Amòfin
Amòfin ni a lè pè ní ẹni tí ó ń ṣísẹ́ òfin tàbí tí ó ń fi òfin ṣiṣẹ́ ṣe. Ipa tí amòfin ń kò kò kéré láàrín ìlú sí ìlú ati orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè. Amòfin lè jẹ́ agbèfúni (solicitor), ó lè jẹ́ amòfin níwájú adájọ́, ó lè jẹ́ amòfin ajàfẹ́tọ́ẹni àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Èyíkéyí tí kò báà jẹ́ nínú iṣẹ́ wọn ni ó ní ojúṣe tìrẹ àti ànfaní rẹ̀ pẹ̀lú.[1]Ṣíṣe iṣẹ́ amòfin ni ó ní kíkọ́ ati mímọ̀ nípa àpadé-àludé bí ofin ìlú tabi orílẹ̀-èdè bá ṣe rí àti ìmọ̀ nípa bí a ṣe lè lo òfin náà láti fi yanjú ìṣòro.[2][3] [4][5]
Èdè ìperí wọn
àtúnṣeOnírúurú nkan ni oríṣiríṣi ìlú tàbí orílẹ̀-èdè ma ń wo ṣàkun rẹ̀ kí wọ́n tó lè pe enìkan ni amòfin, fúndí èyí, orúkọ tí wọn a máa pe amòfin ní ibìkan sí òmíràn a máa yàtọ̀ sírawọn.
Àwọn ìlú mìíràn ní osíṣi iṣẹ́ amòfin méjì tí wọ́n sì pè wọ́n ní barrister ati solicitor, nígbà tí àwọn kan jan orúkọ méjèèjì pọ̀. Bí wọ́n bá pe ènìyàn ní Barrister, ó túmọ̀ sí wípé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ akọni níwájú adájọ́, nígbà tí Solicitor túmọ̀ sí ẹni tí kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń gbé ẹjọ́ kan tàbí òmíràn lọ síwájú adájọ́ nílé-ẹjọ́. Agbègbè tàbí ìlú ni ó lè sọ bí Solicitor bá lè ṣègbè fúnni nílé ẹjọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀tọ́ láti dúró ṣègbè tàbí tako ẹjọ́ níwájú adájọ́. Lóòtọ́ ni Barrister àti Solicitor kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ òfin síbẹ̀, iṣẹ́ wọn yàtọ̀ sírawọn. Ìyàtọ̀ láàrín Barrister àti Solicitor ni ó jẹyọ nínú ìmọ̀òfin awọn gẹ̀ẹ́sì, tí ó sì jẹ́ wípé púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Won gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìmúnisìn àwọn gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń lo ìlànà òfin gẹ̀èsì, síbẹ̀ wọ́n sọ orúkọ méjèèjì di ọ̀kan. Àwọn orílẹ̀-èdè bíi: New Zealand, Kánádà, India Pakistan, àti US ni wọ́n sọ Barrister àti Solicitor (agbẹjọ́rò) di ọ̀kan ṣoṣo. [6] Àwọn mìíràn náà tún pa iṣẹ́ àwọn agbẹjọ́ró méjèèjì náà pọ̀ di ẹyọkan tí wọ́n sì sọniṣẹ́ wọn fi ẹyọkan pẹ̀lú. Ní USA, wọn a máa pe Barrister àti Solicitor ní attorneys", tí ó túmọ̀ sí agbẹjọ́rò tí ó lè jà fúnni tàbí takoni níwájú adájọ́. [5] Amọ́ ní orílẹ̀-èdè India àti Pakistan, wọn a máa pe amòfin agbẹjọ́rò ní advocates. Nígbà tí àwọn mìíràn jan àwọn orúkọ amòfin agbẹjọ́rò bíi :"barrister àti solicitor" tàbí "attorney àti counselor" láti fi júwe oníṣẹ́ òfin tí a mọ̀ sí agbẹjọ́rò lápapọ̀.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Henry Campbell Black, Black's Law Dictionary, 5th ed. (St. Paul: West Publishing Co., 1979), 799.
- ↑ Geoffrey C. Hazard, Jr. & Angelo Dondi, Legal Ethics: A Comparative Study (Stanford: Stanford University Press, 2004, ISBN 0-8047-4882-9), 20–23.
- ↑ John Henry Merryman and Rogelio Pérez-Perdomo, The Civil Law Tradition: An Introduction to the Legal Systems of Europe and Latin America, 3rd ed. (Stanford: Stanford University Press, 2007),102–103.
- ↑ David G. Cooper and Michael J. Gibson, Introduction to Paralegal Studies, 2nd ed.(Clifton Park: Thomson Delmar Learning, 1998), 4.
- ↑ 5.0 5.1 "Rule 5.5: Unauthorized Practice of Law; Multijurisdictional Practice of Law". American Bar Association. Archived from the original on 2015-06-02. Retrieved 2015-04-18. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "THE ADVOCATES ACT, 1961" (PDF). Bar Council of India. 1961. Archived from the original (PDF) on 19 Aug 2008. Retrieved 1 May 2023. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)