Muyideen Agboọlá Àlàdé Arómirẹ́ tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí Àlàdé Arómirẹ́ tí wọ́n bí ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹjọ ọdún 1963 jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré ìtàgé, agbéré-jáde, àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Àlàdé lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ansar-ud-Deen tí ó wà ní Alakoso ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Ansar-ud-Deen College, ní Ìlú Ìsọlọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó kan náà. Ó tún kọ́ ẹ̀kọ́ nípa eré oníṣẹ́ ní School of Arts rí ó wà ní Apapa.

Iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí òṣèré, ó ti rí gbogbo rògbàdìyàn àti akitiyan tí ó wà nínú lílo ìlànà "atabloid" tí àwọn àgbà òṣèré bíi: Moses Ọláìyá Adéjùmọ̀, Olóyè Hubert Ògúndé ń lò láti gbé eré jáde tí ó sì ń ná wọn lówó gegere kí eré náà ó tó jáde síta fún àwọn ènìyàn. Ó dá ṣíṣe yíya eré sinimá àgbéléwò àkókọ́ sílẹ̀ tí ó pe àkọọ́lé rẹ̀ ní Ẹkùn ní ọdún 1989.[2]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Meet Alade Aromire, The Man Who Changed The Face Of Yoruba Movies And How He Died 11 Years Ago". City People Magazine. 2019-05-15. Retrieved 2020-10-29. 
  2. "I STARTED NOLLYWOOD...ALADE AROMIRE". Modern Ghana. 2007-10-01. Retrieved 2020-10-29.