Ìwọ́ ìtanná tabi ìwọ́ iná ni bi àdìjọ ìtanná se n sàn kiri. Ẹyọ ìwọ̀n SI fun ìwọ́ iná ni ampere (A), to dọ́gba mọ́ sísàn kiri coulomb kan agbára iná ní ìsẹ́jú àáyá.

Ìtumọ̀

àtúnṣe

Iye ìwọ́ iná (ti a wọ̀n ní ampere) ti o n gba òdeojú (surface) kan kọ já ni iye agbára iná (ti a wọ̀n ní coulombs) ti o n sàn kiri l'òdeojú na láàrin àsìkò kan. Tí Q bá jẹ́ iye agbára iná tó kọ já l'òdeojú na láàrin àsìkò T, nípa bayi àriniye (average) ìwọ́ iná I jẹ́:

 

Tí a bá jẹ́ kí ìwọ̀n àsìkò T kí ó dín títí títí dé òdo, á nìí ìwọ́ iná ẹ̀kanáà (instantaneous) i(t) gẹ́gẹ́ bi:

 

Ìwọ́ iná nínú wáyà onípánù (metal wire)

àtúnṣe

Nínú àwọn wáyà onípánù (Agbéiná – electrical conductor) tí wón gba agbára iná láàyè, ogunlọ́gọ̀ àwon atanná (electron) ni wọ́n rìn kiri lọ́fẹ̀ẹ́lófòò (atanná ọ̀fẹ́). Àwọn atanná wọ̀nyí kò sopọ̀ mọ́ átọ́mù kankan.

Òfin Ohm

àtúnṣe

Òfin Ohm n tọ́kasí ìbásepọ̀ tó wà láàrin ìgbanná (Voltage), ìwọ́ iná ati ìdinà iná (electrical resistance):

 

nígbàtí,

I jẹ́ ìwọ́ iná, ni ìwọ̀n ampere
V jẹ́ ìgbanná (ìyàtọ̀ ìlókun) (potential difference), ní ìwọ̀n volt
R jẹ́ ìdinà iná, ní ìwọ̀n ohm

Àpẹrẹ

àtúnṣe

Àpẹrẹ ìwọ́ iná ti a le fojuri ni mọ̀nàmọ́ná (lightning) ati ìjì ojúòòrùn (solar wind). Bakana iwo ina ti a mọ̀ ni sisan atanna ninu okùn onírin, fun apere awon waya opo ina to n gbe ina lati ibikan de ibo miran ati awon waya kekeke ninu awon ero onina (electronics), ati bi atanna se n san koja ninu adena ina (resistor), sisan kiri ioni (ion) ninu bátìrì (battery) ati sisan kiri iho ninu agbeinadie (semiconductor).

 
Gẹ́gẹ̀ bi òfin Ampère se sọ, ìwọ́ ìtanná n fa pápá onínágbérigbérin.

Inágbéringbérin (electromagnetism)

àtúnṣe

Ìwọ́ iná n pese pápá gbéringbérin (magnetic field). A le wo papa gberigberin bii ọ̀pọ̀ ìlà to yi waya po.