Àjẹsára àrùn onígbáméjì

Àwọn àjẹsára àrùn onígbáméjì jẹ́ àwọn àjẹsára tó ní agbára láti dènà àrùn onígbáméjì.[1] Ìwọ̀n agbára wọn tó bíi 85% ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí ènìyàn gbà wọ́n, àti 50–60% lẹ́yìn ọdún kan.[1][2][3] Ìwọ̀n agbára wọn a má a dínkù sí ìwọ̀n tó kéré sí 50% lẹ́yìn ọdún méjì. Bí a bá ti fún iye àwọn ènìyàn tó pọ̀ púpọ̀ láàárín àwùjọ kan ní àjẹsára náà, ànfàní tó wà nínú ààbò lọ́wọ́ àrùn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àwùjọ kan ní lè wáyé láti dáàbò bo àwọn tí kò tíì gba àjẹsára náà. Àjọ Ìlera Àgbáyé gba ni nímọ̀ràn láti lò wọ́n pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tí a lè gbé fún àwọn tó wà lábẹ́ ewu ńlá láti kò àrùn náà. Ìwọ̀n egbògi náà méjì tàbí mẹ́ẹ̀ta, tí à ń gba ẹnu lò, ni a má a ń sábà dámọ̀ràn.[1] Àwọn oríṣi tí a lè fún ni bí abẹ́rẹ́ náà wà ní àwọn agbègbè kan ní àgbáyé ṣùgbọ́n wọn kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.[2][1]

Àwọn ènìyàn tó ń gba àjẹsára ibà

Àwọn oríṣi àjẹsára náà méjèèjì tó wà, tí à ń gba ẹnu lò, ni a lè lò láìséwu. Inú-rírun tàbí ìgbẹ́-yíyà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ipá lè wáyé. Wọ́n ṣeé lò láìséwu bí ènìyàn bá ní oyún, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí agbára àti kojú àìsàn wọn kò múnádóko náà tún lè lò ó. A fún ni ní ìwé-àṣẹ láti lò wọ́n ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ju 60 lọ. Ìmúlò rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti wọ́pọ̀ a má a mú àbájáde tí a lérò wáyé.[1]

Àwọn àjẹsára àkọ́kọ́ tí a lò láti kojú àrùn onígbáméjì ni a ṣe àgbéjáde wọn ní ìparí àwọn ọdún 1800. Àwọn ló jẹ́ àjẹsára àkọ́kọ́ tí a lò káàkiri júlọ, tí a ṣe àgbéjáde rẹ̀ ní yàrá tí a tí ń ṣe àgbéjáde àwọn egbògi.[4] A ṣe àgbéjáde àwọn àjẹsára tí à ń gba ẹnu lò ní àwọn ọdún 1990.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé (World Health Organization), àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Iye owó tí a nílò láti dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àrùn onígbáméjì jẹ́ láàárín 0.1 sí 4.0 USD.[6]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Cholera vaccines: WHO position paper."
  2. 2.0 2.1 Graves PM, Deeks JJ, Demicheli V, Jefferson T (2010).
  3. Sinclair D, Abba K, Zaman K, Qadri F, Graves PM (2011).
  4. Stanberry, Lawrence R. (2009).
  5. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  6. Martin, S; Lopez, AL; Bellos, A; Deen, J; Ali, M; Alberti, K; Anh, DD; Costa, A; Grais, RF; Legros, D; Luquero, FJ; Ghai, MB; Perea, W; Sack, DA (1 December 2014).