== Ẹkáàbọ̀!

Ẹpẹ̀lẹ́ o, Zend2020,ẹkáàbọ̀ sí Yòrùbá Wikipedia!! Adúpẹ́ fún àfikún yín. Mo lérò wípé ẹ nífẹ́ sí kí ẹ wà níbí. Ẹwo àwọn oun tí a ṣètò sí ìsàlẹ̀ yìí bóyá ó lè wúlò fun yín:

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí fi òǹtẹ̀ tẹ oun tí ẹ bá kọ sí ọ̀rọ̀ ojú ewé pẹ̀lú igun mẹ́rin (~~~~); èyí máa gbé orúkọ yín àti déètì jáde. Bí ẹ bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ ẹ kàn sí mi, +/-, mo sì máa ràn yín lọ́wọ́, ẹkáàbọ̀! Agbalagba (ọ̀rọ̀) 20:25, 13 Oṣù Kẹfà 2021 (UTC)

E se gan --Zend2020 (ọ̀rọ̀) 20:39, 13 Oṣù Kẹfà 2021 (UTC)

Àkíyèsí

àtúnṣe

Ẹ n lẹ́ oo Oníṣe:zend2020, amì yín kú iṣẹ́ takun takun, amọ́ a fẹ́ kí ẹ gbìyànjú kí ẹ lọ ṣe àyípadà àwọn àyọkà titun tí ẹ da sílẹ̀ sí orí Wiki yí, nítorí irinṣẹ́ Google ni ẹ ló láti fi ṣe ògbufọ̀, a kò sì fẹ́ irú rẹ̀ ní ojú-ewé wa. Ẹ ṣeun púpọ̀Agbalagba (ọ̀rọ̀) 16:47, 18 Oṣù Keje 2021 (UTC)

E seun pupo fun leta amo mi o lo Google .Ti a ba kaa awon atunse wo yii te ba fi si ori google e ma ripe gbogbo oro ti o ba ara won mo ni mo fii le eyin ti Google lo ti o ni itumo ni mo. Bi apere Sepeteri mo mu article Wikipedia ti Oyibo copy and paste line by line ni mo fi tumo e.Eyi oku ni mo lo translation ti Wikipedia se ti mo yoo awon Google translation .O daa bi pe o da yi loju pe Google ni mo lo,bi e se ni ipinu ni mo fe moo nitori mo mo ise ti mo se lori awon kiini yi. Nitori e mo pe ti yan pa lo Google translation 100% ko ni se atejade ,see e sope kaa yo gbogbo Google translation kuro ta baa lo translationti Wikipedia?Zend2020--Zend2020 (ọ̀rọ̀) 18:02, 18 Oṣù Keje 2021 (UTC)

  • Ó dára, ẹ kú iṣẹ́ náà. Mo ri wípé gbogbo ohun tí ẹ ń ṣe pátá ni ó ń túmọ̀ sí wípé ẹ ń gbìyànjúláti mú ìdàgbà-sókè bá Wikipedia èdè Yorùbá. Àmọ́ n kò fẹ́ dá yín lágbara, màá gbà yín níyànjú kí ẹ má ṣe dá àyọkà tuntun míràn sílẹ̀ mọ́ lásìkò yí kí á fi ṣe àtúnṣe sí àwọn èyí tí wọ́n ti wà nílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ lè ma ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ pẹ̀ pẹ́ sì àwọn ayọkà tí ó kú diẹ̀ káàtó fún títí a ó fi rí ọ̀nà àbáyọ sí àwọn àyọkà yí. Èyí kìí ṣe láti tàbùkù yín rárá o, ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣì mí gbọ́. Mo wà nítòsí fún yín bí ẹ bá nílò ìrànwọ́ lórí ohun kan tàbí òmíràn. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún iṣẹ́ takun takun yín.Agbalagba (ọ̀rọ̀) 10:28, 19 Oṣù Keje 2021 (UTC)