Èdè Yorùbá

(Àtúnjúwe láti Yoruba language)

Èdè Yorùbá Ni èdè tí ó ṣàkójọpọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oò-jíire bí, ní apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní Ìwọ̀-Oòrùn aláwọ̀-dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn.[1] Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni Ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ìpínlẹ̀ Èkó, àti Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone,United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ.[2]

Yorùbá
èdè Yorùbá
Sísọ ní Nigeria
 Togo
 Benin
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀25 - 50 milionu (Sachnine 1997 as cited in Ethnologue)
Èdè ìbátan
Sístẹ́mù ìkọLátìnì, Odùduwà, Braille
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Àkóso lọ́wọ́Kòsí àkóso oníbiṣẹ́
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1yo
ISO 639-2yor
ISO 639-3yor
Èdè Yorùbá

Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì wuyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ìbátan Kwa ní èdè Yorùbá jé, kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní apá Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀nà tí èdè Yorùbá pín sí àtúnṣe

Èdè Yorùbá gbajú-gbájà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti káàkiri àgbánlá ayé lápapọ̀. Àwọn nǹkan tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì tí ó fi di àrí má leè lọ àti àwòpadà sẹ́yìn nìwọ̀yín:[3]

Òwe àtúnṣe

Òwe ni ọ̀kan lára àwọn ọnà-èdè tí àwọn Yorùbá mán ń gbà láti kó ẹwà bá ohùn ènu wọn. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a le gbà pa òwe:

(a) A le pa òwe gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè ti ń pa á tàbí bí gbogbo ènìyàn ti ń pá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Àíyá bẹ́ sílẹ̀ ó bé áré, (igi ọ̀ún ni kò ga).

(b) À lè pa òwe dà, bí àpẹẹrẹ: Ojú kìí ti eégún kí ọmọ alágbàá ma kọrí sóko.

(i) Ojú kì í ti eégún nínú aṣọ

(ii) Ohun tí n tán lọdún eégún, ọmọ alágbàá a kọri sóko.

2. Akànlò èdè

3. Lílò àmìn ohùn (´-`).

Ìlò-èdè Yorùbá àtúnṣe

Lára àwọn èròngbà kan gbòógì tí ìlò èdè Yorùbá yíì ni pé mo fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ èdè Yorùbá lo dáradára nítorí náà a wo ìjúba ni awùjọ Yorùbá, a wo ààtò, Ìtúmọ̀, ìlò, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òwe, àkànlò èdè àti ọ̀rọ̀ àmúlò mííràn. A wo èdè àmúlò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ àti igba ti a ba kọ èdè Yorùbá silẹ. A wo ẹ̀bùn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. A sí wo ìlànà ati òté tó de sísọ̀rọ̀ ni àwùjọ Yorùbá. A wo ìwúrẹ láwùjọ Yorùbá. A wo aáyan àròkọ kikọ. Lábẹ́ àròkọ, a wo arokọ wọ̀nyí: alapejuwe, ajemọroyin, alalaye, alariiyan, ìsòròǹgbèsì, onisiipaya, ajẹmọ́-ìsonísókí-ìwé ati arokọ onileta. A wo bi a ṣe n se agbekale isẹ to da le girama, iwe atumọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ, àbọ̀ ìpàdé, ìjábọ̀ ìwádìí, ìwé ìkéde pélébé àti eyí ti a fi n se ìpolongo ti a máa ń tẹ̀ mọ́ ara ògiri. Èdè Yorùbá ni ibamu pẹlu asa obínibí Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ ọ̀rọ̀ í dá sí. Ó yẹ ki a mọ ọ̀rọ̀ sọ, ki á si mọ ọ̀rọ̀ ọ́ kọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ti a bá ka ìwé kékeré yìí.[4]

Bí èdè Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀ àtúnṣe

Kí àwọn òyìnbó tó gòkè odò dé, kò sí ètò kíkọ ati kíka èdè Yorùbá. Gbogbo ọ̀rọ̀ àbáláyé tí ó ti di àko sílẹ̀ lóde òní,nínú ọpọlọ́ àwọn baba ńlá wa ni wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ àbáláyé báyìí a máa súyọ nínú orin, ewì àti ìtàn àwọn baba wa. Nígbà tí a kọ́ ń pe gbogbo àwọn ẹ̀yà tí èdè wọ́n papọ̀ yìí ní Yorùbá tàbí Yóòbá, wọn kò fi tara tara fẹ́ èyí nítorí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ìyókù gbà pé àwọn Ọ̀yọ́ nìkan ni Yorùbá. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run aláwọ̀ funfun tó wá wàásù nípa kírísítì ṣe àkiyèṣí pé èdè wọ́n bá ara wọn mu ni wọ́n bá pè wọ́n ní Yorúbà tàbí Yóòba. Àwọn Yorùbá ti a ko l’éní lo si ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí a sì wá dá padà sí sàró lẹ́hìn tí òwò ẹrú tí tán ni àwọn òyìnbó Ìjọ C.M.S. kọ́kọ́ sọ di onígbàgbọ́.

