Ọdún Ìgògò
Àdàkọ:Infobox recuring festival Ọdún Ìgògò jẹ́ ọdún ìbílẹ̀ Yorùbá tí ó ma ń wáyé ní ìlú Ọ̀wọ̀ Ìpínlẹ̀ Òndò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n ma ń ṣe ọdún yí ní gbogbo oṣù Kẹsàn án sí oṣù Kẹwàá ní ọdọọdún ní ìbu ọlá fún Olorì Oronsen tí ó jẹ́ olorì ọba Rerengejen [1] Lásìkò ọdún yí, ọba tí ó bá wà lórí ìtẹ́ àti àwọn olóyè láàfin yóò.múra bí àwọn obìnrin pẹ́lú aṣọ tí wọ́n fi ilẹ̀kẹ̀ sẹ̀gi ṣe lọ́jọ̀, tí wọn yóò sì dirun gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin ti ma ń ṣe.[2] Wọn yóò dé fìlà, tí wọn yóò sì ma lu ìlù pẹ̀lú àwọn orin ọlọ́kan ò jọ̀kan, tí wọn yóò sì ma yin ìbọn sókè lásìkò ọdún náà.[3]
Ìtàn bí ọdún náà ṣe bẹ̀rẹ̀
àtúnṣeỌdún Ìgògò bẹ̀rẹ̀ ní nkan bí ọgọ́rùn ún mẹ́fà ọdún sẹ́yin ni ọba Ọlọ́wọ̀ Rerengejen fẹ́ olorì Orosen tí ó jẹ́ arẹwà àti ọlọ́rọ̀ tí ọba náà kò mọ̀ wípé òrìṣà ni. Olorì yí fi gbogbo nkan kẹ́ Ọlọ́wọ̀ yí kódà tó fi mọ́ agbára, tí ọba naa sì nífẹ́ rẹ̀ tọkab tọkan. Olorì Orosen ní àwọn èwọ̀ kan tí kìí fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó ṣe nítòsí rẹ̀ tàbí kí ó fojú rí. Lára àwọn èwọ̀ rẹ̀ ni:
- ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ ilá lórí ọlọ.
- ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ da omi èyíkéyí sílẹ̀ lójú rẹ̀.
- ẹnikẹ́ni tó bá lọ sóko kò gbọdọ̀ di ẹrù igi sórí wọ agbolé tàbí àfin.
Fúndí èyí, ọba Rerengejen kọ̀ fún àwọn olorì tó kù kí wọn má ṣe ṣe àwọn nkan wọ̀nyí.[4] Ní ọjọ́ kan, olorì Orosen ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú àwọn olorì tó kù nínú àfin. Àwọn olorì wọ̀nyí wá gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sì ṣe gbogbo nkan èwọ̀ tí kò fẹ́ran sílẹ̀ fun nígbà tí kò sí nílé. Àwọn ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí àwọn olorì tókù hù yí ni ó mú Orosen bínú kúrò ní àfin fún wọn. Nígbà tí ó ń bínu kúrò ni àfin lọ́jọ́ naa lọ́hùn ún, àwọn ìlàrí ọba àti àwọn ìjòyè gbìyanjú láti da dúró kí ó má lọ ṣùgbọ́n agbára wọn ko káa. Ó sáré títí ó dé ìbìkan tí wọ́n pè ní "Ugbo Laja", níbi tí ó sinmi sí. Ibí ni àwọn akọ́dà ọba àti àwọn ìjòyè ti gbìyànjú láti mu padà wá sí àfin. Akitiyan àwọn ènìyàn wọ̀nyí túbọ̀ bí olorì Orosen nínú tí ó sì bínú pòórá wọgbó "Igbo Oluwa"lọ láì mú ìgbànú tàbí ọ̀já rẹ̀ kí ó tó wọgbó, tí wọ́n sì dá ọ̀já náà padà fún ọba Rerengejen láàfin. Wọ́n sọ Igbo Oluwa di ojúbọ olorì yí tí wọ́n sì ṣe ère rẹ̀ lọ́jọ̀ sí "Ugbo Laja" fún ìrántí rẹ̀ wípé kò sí ohun tó lè mú olorì náà padà wá sí ìlú mọ́. Àmọ́, wọ́n ma ń bọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí òrìṣà lọ́dọọdún pẹ̀lú àwọn nkan wọ̀nyí:
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Festivals". www.owo-kingdom.net. Archived from the original on February 10, 2016. Retrieved April 14, 2016. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑
"A visit to Owo". Daily Trust. Archived from the original on August 11, 2016. Retrieved April 14, 2016. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Igogo festival begins". Nigerian Tribune Newspaper. Archived from the original on April 25, 2016. Retrieved April 14, 2016. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Owo Celebrates Igogo Festival". The Nation Newspaper. Retrieved April 14, 2016.
- ↑ Elisabeth Benard; Beverly Moon (21 September 2000). Goddesses Who Rule. Oxford University Press. pp. 125–. ISBN 978-0-19-535294-8. https://books.google.com/books?id=D50ob0i_e0MC&pg=PA125.