Òṣùpá (aami: ☾) jẹ́ olùyípo (satellite) ilẹ̀-Ayé. Arinidaji jíjìnnà sí láti ilẹ̀-ayé títí dé orí òṣùpá jẹ́ kìlómítà 384,403. Ìwọ̀n ìdábùú òbírí yìí fi ìlọ́pò ọgbọ̀n jù ti ilẹ̀-ayé. Ìlà-àárín òṣùpá jẹ́ kìlómítà 3,474 - tó jẹ́ pé díẹ̀ ló fi jù ọ̀kan nínú mẹ́rin lọ sí ti ilẹ̀-ayé. Èyí sì jẹ́ pé kíkún-inú (volume) òṣùpá jẹ́ ìdá àádọ́ta péré ti ilẹ̀-ayé. Fífà ìwúwosí rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́fà sí ti ilẹ̀-ayé. Òṣùpá ń yípo ilẹ̀-ayé ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọjọ́ 27.3 (1 oṣù; ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé ní wákàtí mẹ́ta).

Òṣùpá
Òṣùpá ati Ilé-ayé