Babaláwo gbólóhùn yí jẹ́ gbólóhùn alákànpọ̀ (Bàbá) àti (Aláwo) tí ó túmọ̀ sí bàbá tí ó nímọ̀ ní awo ṣíṣe, yálà awo Ògbóni tàbí awo mìíràn. Àmọ́, Babaláwo túmọ̀ sí ẹni tí ó yanṣẹ́ awo ṣíṣe láàyò pàá pàá jùlọ̀ Ifá dídá láti máa fi ṣiṣẹ́ yẹ̀míwò fún àwọn ènìyàn. Irú ẹni yìí ma ń dáfá káàkiri ìgbèríko àti agbègbè rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àṣe tí ifá bá paá. Babaláwo yàtọ̀ sí Oníṣègùn, nínú iṣẹ́ ìbílẹ̀ abínibí ilẹ̀ Yorùbá.

Iṣẹ́ Awo ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ abínibíÀtúnṣe

púpọ̀ nínú àwọn babaláwo ayé àtijọ́ àti díẹ̀ nínú àwọn tòde òní ni wọ́n jẹ wípé wọ́n bá iṣe awo ṣíṣe nílé tí wọ́n sì jogun ba lọ́wọ́ àwọn baba-ńlá baba wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìdílé àti abínibíbí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ má ń lọ fira wọn jìn tàbí ṣọfà sọ́dọ̀ Onífá kan láti mọ̀ tàbí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ifá dídá. Lẹ́yìn ọọ̀pọ̀ ọdún wọn yóò mọ̀ nípa bí a ti ń dáfá tì wọ́n yóò sì dẹni ara wọn pẹ̀lú.[1]àwọn ìtọ́ka síÀtúnṣe

  1. "Iwe fun Odu Ifa: Ancient Afrikan Sacred Text". Kilombo Restoration & Healing. Retrieved 2019-03-14.