Àjàkáyé-àrùn COVID-19 ní Áfríkà

Lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kejì ọdún 2020 ni Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 kọ́kọ́ ṣẹ́yọ nílẹ̀ Áfíríkà. Orílẹ̀ èdè Íjíbítì ni ó sì ti kọ́kọ́ ṣẹ́yọ,[3][4] tí àkọ́kọ́ tí ó ṣẹ́yọ lápá iwọ̀-oòrùn Áfíríkà ṣẹ́yọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[5] Púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n kó àrùn náà kó o láti ilẹ̀ òkèèrè ní Europe àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kì í ṣe orílẹ̀-èdè China tí àrùn ti kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ ni wọ́n ti kó o.[6] Ìgbàgbọ́ wà pé ìròyìn nípa àjàkálẹ̀ àrùn náà ní Áfíríkà kò fi bẹ́ẹ̀ dunlẹ̀ tó tàbí kúnjú òṣùwọ̀n bí àjàkálẹ̀ àrùn náà ṣe ń jà rànyìnrànyìn sí nítorí àìsí àwọn ohun èròjà ìlera tó péye.[7]

COVID-19 pandemic in Africa
Map of the 2020 COVID-19 pandemic in Africa as of 22 July 2020
  100,000+ Confirmed cases
  10,000–99,999 Confirmed cases
  1,000–9,999 Confirmed cases
  100–999 Confirmed cases
  10–99 Confirmed cases
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiÁfíríkà
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, Hubei, China
Index caseCairo, Egypt
Arrival dateỌjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì ọdún 2020 (14 February 2020)
(4 years, 8 months, 2 weeks and 5 days ago)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn770,175 [1]
Active cases325,922[1]
Iye àwọn tí ara wọn ti yá408,788[2][1]
Iye àwọn aláìsí
16,446 [1]
Territories
54[2][1]

Àwọn onímọ̀ kẹ́dùn pé àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 lè ba nǹkan jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní Áfíríkà nítorí àìsí àwọn irinṣẹ́ àti ètò ìlera tó péye nílẹ̀ náà, wọ́n ní àwọn ìṣòro bí i, àìsí àwọn irinṣẹ́ àti ètò ìlera tó péye, àìlówó tó, àìní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó péye fún àwọn oṣìṣẹ́ ìlera, àti àìsí àkọsílẹ̀ tó péye fún àmúlò. Ìbẹ̀rù wà pé yóò nira láti dẹ́kun tàbí mójútó àjàkálẹ̀ àrùn ní Áfíríkà, èyí sìn lè fa ìṣòro ńlá fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wọ́n bí àrùn náà bá tàn kálẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.[8][6]Lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin, àwọn ẹ̀rọ́-amúnimí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní di ọ̀wọ́n gógó káàkiri Áfíríkà: ẹgbẹ̀rún méjì, (2000) péré ẹ̀rọ́-amúnimí ni ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè ókàndínlógójì (41), tí orílẹ̀ èdè mẹ́wàá kò ní ẹ̀rọ yìí rárá. Kódà, ọ̀wọ́n nǹkan èlò bí i ọṣẹ, àti omi yóò wọ́n láwọn orílẹ̀-èdè Áfríkà mìíràn.[9]

