Ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn ní Zimbabwe
Ọ̀pọ̀ àwọn àfisùn ni ó ti wà nípa rírẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ènìyàn je ní Zimbabwe lábẹ́ ìjọba Robert Mugabe àti ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀, ZANU-PF, láàrin ọdún 1980 sí 2017.
Gégé bí àgbéjáde tí àjọ Amnesty International àti Human Rights Watch ṣe, Zimbabwe kò bọ̀wọ̀ fún ètọ́ sí ilé, oúnjẹ, àti àwọn ètọ́ míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlù ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníròyìn, olóṣèlú àtakò, àti àjà fún ètọ́ mẹ̀kúnù.
Àwọn ọlọ́pá ma ń sábà ṣe ìkọlù sí ìpéjọpọ̀ àwọn alátakò, àpẹẹrẹ rẹ̀ ni sí ìwóde Movement for Democratic Change (MDC) ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2007. Ní ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, adarí ẹgbẹ́ náà, Morgan Tsvangirai àti àwọn ọ̀kàndínládọ́ta míràn ni àwọn ọlọ́pá gbé, wọ́n sì tún nà wọ́n. Edward Chikombo, oníròyìn kan tí ó rán fọ́tò bí àwọn ọlọ́pá ṣe na àwọn oníròyìn náà sí ilé ìròyìn ní orílẹ̀ èdè míràn sọ èmí rẹ̀ nù nígbà tí wọ́n jí gbé tí wọ́n sì pá lẹ́yìn ọjọ́ díè lẹ́yìn tí ó rán fọ́tò náà.[1] Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tú Morgan Tsvangirai sílẹ̀, ó sọ fún ìròyìn BBC pé òun ṣeṣe ní orí, òun sì tún sọ ẹ̀jẹ̀ nù. Adarí àgbà, Ban Ki-moon, European Union àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi àìdùnú wọn hàn sí ọ̀rọ̀ náà.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Zimbabwe journalist murdered 'over leaked Tsvangirai pictures'", The Independent, 4 April 2007
- ↑ BBC (14 March 2007). "Unbowed Tsvangirai urges defiance". BBC News. http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/6449691.stm.