Àjẹsára ikọ́ọfe

Àjẹsára ikọ́ọfe jẹ̀ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ ikọ́ọfe.[1] Àwọn oríṣi méjì pàtakì ni ó wà: àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì àti àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì.[1] Àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì náà ní ìwọ̀n agbára àti ṣiṣẹ́ tó tó 78% nígbàti àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì ní ìwọ̀n agbára àti ṣiṣẹ́ tó tó 71–85%.[1][2] Agbára àti ṣiṣẹ́ àwọn àjẹsára náà a má a dàbí èyí tí ó dín kù pẹ̀lú ìwọ̀n 2 sí 10% lọ́dún, pẹ̀lú díndínkù tó pọ̀ jùlọ nínú àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì. Fífún ni ní àjẹsára nígbàtí ènìyàn bá ní oyún lè dáàbò bo ọmọ inú oyún náà.[1] A ṣe ìṣirò pé àjẹsára náà ti dáàbò bo iye ẹ̀mí tó ju ìdajì mílíọ̀nù lọ ní ọdún 2002.[3]

Àwòrán àjẹsára

Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn gba ni nímọ̀ràn pé kí a fún gbogbo ọmọdé ní àjẹsára ìkọ́ọfe, àti pé kí a fikún àwọn àjẹsára tí à ngbà lóòrèkóòrè.[1][4] Èyí sì kan àwọn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS pàápàá. Ìwọ̀n egbògi mẹ́ẹ̀ta tí a bẹ̀rẹ̀ lọ́gán tí ọmọ bá ti pé ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ̀fà ni a má a ń sábà dámọ̀ràn fún àwọn ọmọdé kékèké. A  lè fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà díẹ̀ síi àti àwọn àgbàlagbà ní àfikún ìwọ̀n egbògi. Àjẹsára náà wà gẹ́gẹ́ bí àdàlù pẹ̀lú àwọn àjẹsára mìíràn nìkan.[1]

Àwọn àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì ni a má a ń sábà lò ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìlọsíwájú nítorí àtúnbọ̀tán rẹ̀ tí kò ní ipá púpọ̀. Ibi ojú abẹ́rẹ́ lára iye àwọn ènìyàn tó tó 10 sí 50% tí a fún ní àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì a má a pupa yòò, wọn a sì má a ní ibà. Gìrì àti igbe-kíké fún ìgbà pípẹ́ a má a wáyé lára iye àwọn ènìyàn tó kéré sí ìwọ̀n kan nínú ọgọ́ọ̀rún. Pẹ̀lú àjẹsára aláìní sẹ́ẹ̀lì, apá-wíwú tí kò ni ni lára rárá lè wáyé fún àkókò díẹ̀. Àtúnbọ̀tán pẹ̀lú àwọn oríṣi àjẹsára náà méjèèjì, pàápàá jùlọ pẹ̀lú àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì, a má a kéré síwájú síi bí ọjọ́-orí ọmọ bá ti kéré sí. A kò gbọdọ̀ lo àjẹsára ẹlẹ́ẹ̀kún sẹ́ẹ̀lì fún ọmọ tí ọjọ́-orí rẹ̀ bá ti kọjá ọdún mẹ́ẹ́fà. Kò sí ìṣòro ọlọ́jọ́-pípẹ́ tó jẹ mọ́ àìsàn nínú iṣan ara pẹ̀lú èyíkéèyí nínú àwọn àjẹsára méjèèjì.[1]

A ṣe àgbéjáde àjẹsára ikọ́ọfe ní ọdún 1926.[5] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[6] Iye owó ẹ̀yà rẹ̀ kan tó tún ní àwọn àjẹsára àwàlù eyín, ikọ́ gbẹ̀fun gbẹ̀fun, àrùn rọpárọsẹ̀, àti ti ọ̀fìnkì oríṣi b nínú jẹ́ 15.41 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[7]

References

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 "Pertussis vaccines: WHO position paper - September 2015."
  2. Zhang, L; Prietsch, SO; Axelsson, I; Halperin, SA (Sep 17, 2014).
  3. "Annex 6 whole cell pertussis" (PDF).
  4. "Pertussis: Summary of Vaccine Recommendations".
  5. Macera, Caroline (2012).
  6. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  7. "Vaccine, Pentavalent" Archived 2020-01-25 at the Wayback Machine..