Urea cycle

(Àtúnjúwe láti Ìpòyì urea)

Urea cycle (tí wọ́n tún mọ̀ sí ìpòyì ornithine) jẹ́ ìpòyì àwọn ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà àgọ́ ara tí ó má a ń ṣẹlẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko tí ó máa ń jẹ́ kí urea ((NH2)2CO) jade láti inú ammonia (NH3). Ìyípo yìí jẹ́ ìpòyì ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà àgọ́ ara àkọ́kọ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ ṣàwárí (Hans Krebs àti Kurt Henseleit, 1932), ní ọdún marún sẹ́yìn kí wọ́n tó ṣàwárí Ìyípo TCA.[1] Ní àwọn ẹranko tó lè bímọ, ìyípo urea máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀dọ̀, bíi díẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nínú kídìrín.

Ìṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Àwọn oun ẹlẹ́mí tí kò rọrùn fún láti yọ ammonia kúrò lára máa ń sọọ́ dí àwọn nkan míràn bíi urea tàbí uric acid, tí kò ní májèlé púpọ̀.[2] Àìtó ìyípo urea yìí  máa ń wáyé látàrí àṣìṣe ìbínimọ́ (àṣìṣe ìbínimọ̀ nínú ara), àti tí ẹ̀dọ̀ bá dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Èsì ìdáwọ́ iṣẹ́ ẹ̀dọ̀ dúró ní ìkójọpọ̀ àwọn ẹ̀gbin tí ó ní ṣe pẹ̀lú nitogen, pàtàkì jùlọ ammonia, tí ó máa ń fa ààrùn hepatic encephalopathy.

Àwọn ìbáṣepọ̀

àtúnṣe

Ìyípo urea ní àwọn ìbáṣepọ̀ marún: méjì ń ṣẹlẹ̀  nínú mitochondra tí mẹ́ta sì ń ṣẹlẹ̀ nínú  cytosol. Ìyípo yìí máa ń sọ àwọn ẹgbẹ́  amino méjì, ìkan láti NH4+ àti ìkan lati  Asp, àti átọ́mù carbon kan láti HCO3, sí àwọn ẹ̀gbin tí kò ní májèlé urea ní iye "agbára nlá"  àwọn àsopọ̀ phosphate ( ATP mẹ́ta tí ó pín sí ADP méjì àti AMP ẹyọ kan). Ornithine ló máa ń gbé àwọn átọ́mù carbon àti nitrogen yìí.

Àwọn ìbạ́ṣepọ̀ àwọn ìyípo urea
Ìgbésẹ̀ Àwọn ìbáṣe
Àwọn èsì
tí ó mú ìlọsíwájú báa Ibi tó wà
1 NH3 + HCO3 + 2ATP carbamoyl phosphate + 2ADP + Pi CPS1 mitochondria
2 carbamoyl phosphate + ornithine citrulline + Pi OTC mitochondria
3 citrulline + aspartate + ATP argininosuccinate + AMP + PPi ASS cytosol
4 argininosuccinate Arg + fumarate ASL cytosol
5 Arg + H2O ornithine + urea ARG1 cytosol
Àwọn ìbáṣepọ̀ ìyípo urea
 

1 L-ornithine 2 carbamoyl phosphate 3 L-citrulline 4 argininosuccinate 5 fumarate 6 L-arginine 7 urea L-Asp L-aspartate CPS-1 carbamoyl phosphate synthetase I OTC Ornithine transcarbamoylase ASS argininosuccinate synthetase ASL argininosuccinate lyase ARG1 arginase 1

Ní ìbáṣepọ̀ àkọ́kọ́, NH4+ + HCO3 jẹ́  NH3 + CO2 + H2O.

Gbogbo oun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìyípo urea jẹ́:

  • NH3 + CO2 + aspartate +  ATP mẹ́ta+  H2O méjì→ urea + fumarate +  ADP méjì+  Pi méjì+ AMP + PPi

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́pé a máa ń rí fumarate tí a bá yọ NH3 kúrò nínú aspartate (nínú ìbáṣepọ̀ kẹta àti ìkẹrin), àti PPi + H2O →  Pi méjì, ó lè rọrùn báyìí:

  •   NH3 méjì + CO2 +  ATP mẹ́ta + H2O → urea +  ADP méjì + Pi  mẹ́rin + AMP

Ìmọ̀ nípa àìsan tí ó rọ̀ mọ

àtúnṣe

Ìṣàìtó àwọn enzymes àti àwọn ọlọ́kọ̀ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìyípo urea lè fa àwọn àìsàn tí ó rọ̀ mọ́ ìyípo urea bíi:

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Dr. B.S. Chauhan (1 January 2008). Principles of Biochemistry and Biophysics. Firewall Media. pp. 606–. ISBN 978-81-318-0322-6. http://books.google.com/books?id=iVr0HWkAdS8C&pg=PA606. 
  2. B. D. Hames; N. M. Hooper (2005). Biochemistry. Garland Science. pp. 407–. ISBN 978-0-415-36778-3. http://books.google.com/books?id=dmkdDMRaR3UC&pg=PA407.