Ọbáfẹ́mi Martins

Ọbáfẹ́mi Akínwùnmí Martins tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1984 (28th October 1984) jẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Àfẹsẹ̀gbá ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó máa ń gbá Bọ́ọ̀lù Àfẹsẹ̀gbá ni ipò Agbábọ́ọ̀lù-sáwọn.

Obafemi Martins
Martins Llevant.jpg
Martins playing for Levante in 2012
Personal information
OrúkọObafemi Akinwunmi Martins[1]
Ọjọ́ ìbí28 Oṣù Kẹ̀wá 1984 (1984-10-28) (ọmọ ọdún 36)[2]
Ibi ọjọ́ibíLagos, Nigeria
Ìga1.70 m[3]
Playing positionForward
Youth career
1999–2000Ebedei
2000–2001Reggiana
2001–2002Inter Milan
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
2000–2001Reggiana2(0)
2001–2006Inter Milan[2]88(28)
2006–2009Newcastle United88(28)
2009–2010VfL Wolfsburg16(6)
2010–2012Rubin Kazan20(3)
2011Birmingham City (loan)4(0)
2012–2013Levante21(7)
2013–2015Seattle Sounders FC72(40)
2016–2018Shanghai Shenhua40(19)
National team
2004–2015Nigeria42(19)
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only and correct as of 07:44, 3 April 2018 (UTC).

† Appearances (Goals).

‡ National team caps and goals correct as of 19 November 2015

O gbajúmọ̀ látàrí eré sísá rẹ̀ bí ehoro bí ó bá ń gbá Bọ́ọ̀lù. Martins wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìdínlógún nígbà tí ó lọ sí òkè òkun lórílẹ̀ èdè Italy, láti ìgbà náà, ó ti gbá Bọ́ọ̀lù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ní ilẹ̀ Europe. Lọ́dún 2002 ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá Bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àgbà ní orílẹ̀ èdè Italy, ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Inter Milan ló ti kọ́kọ́ wà kí ó tó wá sí orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí ó sìn dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Newcastle United lọ́dún 2006, lẹ́yìn èyí ó kọjá sí orílẹ̀ èdè Germany níbi tí ó ti gbá Bọ́ọ̀lù fún VfL Wolfsburg lọ́dún 2009. Lọ́dún 2010, ó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Rubin Kazan lorílẹ̀ èdè Russia. Lọ́dún 2011, Rubin Kazan yá a ṣí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Birmingham City lórílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ní àsìkò yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àmìn àti ife ẹ̀yẹ tí Ọbáfẹ́mi Akínwùnmí Martins tí gbà káàkiri àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí ó ti gbá Bọ́ọ̀lù jẹun títí dé orílẹ̀ èdè China. Yàtọ̀ sí èyí, Martins jẹ́ gbajúmọ̀ Agbábọ́ọ̀lù fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá Super Eagles ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tí Nàìjíríà fún ìdíje ife ẹ̀yẹ tí ilẹ̀ Áfíríkà lọ́dún 2006,2008 àti 2010. Bẹ́ẹ̀ náà ó wà lára ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tí Nàìjíríà tí wọ́n lọ díje ife àgbáyé lórílẹ̀ èdè South Africa lọ́dún 2010 Ọbáfẹ́mi Martins ní ọmọ ìyá méjì tí àwọn náà ń gbá Bọ́ọ̀lù Àfẹsẹ̀gbá jẹun. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni Ọládipúpọ̀ Martins, tí ó fìgbà kan gbá Bọ́ọ̀lù fún Reggiana, Partizan àti Innsbruck kí ó tó fẹ̀yìntì lọ́dún 2009 nítorí àìsàn ọkàn tí ó ní.[4][5] Martins' younger brother is John Ronan Martins. The name "Obafemi" translates literally to "the king loves me" in the Yoruba language.[6]

Àwọn ìtọ́kasíÀtúnṣe

  1. "Acta del Partido celebrado el 02 de marzo de 2013, en Valencia" [Minutes of the Match held on 2 March 2013, in Valencia] (in Spanish). Royal Spanish Football Federation. Retrieved 16 June 2019. 
  2. 2.0 2.1 "Obafemi Martins". Archive. Inter Milan. Retrieved 6 February 2011. 
  3. "FIFA World Cup South Africa 2010 List of Players" (PDF). FIFA. 4 June 2010. p. 22. Retrieved 2 May 2016. 
  4. "How Did Nigeria's Obafemi Martins' Brother Die?". Socqer.com. 10 August 2011. Retrieved 3 August 2012. 
  5. "Martins' Brother Dies of Heart Problem". Vanguard. 9 August 2011. Retrieved 3 August 2012. 
  6. "Meaning of Obafemi". Nigerian.name. Retrieved 3 August 2012.