Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà

Ìlú tí ó lajú
(Àtúnjúwe láti Ìjèbú-Jèṣà)

Ìjèbú-Jèṣà je ilu ni ile Naijiria ati oluilu agbegbe ijoba ibile Oriade ni Ipinle Osun.

Agbègbè kan ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà

Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín.

Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé: Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kìíni, Agírgírì jẹ́ tẹ̀gbọ́n tábúrò. Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọomún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú Ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Nípa bẹ́ẹ̀ Ọwá Ajíbógun àti Agígírì jọ dàgbà pọ̀. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kí í sì í yara wọn bí ó ti wú kí ó rí.

Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji-Agígírì àti ajíbogun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣa láti dó sí kí wọn lè ni àyè ijọba tiwọn. Ajíbogun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónìí yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírì rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbùrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọdọ̀ jìnná sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé aginjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pè ibi tí òun ti rìn ti nàsẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí.

Kì wọn tó kùrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún un ní ọgbọn nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọn, òun lè dáàbò bo ara òun, ò sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé;

“Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n

Ijẹ̀bú ogún

É sìí bó ṣe a rí

Kógún a parẹ́

mọ́gbọ̀n lára”

Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírì àti Ajíbógun ni Ilé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lè ríran padà ó lọ, Ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohun ìní bàbá wọn líifi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran.

Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀) bàbá rẹ̀. ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fun un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú irin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀.

Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyà yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn sì wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn.

Itán sọ pé Ibòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọna Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà sì gba Ilékéte lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ si Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró: Agóró yìí ló dúró sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan patàki nínú àwọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sì iwájú díẹ̀ kí ó lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ràn Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Igbà ti Agígírì kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fun ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lonìí yìí. Iyàlẹnu ńlánlà lọ́ jẹ́ fún Agígírì láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lù àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí ti ibẹ̀ dùn mọ́ on fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọdẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì a sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n isàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkònísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayó”.

Agbo ilée Bajimọn ní Òkè -Ọjà ni Agígírì sọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́jìn èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gbà òtẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè Agígírì kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ilédè náà ní ibi tí Aàfin Ọba Ijẹ̀bú-jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí wọ́n múra láti ibé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nikẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. “Ojú iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu tí ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ́ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n.

Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ijẹ̀bù-Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bí-Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbà tí wón dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n pẹ̀rẹ̀sì í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mù ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n Igbà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ láti máa tọ́jú ogbà náà, wọ́n sì dúró pẹ́ dìẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìbẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilé. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn –Agígírì sọ ibẹ̀ ni IJẸLÚ nítorí pe ÌJẸ̀ ni Ìjẹ̀sà máa ń pe Ẹ̀JẸ̀. Nigbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ̀bú tí wọ́n ti ń pè tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní.

Ṣùgbọ́n Ijẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́. Ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa.

A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bu ti Ìjẹ̀bù –Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè má sí láàárin wọn nígbà kan ti rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu Ògbóni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-Òde lọ. Ibẹ̀ ló gi mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó.

Nínú àwọn ìtàn òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ijẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfẹ́ èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ijẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mi díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ògbóni. Itán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀.

Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, Ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ ọ̀ọ́tó jù lọ nínú wọn.

Nipa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ojọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a sẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì kan náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti ajá tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárìn wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ìlẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkán kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn.

Tí Ọwá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀.

Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilẹ̀ṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bu-Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Ilẹ́ṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Ilẹ́ṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọ̀n ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Idí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé;

“Kàí bi an kọlíjẹ̀bú

Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀

Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú

Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀”

Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sì n jẹ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà a rí Ògbóni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara Ìwàrẹ̀fà mẹfà ni ògbóní méjèejì yí a ni Iléṣà ṣùgbọ́n ògbóni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. A rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà.

Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí ti orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún apẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní ìléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú jèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ́lù.

Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, àdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ.

Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán.

Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, ón ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù.

Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀nà tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù.

Nígbà tí ilẹ̀ Ilèṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́ún, àrìmọ-kùnrin Ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bù-Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójù ráyè, kí ó tó tùbà tùṣẹ.

Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọbà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá àti Ògbóni Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”

Alaye sọ́kí lórí ìlú àti àwọn ènìyàn ìjẹ̀bù-jẹ̀ṣà

Ìlù Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ ìlú kan pàtàkì ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yị́ ní Nàìjéríà. Apá ìwọ́ oòrùn ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí káàárọ́ - oò- jíire. Ìlú Ilẹ́ṣà ti ó jẹ́ olú ìlú fun gbogbo ilẹ̀ jẹ̀ṣà jẹ́ nǹkan ibùsọ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin sí ìlú Ìbàdàn tí jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlú Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì tó nǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́fà sí Iléṣà ní apá àríwá ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà.

Ní títóbi, ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ó pọwọ́lé ìlú Iléṣà ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, òun si ni olú ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ọ́un kí wọn tó tún un pín sí ọ̀nà mẹ́rin; síbẹ̀ náà òun ni olú ìlú fún ìjọba ìbìlẹ́ ààrin gùngùn obòkun.

Àdúgbò márùnún pàtàkì ni wọ́n pín ìlú yìí sí kí bà lè rọrùn fún ètò ìjọ̀ba síṣe àti fúniṣẹ́ Ìlọ́rọ̀, Ọ̀kènísà àti Òdògo. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúgbò yí ló ní Olórí ọmọ tàbí lóógun kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ aṣáájú fún ọmọ àdúgbò rẹ̀ òun ní aṣáájú fún iṣẹ́kíṣẹ́ àti tí ó bá délẹ̀ láti ṣe ni àdúgbó, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún jẹ́ aṣojú ọba fún àwọn ọmọ àdúgbò rẹ̀. Òdògo nìkan ni kò fi ara mọ́ èlò yí tó bẹ́ẹ̀ nítorí ìtàn tó bí i fi hàn pé ìlú ọ̀tọ̀ gédégédé ni òun. Àwọn ènìyàn ọ̀gbọ́n náà ń fẹ́ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ ti fi hàn wí pé wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Lòde òní, nǹkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí pé àjọṣẹ tí ó péye ti ń wàyé láàárín ọ̀gbọ́n náà àti àwọn ọ̀gbọ́n yòókù.

Ẹ̀rí tí ó fi hàn gbegbe pé àwọn Ìjẹ̀ṣà gba ìlù Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bi ìlú ti ó tẹ̀ lé Iléṣà ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni pé ìjókòó àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá ìlẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń yàn àn lé. Síwájú sí i, nípa ti ìlànà oyè jíjẹ, ó ní iye ọjọ́ tí Ọwá tuntun gbọ́dọ̀ lò ní Ijẹ̀bù - Jẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni ó máa ń gbé Ọwá lésẹ̀ tí ó sì máa ń ṣúre fún un kí wọn tó gbà á gẹ́gẹ́ bí ọwá àti olóri gbogbo ọba ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà.

Láti túnbọ̀ fi pàtàkì ìlú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ìtàn ìwásẹ̀, ti Ọwá bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ọ̀daràn apànìyàn kan, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbódọ̀ wà níjòkó, bí èyí kò bà rí bẹ́ẹ̀, Ọwá gbódọ̀ sùn irú igbẹ́jọ́ tábi ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe máa ń sọ pé

“Ọwa ràà dáni í pa

K Ìjẹ̀bu -Jẹ̀ṣà mọ mọ̀n

Kọ́wá bá a pani

Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà á gbọ́”

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ, bẹ́ẹ̀ ni a tún rí àwọn tó mú àgbẹ̀ àrojẹ mọ́ àgbẹ̀ agbinrúgbìn tó ń mówó wọlé lọ́dọ́ọdún àti láti ìgbàdégbà. Àwọn irúgbìn tí wọ́n ń gbìn fún àrojẹ ni, iṣu, ẹ̀gẹ́ (gbáàgúdá) ikókó, ìrẹsì, àgbàdo, kọfí, òwù àti obì sì jẹ́ àwọn irù-gbìn tó ń mówó wálé fún wọn.

A rí àwọn oniṣẹ-ọwọ́ bíi, alágbẹ̀dẹ, onílù. agbẹ́gilére, àwọn mọlémọlé àti àwọn kanlékanlé. Àwọn obìnrin wọn náà a máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́-ọwọ́, lára wọn ni aró dídá, apẹ ati ìkòkò mímọ àti aṣọ híhun pẹ̀lú.

