Oníṣègùn tàbí oníwòsàn tàbí dókítà ni ẹnìkan tí o n siṣẹ́ ìwòsàn.

Jan Havicksz Steen


Oníṣègùn ní ilẹ̀ Yorùbá

àtúnṣe

Ní ilẹ̀ Yorùbá oníṣègùn ni ẹni tí ó nímọ̀ nípa tewé tegbò ìbílẹ̀, yálà ó jogún bá ìmọ̀ náà ni tàbí ó lọ kọ́ọ lọ́dọ̀ àwọn tónímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ká lo tewé tegbò láti fi ṣe itúsílẹ̀ ẹ̀dá kúrò lọ́wọ̀ àìsàn aṣẹ̀míófò gbogbo. Wọ́n sì yàtọ̀ sí Adáhunṣe.

Ìyàtọ̀ láàrín Babaláwo àti Oníṣègùn

àtúnṣe

Ẹ̀wẹ̀, àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ yàtọ̀ sí àwọ́n Babaláwo tàbí àwọn onífá, nítorí Ifá nìkan ni àwọn Babaláwo ma ń dá tí wọn yóò sì ka nǹkan ètùtù nígbà tí Ifá náà bá yan ǹkan ètùtù fún ẹni tí wọ́n dífá fún. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Babaláwo ló ma ń báni ṣètùtù, àyàfi tí Ọ̀rúnmìlà bá fòté le wípé Oníṣègùn kannpàtó ló gbọ́dọ̀ rúbọ náà. Iṣẹ́ àwọn oníṣègùn ni kí wọ́n tọ́jú aláìsàn pẹ̀lú oògùn ìbílẹ̀ oríṣiríṣi tí wọ́n ti pèsè láti ara ewé àti egbò tí ó le wo àrùn tàbí àìsàn náà sàn. Àwọn iníṣègùn kìí dífá yanbọ fúni rárá, àmọ́ eọ́n ma ń gbowọ́ ọ̀yà lẹ́yìnbtí eọ́n bá ṣe ìtọ́jú aláàrẹ̀ tán gẹ́gẹ̀ bí èrè iṣẹ́ wọn.Àwọ̀n ìtòka sí

àtúnṣe