Ìkìlọ̀ pàtàkì àtúnṣe

@Adeseyoju Deborah , mo fẹ́ fi àsìkò yí ṣe ìkìlọ̀ fún ọ wípé a kò fàyè gba lílo irinṣẹ́ Google Translation lórí Wikipedia èdè Yorùbá. Kí n sì tún fi asiko yí kìlọ̀ fún o láti dẹ́kun lílòó láti máa fi dá àyokà sí orì Wiki yí. Bí o bá nílò ìrànwọ́ tàbí ìdániĺkọ̀ọ́ lórí bí a ṣe lè dá àyokà tuntun sílẹ̀ láì lo Google Translation, jọ̀wọ́ kàn sìi. Fúndìí èyí, mo rọ̀ọ́ kí o mà ṣe dá àyọkà míràn sílẹ̀ mọ́ títí o ó fi ṣe àtúnkọ àwọn àyọkà tí o ti ṣ'ẹ̀dá látara lílo Google Translation kí́ ó lè dunúnkà fún àwọn olólùfẹ́ Wikipedia èdè Yorùbà. Bì́ o bá tún ṣ'ẹ̀dá àyọkà mìràn, èyí lè mú kí a gbé ìgbéssẹ̀ tí ó nípọn lórí àwọn iṣẹ́ rẹ tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀. O ṣeun púpọ̀.Agbalagba (ọ̀rọ̀) 12:06, 3 Oṣù Kẹrin 2024 (UTC)Reply

@àgbàlagbà, Mo tọọrọ àforíjì fún awọn àyọkà tí mo ti gbéjáde lórí Wikipedia tí kò ṣe déédé. Mo lóyè pàtàkì àkọsílẹ̀ ti ó dára lórí pẹ́pẹ́, àti pé mo kábàámọ̀ èyíkéyìí àìrọrùn tàbí rúdurùdu àwọn àyọkà mi lè ti fà.

Mo fẹ́ fi dá yin lójú pé èmi yóò ṣe àtúnyẹ̀wò àti àtúnṣe àwọn àyọkà ti Mo ti firánṣẹ́ tẹ́lẹ̀ láti ríi dájú pé wọ́n pàdé àwọn ìtọ́nisọ́nà dídára Wikipedia.  Ní àfikún, ṣáájú sísẹ̀dá èyíkéyìí awọn àyọkà tuntun, Èmi yóò gba àkokò tó wúlò láti ṣe ìwádìí ní kíkún àti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àyọkà tuntun.
Ẹ ṣeun púpọ̀ fún oye yín, àti pé nígbà kúgbà tí mo bá ṣe àṣìṣe lórí àyọkà mi ẹ jọ̀wọ́ ẹ máa tọ́ mi sọ́nà. Ẹ ṣeun púpọ̀.