Ìdòwú Philips

Òṣéré orí ìtàgé
(Àtúnjúwe láti Ìdòwú Phillips)

Ìdòwú Philips ni a bí ní ọjọ́ Kẹrìndílógún oṣù Kẹwàá ọdún 1942 (26-10-1942), òun ni a mọ̀ sí Ìyá Rainbow,[1] jẹ́ gbajúgbajà Òṣeré kan tí ó jé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà . [2][3][4]

Idowu Philips
Ọjọ́ìbí16 October 1942 (1942-10-16) (ọmọ ọdún 82)
Ijebu Ode, Ogun State, Nigeria.
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànIya Rainbow
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Nurse, film actress
Ìgbà iṣẹ́1965-present
Àwọn ọmọ5

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Ìyá Rainbow ní ìlú Ìjẹ̀bú-ÒdeÌpínlẹ̀ Ògùn, tí ó jẹ́ apá Gúsù ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Naijiria . Orúkọ àpèjẹ orí ìtàgé rẹ̀ ni "Ìyá Rainbow" tí ó túmọ̀ sí "Òṣùmàrè" (tí ó túmọ̀ sí "Rainbow" ní èdè Gẹ̀ẹ́sì), orúkọ tí Ìdòwú tẹ̀ mọ́ra yí ni ó jẹ́ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèrè ọkọ rẹ̀ Sir Hubert Ògúùndé, tí ó kú ní ọdún 1990. Ó ti fìgbà kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú aláìsàn ní àwọn ilé-ìwòsàn gbogbo-gbò ti ìjọba ni ilẹ̀ Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí ó sì ma ń ṣe eré orí ìtàgé nídàákú rekú ní àwọn àsìkò tí ó ń ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà ní pẹrẹu ní ẹ̀yìn ikú ọkọ rẹ̀, ìyẹn Augustine Àyànfẹ́mi Phillips (ẹni tí ó ́jẹ́ òṣìṣẹ́ gidi pẹ̀lú olùdásílẹ̀ Sinimá Àgbéléwò ní ilẹ̀ Nàìjíríà (Sir Hubert Òguúndẹ́). Ìdòwú ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíímù ilẹ̀ Nàìjíríà, bíi Àpáàdì, Ẹrú, Àjẹ́ ni ìyá mi àti àwọn mìíràn. Ọlórun fi ọmọ márùún ta á lọ́rẹ. [5]

Àwọn Fíímù tí ó ti kópa

àtúnṣe
  • 1997- Padà sí Áfíríkà
  • 2000- Lạ́gídígba
  • 2002- Jésù Mushin
  • 2002- Ìrẹ́pòdùn
  • 2002- Ẹyin Ògòngò
  • 2003- N150 Mílíọ̀nù
  • 2003- Ìfé òtító
  • 2003- Fìlà Daddy
  • 2003- Ọkọ̀ North
  • 2003- Ọmọ òkú Ọ̀run
  • 2003- Okùn ìfẹ́
  • 2004- Okùn ìfẹ́ 2
  • 2004- Ọ̀kan ṣoṣo
  • 2004- Ọ̀kan ṣoṣo 2
  • 2004- Ògì eto
  • 2004- Ògì eto 2
  • 2006- Àbẹ̀ní
  • 2006- Ọdún ǹ bákú
  • 2006- Mẹ́wá ń ṣẹlẹ̀
  • Ọdun 2006- Èebúdolá tèmi
  • 2006- Agbefo
  • 2006- Agbefo 2
  • 2007- Orita Ipinya
  • 2007- Olugbare
  • 2007- Olóri
  • 2007- Maku
  • 2007- Kootu olohun
  • 2007- Kilebi olorun
  • 2008- Taiwo Taiwo
  • 2008- Taiwo Taiwo 2
  • 2008- Itakun ola
  • 2008- Ìkúnlè kèsán
  • 2008- Ikilo agba
  • 2008- Igba ewa
  • 2008- Aje metta
  • 2008- Aje metta 2
  • 2009- Ìpèsè
  • 2009- Ìdàmu eléwòn
  • 2009- Elewon
  • 2009- Akoto olokada
  • 2009- Akoto olokada 2
  • 2018- Oga Bolaji

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "I wish to live up to 120 years, says Mama Rainbow @ 79". Punch Newspapers. October 17, 2021. Retrieved May 29, 2022. 
  2. "Veteran actress, Iya Rainbow celebrates 75th birthday and 50 years acting career". http://allure.vanguardngr.com/2017/11/veteran-actress-iya-rainbow-celebrates-75th-birthday-50-years-acting-career/. Retrieved December 29, 2017. 
  3. Okonofua, Odion (2018-10-16). "Idowu Phillips 'Iya Rainbow' celebrates 76th birthday with stunning photos". Pulse Nigeria. Archived from the original on 2019-12-13. Retrieved 2019-11-20. 
  4. Bassey, Ekaete (February 1, 2022). "Mama Rainbow adopts Lateef Adedimeji on 36th birthday - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper. Retrieved May 29, 2022. 
  5. Adebayo, Musliudeen (2019-08-10). "Nollywood needs government's support to prevent it from going into extinction - Idowu Phillips". Daily Post Nigeria. Retrieved 2019-11-20.