Átọ̀mù je eyo kan ipile èlò ni a mo si ohun to kere julo fun awon apilese (element). Bo tile je pe atomu ni ede Griki tumosi eyi ti ko se fo si wewe, imo atomu nisinyi ni pe awon ohun abeatomu miran tun wa:

Helium atom
Helium atom ground state.
Helium atom ground state.
An illustration of the helium atom, depicting the nucleus (pink) and the electron cloud distribution (black). The nucleus (upper right) in helium-4 is in reality spherically symmetric and closely resembles the electron cloud, although for more complicated nuclei this is not always the case. The black bar is one ångström, equal to 10−10 m or 100,000 fm.
Classification
Smallest recognized division of a chemical element
Properties
Mass range: 1.67 × 10−27 to 4.52 × 10−25 kg
Electric charge: zero (neutral), or ion charge
Diameter range: 62 pm (He) to 520 pm (Cs) (data page)
Components: Electrons and a compact nucleus of protons and neutrons
  • atanná (electron), eyi ni agbara ina alapaosi, ọ̀pọ̀ re si kere ju awon yio ku lo.
  • àkọ́wá (proton), eyi ni agbara ina alapaotun, opo re si je ni ona 1836 ju atanna lo.
  • alaigbara (neutron), eyi ko ni agbara ina kankan, opo re si to bi ti akowa.

Akowa ati alaigbara ni won po ti won kun inu inuikun atomu (atomic nucleus) a si n pe won ni abikun (nucleons). Nigbati atanna si parapo da ìsú atanna to yipo inuikun.

O se se ki atomu o yato nipa iye awon ohun abeatomu ti won ni. Atomu ti won ni apilese kanna ni iye akowa kanna (ti a mo si nomba atomu). Fun apilese kan pato, iye alaigbara yato, eyi si ni n so bi olojukanna (isotope) apilese na yio se ri. Atomu ko ni agbara ina kankan ti iye akowa ati atanna won ba dogba. Atanna ti won jinna julo si inuikun atomu se gbe lo si odo atomu miran to wa ni tosi won tabi ki won o je pin larin awon atomu o hun. Bayi ni awon atomu se n sopo lati di ẹyọ (molecule). Fun apere eyo kan omi je akopapo atomu meji hydrogen ati atomu kan oxygen. Atomu ti atanna won ku die kato tabi to po ju bose ye lo ni an pe ni ioni. Ona miran ti iye akowa ati alaigbara fi le yipada ninu inuikun atomu ni yiyo inuikun (nuclear fussion) tabi fífọ́ inuikun (nuclear fission).

Atomu je ipilese ti ẹ̀kọ́ egbò (chemistry) duro le lori, be ni won si kopamo (conserve) ninu adapo elegbo (chemical reaction).

Atomu ati eyo

àtúnṣe

Fun awon elefufu (gas) ati onisisan (liquid) ati onilile (solid) eleyo (molecular) (fun apere omi ati suga), eyo je ipin to kere julo ohun ti o ni idamo elegbo.