Àpàlà jẹ ẹ̀yà orin, tí a múwá láti ọ̀dọ̀ àwọn YorùbáNàìjíríà. Ó jẹ́ èyí tí ó gùn lé sítáì pakọ́sàn tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní òpin ọdún 1930 lọ sókè, ní ìgbà tí wọ́n ń lò ó láti jí àwọn olùsìn lẹ́yìn ààwẹ̀ lásìkò oṣù mímọ́ Lámúláánà ti àwọn ìmọ̀le. Ìmìtìtì àpàlà gbòòrò si pẹ̀lú àsìkò, ó fi orin Kúbànì ṣe àtẹ̀gùn tí ó sì di gbajú-gbajù ní Kánádà. Láìpẹ́ ó di èyí tí ẹ̀sìn kìí ṣe àkòrí rẹ̀.[1] Lára ohun èlò rẹ̀ ni ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, àgídìgbo, agogo, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlù dùndún méjì tàbí mẹ́tahttps://www.britannica.com/art/Apala Dájúdájú Hárúnà Ìṣọ̀lá ni olórin àpàlà tí ó gbajúmọ̀ jùlọ nínú ìtàn Nàìjíríà. Àwọn mìíràn le lòdì sí èyí pé Àyìnlá Ọmọwúrà ni wọ́n mọ̀ jù, tí ó sì jẹ́ olórin àpàlà tí ó soríire jùlọ. Àwọn méjèèjì ni ó kó ipa mọyàmí nínú mímú ẹ̀yà orin yìí di ìlúmọ̀ọ́ká, ó sì yàtọ̀ sí, ó dàgbà ju, ó sì nira káká láti mọ̀ ju Fújì lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àyìnlá Ọmọwúrà kú nígbà tí ó wà ní ọmọ ogójì ọdún ó lé díẹ̀ ní ọdún 1980. Ó ṣe àwo tí ó ju ogún lọ, tí ó sì jẹ́ pé gbKogbo wọn ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Fújì sì dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ya orin ìbílẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ láàrin àwọn Yorùbá ní Nàìjíríà, àpàlà sì gbajúmọ̀ dáadáa láàrin àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí ó jẹ́ Mùsùlùmí. Ọ̀nà ọ̀tọ̀ ni a ti gbọ́dọ̀ máa dárúkọ ọmọ Hárúnà Ìṣọ̀lá, Músílíù Hárúnà Ìṣọ̀lá ẹni tí wọn ń gbóríyìn fún nípa mímú àpàlà kúrò nípò òkú, tí ó sì nìkàn ṣe agbátẹrù àjíǹde àpàlà ti ọdún 2000 pẹ̀lú àwo orin rẹ̀ ti ọdún 2000 (tí ó pe ní 'Sóyòyò) Músílíù ti ṣe àṣeyọrí nípa mímú kí orin àpàlà fẹjú síi, sí etíìgbọ́ àwọn ọ̀dọ́, ó ṣe bẹ́ẹ̀ mí èémì ọ̀tun sí inú ẹ̀yà orin yìí bẹ́ẹ̀ náà ni ó mú àṣà (iṣẹ́ takuntakun bàbá rẹ̀) wà láàyè. Ó gba oríyìn mímú ẹ̀yà orin yìí gbajúmọ̀ padà èyí tí ó ti ń di ti àwọn Mùsùlùmí ẹ̀yà Yorùbá ayé àtijọ́. Àṣeyọrí àwo orin 'Sóyòyò' túmọ̀ pé ọ̀dọ́ (lọ́pọ̀ ìgbà onígbàgbọ́ tàbí abọgibọ̀pẹ̀) òde òní ti Yorùbá ti wá ń ṣàfihán ìfẹ́ wọn nínú orin àpàlà. A lè gbọ́ orin rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì káàkìri ilẹ̀ Yorùbá.

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "APALA". APALA. 2018-11-06. Retrieved 2018-11-26.