Àjẹsára àrùn dìgbòlugi

Àjẹsára àrùn dìgbòlugi jẹ́ àjẹsára tí à ń lò láti fi dènà àrùn dìgbòlugi.[1] Àwọn oríṣiríṣi wọn wà tí a lè lò láìséwu, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ bó ti yẹ. A lè lò wọ́n láti fi dènà àrùn dìgbòlugi ṣáájú tàbí fún àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti wà ní sàkání ibití kòkòrò àrùn rẹ̀ gbé wà, bíi kí ajá tàbí àdán gé ni jẹ. Agbára àti kojú àìsàn tí ènìyàn yóò ní jẹ́ èyítí yóò pẹ́ títí lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti gba ìwọ̀n egbògi náà mẹ́ta. A má a ń sábà fún ni ní àwọn àjẹsára náà nípasẹ̀ abẹ́rẹ́ tí a ń gún sínú awọ tàbí ẹran ara ẹni. Lẹ̀yìn tí ènìyàn bá ti wà ní sàkání ibití kòkòrò àrùn rẹ̀ gbé wà, a má a ń sábà gba àjẹsára náà pẹ̀lú àwọn àkóónú inú ẹ̀jẹ̀ tí ngbógun ti àwọn kòkòrò àrùn nínú ara ti àrùn dìgbòlugi. A gba ni níyànjú láti fún àwọn tó wà lábẹ́ ewu wíwà ní sàkání ibití àrùn náà gbé wà ní àjẹsára kí wọ́n tó lọ sí irú sàkání bẹ́ẹ̀. Àwọn àjẹsára náà a má a ṣiṣẹ́ lára ènìyàn àti lára àwọn ẹranko mìíràn. Gbígba àjẹsára fún ajá jẹ́ ìgbésẹ̀ tó lágbára láti dènà àrùn náà lára ènìyàn.[1]

Àjẹsára àrùn dìgbòlugi

A lè lò wọ́n láìséwu fún ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ọjọ́-orí yòówù. Iye àwọn ènìyàn tó tó 35 sí 45 nínú ọgọ́ọ̀rún a má a ní ìrírí pípupa yòò àti dídunni ojú ibi abẹ́rẹ́ náà fún ìwọ̀n ìgbà díẹ́. Iye àwọn ènìyàn tó tó 5 sí 15 nínú ọgọ́ọ̀rún lè ní ibà, ẹ̀fọ́rí, tàbí kí èébì má a gbé wọn. Lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti wà ní sàkání ibití ènìyàn ti lè kó àrùn dìgbòlugi, kò sí ohun tó ní kí ènìyàn má gba àjẹsára náà. Púpọ̀ lára àwọn àjẹsára náà kò ní ohun ti a n pè ní thimerosal nínú. Àwọn àjẹsára tí a ṣe pẹ̀lú iṣan-ara ni à ń lò ní àwọn orílẹ̀-èdè méèló kan, pàápàá ní Éṣíà àti Latin Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n agbára wọn kò pọ̀ púpọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àtúnbọ̀tán wọn pọ̀ púpọ̀. Nítorí náà ni Àjọ Ìlera Àgbáyé kò ṣe gba ni nímọ̀ràn láti má a lò wọ́n.[1]

Àìmọye ènìyàn káàkiri àgbáyé ni a ti fún ní àjẹsára náà, a sì mọ̀ pé èyí a má a dáàbò bo iye àwọn ènìyàn tó ju 250,000 lọ lọ́dún.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé (World Health Organization), àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[2] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ 44 sí 78 USD fún ètò ìtọ́jú lẹ́ẹ̀kanṣoṣo ní ọdún 2014.[3] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ètò ìtọ́jú lẹ́ẹ̀kanṣoṣo ti àjẹsára dìgbòlugi jú 750 USD lọ.[4]

References

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 "Rabies vaccines: WHO position paper" (PDF).
  2. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  3. "Vaccine, Rabies"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].
  4. Shlim, David (June 30, 2015).