Ọ̀gbẹ́ni Matshidiso Moeti ti àjọọ ìlera àgbáyé, World Health Organization sọ wípé owó fífọ̀ àti Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ lè jẹ́ ìṣòro ní àwọn apá kan ní Áfíríkà. Ìsémọ́lé lè máa ṣeé ṣe, tí ìṣòro náà tún lè burú sí i nítorí àwọn àrùn bí í, àrùn ibà, àrùn kògbóògùn éèdì , ikọ́ fée, àti àrùn onígbáméjì.[8] Àwọn olùmọ̀ràn sọ pé, ṣíṣe àyẹ̀wò lè ran àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà lọ́wọ́ láti ṣe àdínkù ìsémọ́lé tí ó lè fa ìṣòro fún àwọn oníṣẹ́ òòjọ́ tí wọ́n gbójúlé iṣẹ́ òòjọ́ láti jẹun àti láti bọ́ ẹbí àti ará wọn. Yàtọ̀ sí èyí, ó ṣeé ṣe kí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 fa iyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà .[10] Àjọ àgbáyé, United Nations sọ wípé, bí wọ́n bá tilẹ̀ mójú tó àjàkálẹ̀ àrùn yìí dáadáa, ó kéré jù, àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn bí i mílíọ̀nùmẹ́tàléníbílíọ́nùkan (1.3 billion) tí wọ́n wà Áfíríkà yóò nílò irinṣẹ́ àyẹ̀wò Covid-19 tí yóò tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (74), pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọọ̀n ẹ̀rọ amúnimí lọ́dún 2020.[11] Bẹ́ẹ̀, àjọ World Health Organization ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà láti dá ibi àyẹ̀wò sílẹ̀.[8] Ọ̀gbẹ́ni Matshidiso Moeti ti àjọọ ìlera àgbáyé, World Health Organization sọ wípé: "A níláti ṣe àyẹ̀wò, àwárí, ṣe ìyàsọ́tọ̀ àti ìtọ́jú".[12]Wọ́n tí ṣe àgbékalẹ̀ oríṣiríṣi ọ̀nà láti dènà jíjàkálẹ̀ àrùn náà ní ilẹ̀ Áfíríkà, lára àwọn ìgbésẹ̀ Ìdènà náà ni ìgbégidínà ìrìn àjò, ìgbégidínà ìrìnkèrindò ọkọ̀ òfuurufú, fífagilé àwọn ètò lọ́lọ́kanòjọ̀kan,[13] títí àwọn ilé-ìwé àti àwọn ẹnu ibodè .[14] Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ sọ wípé, ìmọ̀ nípa ṣíṣẹ́gun àrùn ebola ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè láti gbaradì fún Covid-19 Experts say that experience.[8][13][15]

Lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù karùn-ún ọdún 2020, Lesotho jẹ́ orílẹ̀-èdè Áfíríkà tí ó kéde ẹni tí ó ní àrùn Covid-19 kẹ́yìn;[16][17] kò sí ìkéde àrùn náà ní agbègbè British Indian Ocean Territory, French Southern Territorieslọ àti Saint Helena.

Lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ó ti ju ìdajì àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà tí jíjàkálẹ̀ àrùn yìí tí rápálá ràn láàárín ìlú, lóòótọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àǹfààní láti ṣe àyẹ̀wò fún àwọn ènìyàn dáadáa.[18]

Lọ́sẹ̀ kejì oṣù kẹfà,àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ti kó àrùn Covid-19 ní Áfíríkà ti ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba (200,000) lọ. Àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn náà ń pọ̀ sí lójooojúmọ́, ó gba ilẹ̀ Áfíríkà ní ọjọ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98)láti kéde ẹni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún tí wọ́n ti kó àrùn náà, lẹ́yìn náà, ó gbà Áfíríkà ní ọjọ́ méjìdínlógún péré mìíràn láti kéde àwọn ènìyàn mìíràn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mìíràn.

Íṣe ni iye àwọn ènìyàn tí wọ́n kó àrùn náà ń pọ̀ si, bí ó ti gba ilẹ̀ adúláwọ̀ ní ọjọ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún péré láti kéde ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún àkọ́kọ́ tí wọ́n kó àrùn náà, tí ó sìn jẹ́ pé ọjọ́ méjìdínlógún péré mìíràn láti kéde ọ̀wọ́ kejì ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn mìíràn tí wọ́n kó àrùn náà. Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kó àrùn náà ń pọ̀ sí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fi jẹ́ pé àpapọ̀ iye tí wọ́n ní àrùn náà pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dùnrún (300,000) àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó (400,000) ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù keje, àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní àrùn Covid-19 ní Áfíríkà tí kọjá ìdajì mílíọ̀nù kan lọ.

Àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn náà ni orílẹ̀ èdè márùn-ún ni wọ́n jẹ́ ìdá àádọ́rin (70%)àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ní àrùn náà ní Áfíríkà: àwọn orílẹ̀ èdè náà ni, South Africa , Egypt, Nàìjíríà , Ghana àti Algeria.[19]

Lóṣù kẹfà ọdún 2020, ìròyìn sọ pé, ó ṣeé ṣe kí Áfíríkà jẹ́ ibi tí àrùn Covid-19 yóò ti máa jàkálẹ̀ jùlọ ní àgbáyé, tí ìdàjì àbọ̀ mílíọ̀nù àwọn tí wọ́n ní í wá láti South Africa àti Egypt.[20] Ten countries account for 80% of the reported cases.[20]

Lógúnjọ́ oṣù keje ọdún 2020, àjọ World Health Organisation gbé e pòyẹnu pé pé bí àrùn náà ṣe ń ràn káàkiri ní orílẹ̀ èdè South Africa tó banilẹ́rù, pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣe àkóbá àjàkálẹ̀ àrùn náà tí yóò kó gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà sí wàhálà àjàkálẹ̀ àrùn náà sí i.[21]

Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n kó àrùn náà

àtúnṣe

Àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n kéde pé wọ́n ní àrùn náà ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan

àtúnṣe

Iye àwọn tí wọ́n ní àrùn náà lóòjọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà tí ń jàkálẹ̀ jùlọ:

Àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní àrùn náà láti ìgbà tí ó ti bẹ́ sílẹ̀


Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "Coronavirus update (live)". Retrieved 17 July 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 "Coronavirus in Africa tracker". BBC News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 21 July 2020. Retrieved 2020-07-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Beijing orders 14-day quarantine for all returnees". BBC News. 15 February 2020. https://www.bbc.com/news/world-asia-china-51509248. Retrieved 24 March 2020. 
  4. "Egypt announces first Coronavirus infection". Egypt Today. https://www.egypttoday.com/Article/1/81641/Egypt-announces-first-Coronavirus-infection. Retrieved 24 March 2020. 
  5. "Nigeria confirms first coronavirus case". BBC News. 28 February 2020. https://www.bbc.com/news/world-africa-51671834. Retrieved 24 March 2020. 
  6. 6.0 6.1 Maclean, Ruth (17 March 2020). "Africa Braces for Coronavirus, but Slowly". The New York Times. https://www.nytimes.com/2020/03/17/world/africa/coronavirus-africa-burkina-faso.html. Retrieved 25 March 2020. 
  7. Jason Burke; Abdalle Ahmed Mumin (2 May 2020). "Somali medics report rapid rise in deaths as Covid-19 fears grow". The Guardian. https://www.theguardian.com/world/2020/may/02/somali-medics-report-rapid-rise-in-deaths-as-covid-19-fears-grow. 
  8. 8.0 8.1 8.2 8.3 "African Countries Respond Quickly To Spread Of COVID-19" (in en). NPR.org. https://www.npr.org/sections/goatsandsoda/2020/03/21/818894991/african-countries-respond-quickly-to-spread-of-covid-19. Retrieved 23 March 2020. 
  9. Maclean, Ruth; Marks, Simon (18 April 2020). "10 African Countries Have No Ventilators. That's Only Part of the Problem.". The New York Times. https://www.nytimes.com/2020/04/18/world/africa/africa-coronavirus-ventilators.html. Retrieved 20 April 2020. 
  10. Picheta, Rob. "Coronavirus pandemic will cause global famines of 'biblical proportions,' UN warns". CNN. Retrieved 2020-07-13. 
  11. Burke, Jason (2020-04-26). "'It's just beginning here': Africa turns to testing as pandemic grips the continent" (in en-GB). The Observer. ISSN 0029-7712. https://www.theguardian.com/world/2020/apr/26/its-just-beginning-here-africa-turns-to-testing-as-pandemic-grips-the-continent. 
  12. "New WHO estimates: Up to 190 000 people could die of COVID-19 in Africa if not controlled". WHO | Regional Office for Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-07. Retrieved 2020-05-09.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. 13.0 13.1 "Here are the African countries with confirmed coronavirus cases". CNN. https://www.cnn.com/2020/03/09/africa/nigeria-coronavirus-cases-intl/index.html. Retrieved 24 March 2020. 
  14. "UN Sees Africa Sliding Into Recession Without Debt-Service Help" (in en). Bloomberg.com. 24 March 2020. https://www.bloomberg.com/news/articles/2020-03-24/un-sees-africa-sliding-into-recession-without-debt-service-help. Retrieved 25 March 2020. 
  15. Moore, Jina (15 May 2020). "What African Nations Are Teaching the West About Fighting the Coronavirus". The New Yorker (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 21 May 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. "Remote Lesotho becomes last country in Africa to record COVID-19 case" (in en). Reuters. 2020-05-13. https://www.reuters.com/article/us-health-coronavirus-lesotho-idUSKBN22P1R4. 
  17. "Coronavirus live updates: Lesotho becomes last African nation to report a coronavirus case". Los Angeles Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 13 May 2020. Retrieved 2020-05-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. Akinwotu, Emmanuel (2020-05-26). "Experts sound alarm over lack of Covid-19 test kits in Africa". The Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 29 May 2020. Retrieved 2020-05-29.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  19. "Global report: WHO warns of accelerating Covid-19 infections in Africa". the Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-12. Archived from the original on 12 June 2020. Retrieved 2020-06-12.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  20. 20.0 20.1 "Coronavirus: How fast is it spreading in Africa?". news.yahoo.com. Archived from the original on 7 July 2020. Retrieved July 8, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  21. "Covid-19: Situation in SA 'a warning' for the rest of the continent - WHO". News24 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-07-21.