Ọba AbdulRasheed Adéwálé Àkànbí
Oba AbdulRasheed Adéwálé Àkànbí, Oluwo tì ilẹ̀ Ìwó (tí a bí ní Ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹfà ọdún 1967) jẹ́ Ọba ìlú Ìwó ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó wà ìtẹ́ lọ́wọ́́lọ́wọ́.[1] [2]
Bí ó ṣe jọba
àtúnṣeỌ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ òye láti ìdílé ọba ni ìlú Ìwó ni wọ́n du oyè ọba Olúwòó kí orí tó bá Ọba Adéwálé ṣe é tí ó sìn gorí ìtẹ́ àwọn bàbáńlá rẹ̀ lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kọkànlá ọdún 2015. Agbolé Molààsán tí ìdílé ọba Gbàásè ni ó ti wá. Orílẹ̀ èdè Canada ló wà tí wọ́n fi yàn án lọ́mọ oyè tí ìlú yàn láti jọba Ìwó. [3]
Ìgbà èwe rẹ̀ àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
àtúnṣeỌba Adéwálé bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Omolewa Nursery and Primary School, Orítamẹ́fà ní ìlú Ìbàdàn lọ́dún 1972 sí 1978. Ó tẹ̀ síwájú ní Ìwó Grammar School, Arárọ̀mí ní ìlú Ìwó gangan lọ́dún 1978 sí 1982, ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn ní ilé ìwé Ọba Akínyẹlé Memorial High School, Ìdí -Apẹ ní Ìbàdàn. Ó kàwé gboyè National Diploma nínú iṣẹ́ ìròyìn ni The Polytechnic Ìbàdàn lọ́dún 1985 sí 1987. Ọmọba Adéwálé kàwé gboyè B.Sc. nínú ìmọ̀ ìṣàmọ́jútó Okowò (Business Administration) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga George Brown College, ní ìlú Ontario, Toronto lorílẹ̀ èdè Canada lọ́dún 2005 sí 2009. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé iṣẹ́ ni Ọba Adéwálé tí ṣiṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Canada kí ó tó padà wálé wá jọba. Orílẹ̀ èdè Canada yìí ló wà tí wọ́n fi yàn án lọ́mọ oyè tí ìlú yàn láti jọba Ìwó lọ́dún 2015.
Ààtò awọn Olúwòó ti Ìwó tó ti jẹ ṣáájú Ọba AbdulRasheed Adéwálé Àkànbí
àtúnṣeỌjọ́ tí ó jọba | Ọjọ́ tí ó wàjà | Orúkọ Ọba |
---|---|---|
1415 | 1505 | Parin |
1505 | 1541 | Ọláyílùmí |
1550 | 1610 | Adégúnlódò |
1610 | 1673 | Olúfàtẹ Gbàṣẹ |
1673 | 1744 | Aláwùsá |
1744 | 1816 | Ògúnmákindé |
1816 | 1906 | Monmodu Àgínlá Lámúyẹ |
1906 | 1909 | Sùnmọ́nù Ọsúnwo |
1909 | 1929 | Sanni Àlàbí Abíḿbọ́lá Lámúyẹ |
1929 | 1930 | Seidu Adúbíàrán Lámúyẹ |
1930 | 1939 | Àbánikánńdá Àmúdá Àkàndé |
1939 | 1952 | Kosiru Ande Lámúyè |
1953 | 1957 | Ràífù Àjàní Adégoróyè |
1958 | 1982 | Samuel Ọmọtọ́ṣọ̀ọ́ Abíḿbọ́lá |
1992 | 2013 | Asiru Olatunbosun Tadese |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The Official Website Of The State Of Osun". The Official Website Of The State Of Osun. 2015-11-09. Archived from the original on 2020-09-24. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ "Osun monarch canvasses better funding for police - Nigeria and World NewsNews - The Guardian Nigeria News – Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ Olarinoye, Gbenga (2015-11-12). "How Prince Akanbi emerged new Oluwo". Vanguard News. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ "Iwo - Nigeria". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2019-12-01.
- ↑ "Abibitumi.com Forum". Abibitumi.com - Communiversity. Retrieved 2019-12-01.