọn tó ti kú

àtúnṣe

Láàárín Ọjọ́ mẹ́fà sí mọ́kànlélógójì, tí àmìn àrùn náà ṣẹ́yọ àti àsìkò tí àrùn COVID-19 hànde ni àwọn tí wọ́n lùgbàdì rẹ̀ ń kú, àgbálògbábọ̀, ọjọ́ mẹ́rìnlá .

Titi di ọjọ́ Mẹ́rìnlélogun oṣù kẹjọ ọdún 2020, ó ti ju ènìyàn 800,000 tí àrùn COVID-19 tí pá. Gẹ́gẹ́ bí NHC tí orílẹ̀ èdè China tí sọ, àgbàlagbà ni ó pọ̀jù nínú àwọn tí àrùn náà pa. Ó tó ìdá ọgọ́rin, 80% àwọn àgbàlagbà tí ọjọ́-orí ti kọjá ọgọ́ta tó kú, àti ìdá márùndínlọ́gọ́rin àwọn tí wọ́n ti ní àìsàn mìíràn lára tẹ́lẹ̀, pàápàá jùlọ àìsàn ọkàn, cardiovascular diseases àti itọ̀ ṣúgà, diabetes.

Ẹni àkọ́kọ́ tí àìsàn yìí pa kú lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kìíní ọdún 2020 ní ìlú Wuhan. Ẹlòmíràn tó kú ní orílẹ̀ èdè mìíràn yàtọ̀ sí China kú ní orílẹ̀-èdè Philippines, ẹlòmíràn tí ó tún kú, tí kì í ṣe láti ilẹ̀ Asia kú ní Faransé. Lẹ́yìn China, ó ti ju ènìyàn méjìlá. Mẹ́jìlá lọ tí wọ́n ti kú ní Iran, South Korea, àti Italy. Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ìròyìn tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n tí kú ikú àrùn kòrónà apá àríwá Amẹ́ríkà (North America), Australia, San Marino, Spain, Iraq, àti United Kingdom.[17] Ìwé ìròyìn Daily NK jábọ̀ pé àwọn ọmọ-ogun tó ti ju igba (200) ni àrùn kòrónà ti pa lórílẹ̀-èdè North Korea.[18]

Àwọn àmìn àti ìfarahàn

àtúnṣe
Symptom %
Ìbà 87.9%
Ikọ́ àwúgbẹ 67.7%
Àìlókun 38.1%
Sputum production 33.4%
Àìlèmí kanlẹ̀ 18.6%
Muscle pain or joint pain 14.8%
Sore throat 13.9%
Ẹ̀fọ́rí 13.6%
Chills 11.4%
Èébì 05.0%
kàtá 04.8%
Ìgbẹ́ gbuuru 03.7%
Haemoptysis 00.9%
Conjunctival congestion 00.8%
 
COVID-19 symptoms

Kòsí àmìn kan pàtó tí kòkòrò àìfojúrí kòrónà, COVID-19 máa ń gbé yọ lára ẹni tí ó bá kó o. Àwọn tí ó bá kó o lè máa ní àmìn kankan tàbí kí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàìléra bí i ikọ́, ibà, àìlèmí kanlẹ̀, ara riro, àìlókun, àwọn àmìn àti ìfarahàn rẹ̀ ló wà nínú tábìlì yìí.l.

Bí àrùn yìí bá ti ń peléke, ó máa ń fà àrùn ẹ̀dọ̀fóró, ìnira láti mí, ìjayà àti ikú. Ìwádìí tí fihàn gbangba pé àwọn mìíràn lè ní àrùn yìí láìsí àmìn tàbí Ìfarahàn kankan, nítorí ìdí èyí ni àwọn onímọ̀ ìlera gbà á ní lmọ̀ràn pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ti sún mọ́ enití àyẹ̀wò fihàn pé ó ní àrùn náà gbọ́dọ̀ wà ní ìmójútó láti ríi dájú pé kò lùgbàdì àrùn náà.[20]

