Àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀

Àwọn àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀, jẹ́ àwọn àjẹsára tí à ń lò láti dènà àrùn rọpárọsẹ̀ (polio).[1] À ń lo kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn rọpárọsẹ̀ tí a ti pa  láti fi ṣe oríṣi kan, a sì má a ń fún ni ní èyí bíi abẹ́rẹ́ (IPV), a sì tún ń lo kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn rọpárọsẹ̀ tí kò lágbára mọ́ láti fi ṣe oríṣi kejì, a sì ń gba ẹnu lo èyí (OPV). Àjọ Ìlera Àgbáyé gba ni níyànjú pé kí gbogbo ọmọdé má a gba àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀.[1] Àwọn àjẹsára méjèèjì náà ti dẹ́kun àrùn rọpárọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àgbáyé,[2][3] wọ́n sì ti dín iye ènìyàn tó ń ní àrùn náà lọ́dọọdún kù láti iye tí a ṣírò sí 350,000 ní ọdún 1988 sí 359 ní ọdún 2014.[4]

Elétò ìlera ara ń kán ajẹsára àrùn rọpá rọsẹ̀ sí ahan ọmọdé kan

Àwọn àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀ tí a fi kòkòrò tí a ti pa ṣe náà kò léwu rárá. Pípọ́n yòò ibi ojú abẹ́rẹ́ náà àti ìrora díẹ̀ lè wáyé. Àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀ tí à ń gba ẹnu lò a má a ṣe òkùnfa àrùn rọpárọsẹ̀ tó níí ṣe pẹ̀lú ìmúlò àjẹsára náà nínú ìwọ̀n egbògi náà tó tó mẹ́ẹ̀ta nínú mílíọ̀nù kan. A lè lo oríṣi àjẹsára méjèèjì náà láìséwu bí ènìyàn bá ní oyún àti bí ènìyàn bá ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS ṣùgbọ́n tí ara rẹ̀ ṣì dá ṣáká.[1]

Àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀ àkọ́kọ́ ni àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀ tí a fi kòkòrò tí a ti pa ṣe. Ẹnití ó ṣe àgbéjáde rẹ̀ ni Jonas Salk , a sì bẹ̀rẹ̀ síí lòó ní ọdún 1955.[1] Ẹnití ó ṣe àgbéjáde àjẹsára àrùn rọpárọsẹ̀ tí à ń gba ẹnu lò ni Albert Sabin, a sì bẹ̀rẹ̀ sí tàá fún lílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ọdún 1961.[1][5] Wọ́n wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[6] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 0.25 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo fún oríṣi tí à n gba ẹnu lò ní ọdún 2014.[7] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ 25 sí 50 USD fún oríṣi tí a fi kòkòrò tí a ti pa ṣe.[8]

References

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "Polio vaccines: WHO position paper, January 2014."
  2. Aylward RB (2006).
  3. Schonberger L, Kaplan J, Kim-Farley R, Moore M, Eddins D, Hatch M (1984).
  4. "Poliomyelitis: Fact sheet N°114".
  5. Smith, DR; Leggat, PA (2005).
  6. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  7. "Vaccine, Polio" Archived 2017-02-28 at the Wayback Machine..
  8. Hamilton, Richart (2015).