Ẹyọ Esua
Eyo Ita Esua (Wọ́n bi ní Ọjọ́ kẹrìnla Oṣù Kìíní Ọdún 1901, ó fi ayé sílẹ̀ ní Ọjọ́ kẹfà Oṣù Kejìlá Ọdún 1973. Ó jẹ́ Olùkọ́ ní Ìlú Nàìjíríà àti Oníṣòwò tó kọ ipá ní ìgbà ìjọba Balewa ní Fẹ́dírá Ẹ̀lẹ̀tórá kọmíṣọ́nù ní Nigerian First Republic.[1]
Eyo Esua | |
---|---|
Chairman of the Federal Electoral Commission | |
In office 1964–1966 | |
Arọ́pò | Michael Ani |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Eyo Ita Esua 14 January 1901 Cross River State, Nigeria |
Aláìsí | 6 December 1973 | (ọmọ ọdún 72)
Esua jẹ́ Olórí àwọn Olùkọ́ àti ènìyàn tó wà lára àwọn olùdásílẹ̀ àjọ Nigeria Union Of Teachers. Òun ní ó kọ́kọ́ jẹ́ Gẹ́nẹ́rá-Sẹkẹ́tírí Àjọ náà láti ọdún 1943 títí di ìgbà tó fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1964. Ó Jẹ́ Ọmọ Efik, Arákùnrin Kàlàbá, tí àwọn ènìyàn mọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ takuntakun rẹ̀.[2]
Àwọn Àjọ tí Esua ṣíwájú ló ṣe ètò Ìdìgbò Oṣù Kejìlá ọdún 1964, tí ó jé àríyànjiyàn láàárín ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Àwọn ènìyàn méjì lára àjọ yìí ò gbà sí ohùn tí ọ̀gá wọ́n sọ, èyí ló fà á tí àwọn méjéèjì fi kúrò ní àjọ náà. Esua wà lára àwọn tó ṣètò ìdìbò Ìwọ̀-Òòrùn ìlú Nàìjíríà ní ọdún 1965, tó fa wàhálà àti wí pé àwọn páátí kejì tó jẹ́ United Party Grand Alliance ò gbà sí àbájáde ìdìbò yìí.[3] kí ó tó di Ọjọ́ ìdìbò ni Esua ti sọ wí pé òun ò lè sọ wí pé ìbò tí àwọn fẹ́ ṣe máa jẹ ìbò tó ní òótọ́ nínú.[4] Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìbò yìí lè jẹ́ ohun tó jẹ́ kí ìjọba Ológun gba ìlú Nàìjíríà ní Oṣù Kìíní Ọdún 1966 tí ó jẹ́ kí Ọ̀gágun Johnson Aguiyi-Ironsi gù orí oyè.[5]
References
àtúnṣe- ↑ Imam Imam (9 June 2010). "Past INEC Chairmen". ThisDay. Retrieved 2010-06-10.
- ↑ Remi Anifowose (1982). Violence and politics in Nigeria: the Tiv and Yoruba experience. Nok Publishers International. ISBN 0-88357-084-X. https://archive.org/details/violencepolitics00anif_0.
- ↑ Olukorede Yishau (2010-06-09). "Will he make the difference?". The Nation. Archived from the original on 2010-06-11. Retrieved 2010-06-10. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Herbert Ekwe-Ekwe (1990). The Biafra war: Nigeria and the aftermath. E. Mellen Press. p. 39. ISBN 0-88946-175-9.
- ↑ "ELECTORAL COMMISSION THROUGH THE YEARS". NBF News. 7 Jun 2010. Retrieved 2010-06-10.