Àsìkò ìyàsọ́tọ̀ fún ẹni tí ó bá kó àrùn náà àti ìgbà tí àwọn àmìn rẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde máa ń tó ọjọ́ kan sí mẹ́rìnlá, ọjọ́ márùn-ún ló sáà à máa ń jẹyọ jù. In one case, it had an incubation period of 27 days. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, àrùn COVID-19 kìí ní àmìn ìfarahàn lára ẹlòmíràn.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Coronavirus Update (Live) for COVID-19 Wuhan China Virus Outbreak – Worldometer". www.worldometers.info. 
  2. "Getting your workplace ready for COVID-19" (PDF). World Health Organization. 27 February 2020. 
  3. Rothan, Hussin A.; Byrareddy, Siddappa N. (26 February 2020). "The epidemiology and pathogenesis of coronavirus disease (COVID-19) outbreak". Journal of Autoimmunity: 102433. doi:10.1016/j.jaut.2020.102433. ISSN 0896-8411. PMID 32113704. http://www.sciencedirect.com/science/article/pii/S0896841120300469. 
  4. "Coronavirus Disease 2019 (COVID-19)". Centers for Disease Control and Prevention (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 11 February 2020. Retrieved 9 March 2020. 
  5. "Coronavirus impacts education". UNESCO (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 4 March 2020. Retrieved 7 March 2020. 
  6. "Here Comes the Coronavirus Pandemic – Now, after many fire drills, the world may be facing a real fire.". The New York Times. 29 February 2020. https://www.nytimes.com/2020/02/29/opinion/sunday/corona-virus-usa.html. Retrieved 1 March 2020. 
  7. Krugman, Paul (27 February 2020). "When a Pandemic Meets a Personality Cult". The New York Times. https://www.nytimes.com/2020/02/27/opinion/coronavirus-trump.html. Retrieved 29 February 2020. 
  8. Perper, Rosie (5 March 2020). "As the coronavirus spreads, one study predicts that even the best-case scenario is 15 million dead and a $2.4 trillion hit to global GDP". Business Insider. https://www.yahoo.com/news/coronavirus-spreads-one-study-predicts-101552222.html. 
  9. Clamp, Rachel (5 March 2020). "Coronavirus and the Black Death: spread of misinformation and xenophobia shows we haven't learned from our past". The Conversation. https://www.yahoo.com/news/coronavirus-black-death-spread-misinformation-143713853.html. 
  10. Li, Ruiyun; Pei, Sen; Chen, Bin; Song, Yimeng; Zhang, Tao; Yang, Wan; Shaman, Jeffrey (2020). "Substantial undocumented infection facilitates the rapid dissemination of novel coronavirus (COVID-19)". Medrxiv: 2020.02.14.20023127. doi:10.1101/2020.02.14.20023127. https://www.medrxiv.org/content/10.1101/2020.02.14.20023127v1. 
  11. Sun, Haoyang; Dickens, Borame Lee; Chen, Mark; Cook, Alex Richard; Clapham, Hannah Eleanor (2020). "Estimating number of global importations of COVID-19 from Wuhan, risk of transmission outside mainland China and COVID-19 introduction index between countries outside mainland China". Medrxiv: 2020.02.17.20024075. doi:10.1101/2020.02.17.20024075. https://www.medrxiv.org/content/10.1101/2020.02.17.20024075v1. 
  12. "Another Decade, Another Coronavirus". New England Journal of Medicine 382 (8): 760–62. January 2020. doi:10.1056/NEJMe2001126. PMID 31978944. 
  13. Àdàkọ:Cite biorxiv
  14. "Transmission of Covid-19 may have begun in November". Fiocruz. 
  15. WHO-China Joint Mission (16–24 February 2020). "Report of the WHO-China Joint Mission on Coronavirus Disease 2019 (COVID-19)" (PDF). World Health Organization. Retrieved 8 March 2020. 
  16. Report of the WHO-China Joint Mission on Coronavirus Disease 2019 (COVID-19) (Report). World Health Organization. 2020. https://www.who.int/docs/default-source/coronaviruse/who-china-joint-mission-on-covid-19-final-report.pdf
  17. "Tracking coronavirus: Map, data and timeline". BNO News. 18 February 2020. Retrieved 1 March 2020. 
  18. Joo, Jeong Tae (9 March 2020). "Sources: Almost 200 soldiers have died from COVID-19". Daily NK. Retrieved 10 March 2020. 
  19. The Novel Coronavirus Pneumonia Emergency Response Epidemiology Team. The Epidemiological Characteristics of an Outbreak of 2019 Novel Coronavirus Diseases (COVID-19) – China, 2020. China CDC Weekly, 2020, 2(8): 113–122.
  20. "Clinical Characteristics of Coronavirus Disease 2019 in China". The New England Journal of Medicine. February 2020. doi:10.1056/NEJMoa2002032. PMID 32109013.