Áńtàr Láníyan
Áńtàr Láníyan tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú Òṣogbo ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2]
Áńtàr Láníyan | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Osun State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | film actor and producer |
Notable work | Sango |
Àwọn olùbátan | 1981–present |
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́
àtúnṣeÁńtàr Láníyan jẹ́ ọmọ Yorùbá pọ́nńbélé ti ilu Òṣogbo, Olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ni Baptist secondary school ní ìlú Èkó kó tó tẹ̀ síwájú ní ifáfitì, the University of Ìbàdàn , ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níbi tí ó ti kàwé gboyè dìgírì nínú iṣẹ́ tíátà.[3]
Aáyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1981. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa pàtàkì láti ìgbà náà. Gbajúmọ̀ lára àwọn sinimá-àgbéléwò náà ni, ṣàǹgó. Kódà, gẹ́gẹ́ bí olùdarí sinimá àgbéléwò, òun ló dárí sinimá tí wọ́n máa ń ṣe àfihàn rẹ̀ lórí ẹ̀rọ tẹlifíṣàn, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Super Story", tí gbajúmọ̀ olóòtú sinimá àgbéléwò, Wálé Adénúgà ṣe olóòtú fún lọ́dún 2000. Bákan náà òun ló dárí sinimá àgbéléwò, OH Father, OH Daughter" àti "This Life", gbogbo rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àìmọye sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá ní Áńtàr Láníyan tí kópa gẹ́gẹ́ bí òṣèré àti Adarí-sinimá. [4][5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Dele Odule, Antar Laniyan, Fathia Balogun others head breakaway Yoruba movie association". Nigeria News Today -NNT. Archived from the original on 13 February 2015. Retrieved 13 February 2015.
- ↑ PeoplePill. "Antar Laniyan: Film actor - Biography, Life, Family, Career, Facts, Information". PeoplePill. Retrieved 2019-12-16.
- ↑ "Why I don’t drink, smoke or womanise – Antar Laniyan". Newswatch Times. 2013-06-21. Archived from the original on 2015-02-13. Retrieved 2019-12-16.
- ↑ "Antar Laniyan Archives - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Indonéṣíà). 2015-09-30. Retrieved 2019-12-16.
- ↑ Lindfors, B. (2003). Black African Literature in English, 1997-1999. Black African Literature in English. Hans Zell. p. 8. ISBN 978-0-85255-575-0. https://books.google.nl/books?id=rAUbyu1wRCsC&pg=PA8. Retrieved 2019-12-16.