Àbùdá èdè Yorùbá àtúnṣe

Àbùdá èdè Yorùbá ni ó máa jẹ́ kí á mọ ohun tí èdè jẹ́ gan-an. Orísirísi ni àwọn àbùdá tí èdè Yorùbá ní. Èdè Yorùbá kógo àbùdá wọ̀nyí já.

(1) Ohun tí a bá pè ní mi gba to aobdubdi lnfjbfi gibh knjèdè gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fí ìró èdè gbé jáde. Ìró yìí ni a le pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa. A ó ṣe àkíyèsí pé èyí yàtọ̀ sí pípòòyì, ijó ọlọ́bọ̀ùnbọ̀un, dídún tàbí fífò tata tàbí jíjuwó alákàn sí ara wọn.

(2) Èdè nílò kíkọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó le sọ ọ́. Ó ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni èdè. Àkiyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn eléde gẹ̀ẹ́sì ń gọ́ka sí nígbà tí àwọ́n ba sọ pé “Language is Culturally transmitted”. Ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣè bí tí a kò kọ́ ní èdè, àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn.

(3) Ìhun ni èdè ènìyàn gùn lé tàbí dálé. Bí a ṣe hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú gbólóhùn ṣe pàtàkì kíkà iye ìró èdè nínú gbólóhùn kò fi ibi kankan ní ìtúmọ̀.

A lè sọ pé ìyàndá ṣubú

ìyàndá ẹlẹ́mu ṣubú

Ó ṣubú

Ìyàndá tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣubú.

Ìyípadà orírsirísi ló le wáyé sí gbólóhùn wọ̀nyí tí yóò sì da ètò wọn ní, síbẹ̀síbẹ̀, yóò ní ìtumọ̀. Irú àbùdá yìí ni onímọ̀ ẹ̀dá-èdè ń pè ní “Structure dependence”.

(4) Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí a ń pè ní (Fóníìmù {phonemes}). Foniimu yìí sún mọ́ ti àwọn ẹranko ṣùgbọ́n ó sì tún rọ̀ jut i ẹranko lọ. Ó yàtọ̀ láti èdè kan sì òmíràn. Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. kì í dá ìtumọ̀ ní kó wúlò ìgbà tí a bá kàn án pọ̀ mọ́ fóníìmù mìíràn gan-an ló máa ṣìṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ:- ìró èdè /a/ /b/ /d/ /e/ /ẹ/ kò dá ìtumọ̀ ní, àfi tí abá kàn wọ́n papọ̀ lọ́nà orísirísi. A lè se àkànpọ̀ kí á ri ọ̀rọ̀ bí : abẹ, baba, adé, alẹ́ abbl. Irúfẹ́ àkiyèsí àti ìwádìí yí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀dà-èdè ń pe gẹ̀ẹ́sì rè ní “duality” tàbí “double articulation” ìwádìí fihàn pé àwọn ẹyẹ àti ẹranko tí wọ́n ní ìró èdè kò pò, iye èdè tí òkọ̀ọ̀kan ní kò pọ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ adìyẹ ní ìró èdè bí ogún, ti mààlúù jẹ́ mẹ́wàá ṣùgbọ́n kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọgbọ̀n.

(5) Èdè jẹ́ ohun ètò tí a máa ń lò láti ṣe àròyinlẹ̀.

Ìwúlò èdè Yorùbá àtúnṣe

  1. Èdè wúlò fún kí a le bá ara sọ ọ̀rọ̀ léyìí tí gbédìí fún ẹwà akéwì náà. A kò le ṣe kí a má kí ara wa ní orísirísi ọ̀nà bóyá ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, pẹ̀lú orísirísi ẹwà èdè.
  2. Èdè wúlò fún fífi sọ èrò ọkàn wa àti fífi ìtara hàn sí ohun tí a gbọ́ rí tàbí tí ó ṣelẹ̀ sí wa. Reference:

Ìwé àtúnṣe

  • Taiwo Olunlade “Èdè Yorùbá àti ìmọ̀ ẹ̀dà èdè”
  • Taiwo Olunlade “Àgbéyẹ̀wò ìlò èdè Yorùbá”

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Yorùbá: Languages of Africa at SOAS University of London". SOAS University of London. 2011-02-21. Archived from the original on 2020-02-01. Retrieved 2020-02-01. 
  2. "Yoruba Language - Dialects & Structure". MustGo.com. 2019-05-10. Retrieved 2020-02-01. 
  3. "Yoruba language, alphabet and pronunciation". Omniglot. Retrieved 2020-02-01. 
  4. "Yoruba - Introduction, Location, Language, Folklore, Religion, Major holidays, Rites of passage". World Culture Encyclopedia. 2007-04-03. Retrieved 2020-02-01.