Ìlù Sákárà jẹ́ ìlù kan lára àwọn ìlù mẹ́rin tó jẹ́ ẹbí kan náà nínú ìlù tó ṣe gbòógì mẹ́rin nílẹ̀ Yorùbá. Àwọn èyà ìlù tó kù ni Dùndún tàbí Gángan, Bàtá, àti ìlù Gbẹ̀du. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìlù òkè yí ni wọ́n jẹ́ ìwọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, sì ìyá ìlù tó ma ń ṣáájú nínú eré tí àwọn tókù yóò sì ma kọ́wọ̀ọ́ tẹ̀le. Bákan náà ni àwọn Awúsá náà ma ń lu Sákárà níbi ayẹyẹ wọn pẹ̀lú. Sákárà ní tirẹ̀ jẹ́ ìlù kékeré roboto tí a fu ìjòkò amọ̀ ṣe. Gíga rẹ̀ kò ju ohun tí ó lè dúró sí àárín ọba (thumb) ìka àti ìka ìfábẹ̀lá, tí wọ́n sì ma ń fọwọ́ tẹ̀ láti ẹ̀yín. Wọ́n fi pẹ̀pẹ́ igibde awo ìlù náà mọ́lẹ̀ ní gbogbo eteetí. Lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n ma ń fi awọ ewúrẹ́ sé àwọn ìlù kékẹèèké wọnyí, tí wọ́n sì ma ń fi awọ malúù sé àwọn ilù èyí tí ó bá fẹ̀ dáradára.Ìka ọ̀kan nínú ọwọ́ kan lè ṣe àyípadà sí ohùn ìlù náà nígbà tí wọ́n bá fi kọ̀ngọ́ bojú ìlù yí. Nígbà tí a bá lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlù Sákárà pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, ìyá ìlù ló sábàma ń dún ju gbogbo wọn lọ, tí ó sì ma ń pààlà àti àṣẹ'irúfẹ ìwọ́hùn tí ó bá yẹ. Àwọn Omele akọ àti Omele abo náà ma ń fọhùn ní kíkan kíkan, tí gbogbo wọn sì ma ń fúni lóhùn àdídùn tí ń mórí yá. Àwọn Yorùbá ma ń lo Sákárà fún oríṣiríṣi ayẹyẹ bí ìgbeyàwó, Wéré lásìkò sààrì àti ọdún ìtúnu àwẹ̀. Láti ibí ni orin fújí jáde. Lára àwọn olórin ilẹ̀ Yorùbá tí ó ń lo Sákárà nínú orin rẹ̀ pẹ̀lú gòhé ni Yusuf Ọlátúnjí. [1]

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. "Sakara Music By Yusufu Olatunji Vol. 1". Discogs. Retrieved 2019-12-28.