Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá àgbéléwò, olùgbéré jáde ati Olùkọ́ àgbà fásitì.

Ìgbésí ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀Àtúnṣe

Wọ́n bí Akínwálé ní Ìlú Ìbàdàn, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wàá ti Methodist High School àti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àgbà ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti ìlú Ìbàdàn.[1] Ó tún jẹ́ adarí ẹ̀ka ètò-ẹ̀kọ́ ti Faculty of Arts and Culture ní University of Ilorin.[2][3] Ọ̀jọgbọ́n Akínwálé nígbà ayé rẹ̀ tún jẹ́ alága fún ìgbìmọ̀ àwọn oníṣẹ́-ọnà (Council for Artand Culture) ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Bákan náà ni ó ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn eré ọdún ìbílẹ̀ oríṣiríṣi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ìtàgé rẹ̀ ní ọdún 1970s níbi tí ó kópa ní àwọn eré sinimá orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán àti àwọn eré ìtagé mìíràn.[1] Ó ti gba àmì ẹ̀yẹ ìdánọ́lá ti 4th Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́kẹrin irú rẹ̀ níbi tí wọ́n ti yàán gẹ́gẹ́ bí òṣèré orí-ìtàgé ọkùnrin tí ó peregedé jùlọ..[4]

Àwọn sinimá tí ó ti ṣeÀtúnṣe

  • Sango (1997)
  • Ladepo Omo Adanwo (2005)
  • Iranse Aje (2007)

Ikú rẹ̀Àtúnṣe

Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwálé ṣaláìsí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàán ọdún 2020.

Àwọn ìtọ́ka síÀtúnṣe

  1. 1.0 1.1 "Professor Ayo Akinwale". Dawn Commission. Retrieved August 29, 2015. 
  2. "Don Tasks Nollywood on Professionalism". thisdaylive.com. Archived from the original on 15 November 2014. Retrieved 15 November 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Lecturers as Nollywood Stars". modernghana.com. Retrieved 15 November 2014. 
  4. "Between Film And Professionalism". thisdaylive.com. Archived from the original on 15 November 2014. Retrieved 15 November 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)

Àwọn Ìtàkùn ìjásódeÀtúnṣe

Àdàkọ:Authority control