Ẹ̀fọ́

Ipẹtẹ Ewebe ọlọrọ ni Ilu Naijiria ti o jẹ abinibi si awọn ilu ti Iwo -oorun Naijiria.O tun pe ni bimo Ewebe.

Ẹ̀fọ́ ni irúfẹ́ àwọn ewébẹ̀ tí ó ṣe é jẹ fún ọmọnìyàn tàbí ẹranko gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ. Ẹ̀fọ́ lè jẹ́ ewé ara igi, ewé tí ó lalẹ̀ ju, òdòdó igi tàbí ìtàkùn igi, ewé èsò igi tàbí igi gan an fúnra rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ lọ. [1] Orísiríṣi ewébẹ̀ ni ó wà tí a tún lè pè wọ́n ní ẹ̀fọ́. Ìdàgbà-sókè ọrọ̀ ajé ati kárà-kátà ni ó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀fọ́ orísiríṣi wọ kọ̀rọ̀-kọ́ndú ibi tí wọn kò ti sí tẹ́lẹ̀. Ní nkan bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọdún sí ẹgbẹ̀rún méje ọdún sẹ́yìn, irúfẹ́ àwọn ẹ̀fọ́ tí wọ́n wà nígbà náà a má a jẹ́ àwọn ẹ̀fọ́ ajẹmádùúgbò. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo ti yí padà látàrí okòwò ati ọrọ̀ ajé tí kálukú fi ń mú ohun tí ó wà lágbègbè rẹ̀ fi ṣe ọrọ̀ ajé pẹ́lú Àwọn ìran mìíràn tí wọn kò ni. Èyí ti mú kí kálukú náà ti ma ṣe ògbìn ẹ̀fọ́ tí kò sí ní agbègbè wọn fún jíjẹ tàbí títà.

Vegetables in a market in the Philippines
Vegetables for sale in a market in France

A lè jẹ ẹ̀fọ́ láìsèé tàbí kí wọ́n tún ṣe é lọ́jọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìsebẹ̀ míràn lórí iná fún jíjẹ. Ipa tí ẹ̀fọ́ ń kò nínú gẹ́gẹ́ bí èròjà aṣaralóore kò kéré, àwọn onímọ̀ ìlera a sì ma gba àwọn ènìyàn níyànjú pe kí wọ́n ma jẹ èso tàbí ewébẹ̀ tabi ẹ̀fọ́ dára dára fún ìlera tó péye.


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "vegetable". Cambridge Dictionary. 2024-10-23. Retrieved 2024-10-28.