Ìsopọ̀ kẹ́míkà
Ìsopọ̀ kẹ́míkà ni ìfàmọ́ra láàrin àwọn átọ̀mù tó gba ààyè ìdá àwọn kẹ́míkà tí wọ́n ní átọ̀mù méjì tàbí mẹ́ta. Ìsopọ̀ náà sẹlẹ̀ nítorí agbára ẹlẹktrostátìkì ìfàmọ́ra láàrin àwọn àgbéru olódì, bóyá láàrin àwọn ẹ̀lẹ́ktrọ̀nù àti núkléù, tàbí gẹ́gẹ́bí ìdá ìfàmọ́ra ipoméjì. Agbára àwọn ìsopọ̀ kẹ́míkà jẹ́ orísirísi; àwọn "ìsopọ̀ líle" bíi àjọfagbáradìmú tábí íónì wà àti àwọn "ìsopọ̀ dídẹ̀" bíi ìbáṣepọ̀ ipoméjì sí ipoméjì, agbara ìfọ́nká London àti ìsopọ̀ háídrójìn.