Bákan náà, wọ́n tún jẹ́ oníṣowò gidi. Ọmọ ìyá ni ẹlẹ́dẹ̀ àti ìmọ̀dò, bẹ́ẹ̀ náà sì ni inàki àti ọ̀bọ, gbogbo ibi tí a bá ti dárúkọ Ìjẹ̀ṣà ni a á ti máa fi ojú oníṣòwo gidi wò wọ́n. Elèyìí ni a fi ń pè wọ́n ní “Òṣómàáló” nítorí kò sí ibi tí a kó ti lè rí Ìjẹ̀ṣà ti ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí irúfẹ́ owo tí wọn kò lè ṣe, ohun tí ó kó wọn ni irìnra ni olé àti ọ̀lẹ. “Alápà má ṣiṣẹ́” ni àwọn Ìjẹ̀ṣà máa ń pe àwọn ti kò bá lè ṣiṣẹ́ gidi. Wọn ko sì fẹ́ràn irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ràrá. Ìjẹ̀ṣà kò kọ̀ láti kọ ọmọ wọn lọ́mọ tí ó bá jalè tàbí tí kò níṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́. Wọ̀n á sí máa fi ọmọ wọn tí ó bá jẹ́ akíkanjú tàbí alágbára yangàn láwùjọ. “Òkóbò nìkan ni kìí bímọ sí tòsí, a ní ọmọ òun wà ní òkè-òkun” Bákan náà ni pé “arúgbó nìkan ni ó lè parọ́ ti a kò lè já a nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti kú tán” Purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ ní ń mú wá, bi irọ́ ni, bí òótọ́ ni pé àwọn Ìjèṣà jẹ́ akíkanjú, ẹ wo jagunjagun Ògèdèngbé “Agbógungbórò” Ọ̀gbóni Agúnsóyè, “Ologun abèyìngọgọú, ó pẹ̀fọ̀n tán, ó wojú ìdó kọ̀rọ̀, Ọ̀dọ̀fin Arówóbùsóyè, Ọ̀gbọ́kọ̀ọ́ǹdọ̀ lérí odi kípàyẹ́ bì yẹ̀ẹ̀yẹ̀ẹ̀ séyìn” Ológun Arímọrọ̀ àti àwọn Olórúkọ ńláńlá ni ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Tí a bá tún wo àwọn oníṣòwò ńláńlá lóde òní nílẹ̀ Yorùbá jákèjádò, “Ọkan ni ṣànpọ̀nná kó láwùjọ èpè” ni ọ̀rọ̀ ti Ìjẹ̀ṣà. Nínú wọn ni a ti rí Àjànàkú, Erinmi lókun, Ọmọ́le Àmúùgbàǹgba bíu ẹkùn, S.B. Bákàrè Olóye méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti Onìbọnòjé àtàri àjànàkù tí kì í ṣẹrù ọmọdé. Mé loòó la ó kà lẹ́hín Adépèlé ni ọ̀rọ̀ wọn.

Àwọn ọmọ Ìjèbú -Jẹ̀ṣà jẹ́ aláfẹ́ púpọ̀ pàápàá nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ènìyàn ti o fẹ́ràn àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ láàárin onílé àti àlejò sì ni wọ́n pẹ̀lú. Wọn máa ń pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìlú láti jọ kẹ́gbẹ́ àjùmọ̀ṣe lẹ́nu iṣẹ́ àti oríṣìíríṣìí ayẹyẹ nílùú pẹ̀lú. “Àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dóri” àjùmọ̀ṣè wọn yìí mú ìlọsíwájú wá fún ìlú náà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ “Abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kò má tatí were” ni ti àwọn ọmọ Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà sí ohunkóhun tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlú wọn. Bí ọ̀rọ̀ kan bá délẹ̀ nípa iṣẹ́ ìlú, wọn máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i, wọ́n á sì mú sòkòtò wọn wọ̀ láti yanjú irú ọ̀rọ̀ náà. Ọmọ ọkọ ni àwọn ọmọ ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ní tòótọ̀.

Síwájú sí i, oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó bá òde òní mu ni wọ́n ti là sí àárín ilú láìní ọwọ́ ìjọba kankan nínú fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ Ilé - Ẹ̀kọ́ gíga (Grammar Schoo) méji tí ó wà ní ilú náà, òógùn ojú wọn ni wọ́n fi kọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Modern School wọn. Ọjà ilú, ilé-ìfìwé rànṣẹ́ àti gbàngàn ìlú ti o nà wọn tó àádọ́ta àbọ̀ ọ̀kẹ́ naira: Àwọn ọ̀nà títí tí wọ́n bójú mu tí wọ́n sì bá ti òde òní mu náà ni wọ́n ti fi òógùn ojú wọn là láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba kankan.


  • J.A. Arówóbùsóyè (1982), ‘ITÀN ÌSẸ̀DÁLẸ̀ ÌLÚ ÌJÉḄÚ-JÉSÀ’ DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.