Ẹgbẹ́ Awakọ̀ ojú pópó (NURTW)

Ẹgbẹ́ Awakọ̀ ojú pópó (NURTW) jẹ́ àgbáríjọ ẹgbẹ́ gbogbo ọlọ́kọ̀-èrò tó dá dúró lábẹ́ ẹgbẹ́ Oníṣe ọwọ́ nilẹ̀ Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ yí wà fún láti mú ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrín àwọn ọlọ́kọ̀-èrò ojú pópó, gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ inú òfin wọn.[1] [2]

Ìṣàkóso ẹgbẹ́ wọn

àtúnṣe

Ẹgbẹ́ yí ní àwọn adarí tí wọ́n jẹ́ ti àpapọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ní ẹsẹ̀ kùkú (ìpínlẹ̀ sí ìpínlẹ̀). Ààrẹ àti adarí wọn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Alhaji Tajudeen Baruwa,nígbà tí wọ́n ní àwọn adarí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ẹni tí ó jẹ́ adarí ti ìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ Musiliu Ayinde Akinsanya tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí MC Oluomo. Ṣíṣàkóso ẹgbẹ́ yí ni Akọ̀wé àgbà àpapọ̀ ẹgbẹ́ yí ma ń ṣàtìlẹyìn tí ó sì ń gbẹnusọ láàrín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti Ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ kí ètò ìṣèjọba tó lọ́ọ̀rìn ó lè wà láàrín wọn. [3]

Ọ̀na ìpawó sele wọn

àtúnṣe

Ẹgbẹ́ yí ma ń pawó wọlẹ́ sínú àpò ẹgbẹ́ wọn látara ọrẹ àtinúwá ọmọ ẹgbẹ́, nípa gb yiiiiiii gbígba owó ìgbà ní-wọlé ọmọ ẹ̀gbẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Owó tí wọ́n bá pa nínú ẹgbẹ́ ni wọ́n fi ń ṣe ètò ìróni lágbára, ìlanilọ́yẹ̀ lórí ètò abo ojú-pópó àti ọ̀nà ìbá olùbárà dòwò pọ̀.[4]

Ojúṣe Ẹgbẹ́ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́

àtúnṣe

Lára pàtàkì ojúṣe ẹgbẹ́ ni kí wọ́n dáàbòbò ẹ̀tọ́ ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan níbí kíbi.

Rúkè-rúdò inú ẹgbẹ́ y í

àtúnṣe

Wọ́n mọ ẹgbẹ́ awakọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mọ́ jàgídí jàgan nítorí ìjẹ gàba àti àwọn Àkàní mìíràn bíi: jẹgúdú jẹrá, ìlọ́nilọ́wọ́ gbà, àti ojú ìsájú. Gbogbo ìwọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ oníròyìn ọmọ ilẹ̀ American-British Louis Theroux ṣàfihàn rẹ̀ nínú 2010 documentary film.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Protesting Lagos NURTW members reject MC Oluomo – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2019-12-21. 
  2. "NURTW Archives - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2019-12-21. 
  3. "MC Oluomo inaugurated as Lagos NURTW chairman". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-10-11. Retrieved 2019-12-21. 
  4. "::NURTW::". Access Solutions. Archived from the original on 2019-12-07. Retrieved 2019-12-21.