Ìjọba Ìbílẹ̀ jẹ́ ìpele ìjọba ẹlẹ́kẹta àti irúfẹ́ ìjọba tí ó jẹ́ ti àwa-ara-wa lẹ́sẹ̀ kùkú ti ó wà ní abẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lábẹ́ ìlànà ìṣèlú àwa-ara-wa.[1] Ìjọba ìbílẹ̀ ma ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin àti àlàkalẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè bí àwọn aṣòfin (legistlatives) àti àwọn amòfin (Judiciary) ṣe gbe kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà étò Ìjọba Àpapọ̀ (Federal State), ìjọba ìbílẹ̀ ló sába ma ń wà ní ipò kẹta nínú étò ìṣèlú. [2]

Ẹ̀wẹ̀ àgbékalẹ̀ étò Ìjọba ìbílẹ̀ yàtọ̀ síra wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní agbáyé. [3]

Àwọn Ìpínsísọ̀rí ìjọba

àtúnṣe

Ìpínsísọ̀rí ìjọba lábẹ́ ìjọba apapọ̀ (Federal Government) lábẹ́ ìjọba àwa-ara-wa (Democrcy), ṣe pàtàkì. Ìlànà ìṣèlú lábẹ́ ìjọba Àpapọ̀ pín sí ọ̀nà Mèta.

  1. Ìjọba Àpapọ̀. Èyí ló ń ṣàkóso ìjọba méjèjì ìsàlẹ̀
  2. Ìjọba Ìpínlẹ̀, ẹ̀yí jẹ́ ìjọba àárín tó tún lágbara ju ìjọba ìbílẹ̀ lọ
  3. Ìjọba Ìbílẹ̀ tabí ìjọba ẹsẹ̀ kùkú ti ó kángun sí àwọn ará-ìlú. [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Definition, Examples, & Responsibilities". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-06-09. 
  2. "Definition of LOCAL GOVERNMENT". Definition of Local Government by Merriam-Webster. 2020-05-22. Retrieved 2020-06-09. 
  3. Level, Education (2014-06-04). "What Is Local Government? - Definition, Responsibilities & Challenges - Video & Lesson Transcript". Study.com. Retrieved 2020-06-09. 
  4. "Local Government". Encyclopedia.com. 2020-05-23. Retrieved 2020-06-09.