Ìsìnrú ní Rómù àtijọ́

Ìsìnrú ní Róòmù àtijó kó ipa pàtàkì ní àwùjọ àti ètò ọrọ ajé Róòmù. Yàtò sí lílò wọ́n láti ṣe iṣẹ́ agbára, wọ́n lọ àwọn ẹrú fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ilé àti fún àwọn iṣẹ́ ọpọlọ míràn. Àwọn tí ó ń ka owó àti àwọn oníṣègùn nígbà náà jẹ́ ẹrú. Àwọn ẹrú tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Gríkì ma ń sábà jẹ́ alákọ̀wẹ́. Àwọn tí kò jẹ́ ọ̀mọ́wẹ́ ma ń ṣisẹ́ nínú ọkọ, ilẹ̀ kùsà.

Òfin Róòmù àtijọ́ ka àwọn ẹrú gẹ́gẹ́ bi ohun ìní, wọn kò sì ní àṣẹ sí ayé ara wọn. Wọn kìí tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú sílẹ̀, àwọn olówó wọn sì láṣẹ láti fìyà jẹ wọ́n, lò wọ́n fún ìbálòpọ̀ tí kò tó, sọ wọ́n di aṣẹ́wó, náà wọ́n tàbí pa wọ́n. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ̀wẹ̀, àwọn ẹrú bẹ̀rẹ̀ sí ń ní àwọn òmìnira kọ̀kan lábé òfin, pẹ̀lú pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìwà àwọn olówó wọn tí kò tó lé òfin létí.

Ọ̀nà gbòógì tí Róòmù fi ń rí ẹrú ni nípa kíkó ẹrú lójú ogun.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe