Tesleemah
Àkíyèsí pàtàkì
àtúnṣeA kú déédé ìwòyí oníṣẹ́ Tesleemah. Mo ṣàkíyèsí àwọn akitiyan àti ìlàkàkà yín láti ma ṣe àfikún sí Wikipedia èdè Yorùbá, inú wa sì dùn láti ri wípé ẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣáájú, àwọn àkíyèsí mi nípa àwọn àfikún yín rèé:
- Àwọn àyọkà yín ti ẹ kọ kò gún régé.
- Àgbékalẹ̀ àyọkà náà kò bójú mu.
- Àgbékalẹ̀ àyọkà yín kò bá agbékalẹ̀ èdè Yorùbá mu.
- Ìṣọwọ́kòwé Yorùbá yín kò yàtọ̀ sí ti ẹ̀rọ abánikọ̀wé.
Ẹ wo àyọkà ònkọ̀wé aláfikún ẹgbẹ́ yín Ọmọladéabídèmí99 yí [1] àti àyọkà tèmi yii náà [2] bí wọ́n ṣe ṣe agbékalẹ̀ wọn fún itọ́ni yín bí a ṣe ń kọ èdè Yorùbá. Fúndí èyí, mo ma rọ̀ yín kí ẹ lọ ṣe àtúnṣe tí ó yẹ sí àwọn àyọkà yín tuntun tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yí Ogechi Adeola àti Olubukola Mary Akinpelu dára dára kí wọ́n lè mọ̀yán lórí jù báyìí lọ.
Láfikún, mo ma gbà yín níyànjú kí ẹ ma kọ àwọn àyọkà yín síbìkan kí ẹ sì ma yẹ̀ wọ́n wò dára dára kí ẹ tó ṣẹ̀dá wọn sórí Wikipedia èdè Yorùbá. Èyí yóò jẹ́ kí ẹ mọ àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ tí ó wà nínú wọn lásìkò, èyí kò sì ní ma là yín lóòógùn.
Mo fẹ́ kí ẹ tètè ṣe ìgbésẹ̀ lórí àkíyèsí mi yí ní kánmọ́ kánmọ́. Bí ọjọ́ mẹ́ta bá kọjá lẹ́yìn akíyèsí yìí tí n kò sì rí àtúnṣe lórí wọn, n ó dárúkọ àwọn àyọkà náà fún ìparẹ́.
Àtúnṣe sì àwọn àyọkà
àtúnṣeEse ún @Agbalagba,Máa ṣé àtúnṣe síi àwọn àyọkà náà gẹ́gẹ́bí bí ó ṣé yẹ. Eku ìṣe takun takun. Tesleemah (ọ̀rọ̀) 04:50, 8 Oṣù Kàrún 2024 (UTC)