Aroko Lori igbeyin loju

[1]

Àrokò pípa ní ayé àtijọ́

àtúnṣe

Àrokò pípa jẹ́ ọ̀nà tí Yorùbá máa n gbà se ìkìlọ̀ tàbí ránsẹ́ sí ẹlòmíràn láyé àtíjọ́. Àrokò má n jẹmọ́ isẹ́, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ tí àwọn ènìyàn nse. Òtítọ́ tàbí ìgbọràn se pàtàkì nínú àrokò pípa. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ wípé ẹnikẹ́ni tí a bá fi àrokò rán gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fetí sí òfin àti olótítọ́ ènìyàn.

Àwọn àrokò kan wà tí ó máa n wà lójú kan, àwọn àrokò wònyìí ni à n pè ní àte, irú àwọn àrokò báyìí wà láti ṣe ìkìlọ̀ ewu.

Láyé àtíjọ́, orísirísi àwọn ènìyàn ló má n pàrokò ránsẹ́. Díẹ̀ lára wọn ni:- Ọdẹ ,Babaláwo, awo, ògbóni, jagunjagun, àgbẹ̀, àti bẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ

Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tí a bá pa àrokò]

àtúnṣe
  • Ẹni tí o pa àrokò
  • Ẹni tí a fi àrokò ran
  • Ẹni tí a fi àrokò ránsẹ́ si

Ẹni tí ó pa àrokò: Ẹni tí o pa àrokò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí o mò irú èrònjà tí ó tọ́ fún irú àrokò tí ó fẹ́ pa. Ẹni náà gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́.

Ẹni Tí a fi Àrokò rán: Ẹni tí a fi àrokò náà rán gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó se fi ọkàn tán, tí kìí se màdàrù ènìyàn rárá.

Ẹni tí a fi Àrokò ránsẹ́ sí : Ẹni náà gbọdọ̀ mọ ìtumọ̀ àrokò tí a pa fún, sùgbón tí ẹni náà kò bá mọ irú àrokò tí a pa fún, ó gbọdọ̀ lọ bá àwọn àgbà láti sọ ìtumọ̀ àrokò náà fún.

Oríṣìíríṣìí Àrokò

àtúnṣe
  • Àrokò ìkìlọ̀
  • Àrokò ẹ̀bẹ̀
  • Àrokò ogun
  • Àrokò ìranṣé
  • Àrokò ìfẹ́
  • Àrokò ìtọ́nisọ́nà[2]
  • Àrokò àlè pípa
  • Àrokò àṣẹ́wélé
  • Àrokò agà yíya [3]
  • Àrokò ajẹmówe
  • Àrokò afohùn gbéwà jáde
  • Àrokò ajemáṣìírí

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Ọlátúnjí,O (1986);Àrokò.Ìbàdàn,Vintage Publishers.