Ọdún Iléyá (Lárúbáwá: عيد الأضحى‘Īdu l-’Aḍḥā tabi Aïd el-Kabir) "Ọdún Ìdúpẹ́-Ọòrẹ" jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pàtàkì nínú ẹsìn Ìsìlàámù ti àwọn Mùsùlùmí ṣe àjọyọ̀ káàkiri àgbáyé láti ṣerántí àmì kàn tí wọ́n ní ìfẹ sí tí ó ń jẹ́ Ànọ́bì Ìbùrọ̀hìmù (Abraham) (Ibrahim).[1]

Ọdún Iléyá
Id al-Adha (‘Īdu l-’Aḍḥā)
Ọdún Iléyá Id al-Adha (‘Īdu l-’Aḍḥā)
Official nameLárúbáwá: عيد الأضحى
‘Īdu l-’Aḍḥā
Also calledFestival of Sacrifice,
Sacrifice Feast
TypeIslamic
SignificanceCommemoration of Ibrahim's (Abraham's) willingness to sacrifice his son Ishmael for Allah.
Marks the end of the Pilgrimage to sundown, and ask God for forgiveness.
Begins10 Dhu al-Hijjah
Ends13 Dhu al-Hijjah
ObservancesPrayer, sacrificing a goat, sheep, cow or a camel, giving to poor people as a gift.

Oríṣiríṣi àlàyé ló wà fún ọdún yìi, lára àwọn àlàyé náà ni:


Ní ọdún 1991, Sheikh Dr. Abu-Abdullah Adélabú ṣe àlàyé nípa Ọdún Iléyá ní orí Ẹ̀rọ-sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Rẹ́díò Abùjá wí pé Ọdún Iléyá jẹ́ àjọ̀dún ìfi-ẹ̀mí-ìmọorè-hàn, Ọlọ́hun ní kí Ibrahim ó ṣe láti fi ẹ̀mí-ìmọ́orè hàn èyí tí ó sí fí ọmọ rẹ̀ Ishmael sílè fún ìfi ẹ̀mí-ìmọ́orè hàn sí Ọlọ́run tí ó ṣe àdéhùn fún pé bí oun Ibrahim bá bímọ nínú ogbó pé òun yóò fí ọmọ náà jọ́sín fún Ọlọ́run.

Nínú wàásí Sheikh náà tí í ṣe ọmọ-bibi orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbo lórí ètò àjọ̀dún ọdún tí òṣìṣẹ́ àgbà Mùsùlùmí Àlàájíaji Gúrúrángà ṣe olóòtú àti olú-gbàlẹjọ̀ lórí ẹ̀rọ-sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà wípé, fífi ọmọ bíbí Ibrahim sílè kì ì ṣe rírú ẹbọ. Sheikh Adélabú tí àwọn ọmọ lẹ́hìn rẹ̀ ń ṣe ìgbéjáde Ẹ̀ṣín isilaamu.Com láti pàṣẹ ilé-èkó Ìsìlàámù Awqaf Africa ní Ìlú London ṣé àlàyé ní èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ Rédíò Abùjá wípé ìdánwò ní Ọlọ́hun ṣe fún Ànọ́bì ibrahim láti ṣe Ìfi- rinlẹ̀ jíjẹ olúsìn-rere, olótìitọ̀, olódodo àti olumọ̀- oore.

Onímímọ̀ Yorùbá yíì ṣe ìtumò àwọn ẹsẹ- ọ̀rọ̀ nínú kúránì báyìí wípé [2]:

"Òun (Ibrahim) sí sọ wípé: "Ọlọ́hun mí ó! Fún mí ní ọmọ rere" Bẹ́ẹ̀ náà síní Àwa (Ọlọ́hun Ọba-Áaso) sí fún ní ìròyìn ayọ̀ wípé òun (Ibrahim) yì ó rí Ọmọkùnrin (Ishmael) bí. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí òun (ọmọ ọkunrin kékeré náà, Ishmael) dàgbà dé bí tí ó lè rìn káàkiri (fún ìjíhìn-rere) pẹ̀lú Ibrahim, òun (Ibrahim) sí wí fún wípé: Ìwọ ọmọ mí (Ishmael) ó! A ti fi hàn mí l'ójú rán wípé mo fí ọ ṣe ìdúpẹ́ oore (ní ti fífẹni sílẹ̀ fún ìdúpẹ́ l'ọ́wọ Ọlọ́hun), àbí ìwọ kò rí bí nkán ti rí bí - kíni èrò tìre?! Òun (Ishmael) sí da (bàba rẹ̀ Ibrahim) lóhùn wípé: "Ìwọ bàba mi ó! Ṣe gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe pa ìwọ l'ásẹ láti ṣe, Inshâ' Allâh (Ní ti Ògo-Ọlọ́hun) ìwọ yì ó sí mo bí mo ti jẹ́ nínú àwọn As-Sabirin (Àwọn Olufàradà nínú sùúrù àti òun tí ó jọmọ́ bẹ́ẹ̀ gbogbo).

Lẹ́hìn èyí, tí àwọn méjèèjì sí ti gbà fún Ọlọ́hun wọn Allah tí wọ́n sì ṣe ijúwọ̀-jusẹ̀ sílè fún Ìfẹ Ọlọ́hun), tí òun (Ibrahim) sí tí tẹ́ orí ẹ́e (Ishamel) lọ sílẹ̀ (ní ààyè itébà sí iwájú);

"Báyìí náà ní Àwa sí pé òun: "Ìwọ Ibrahim o!"

"Ìwọọ (Ibrahin) tí ṣe gẹ́gẹ́ bí A ti fi hàn ó (ní ojúran) ní òtítọ àti ní òdodo! Báyìí náà sì ní Àwa ṣe má ń san ẹ̀san fún (gbogbo àwọn) Múhsínùn (olùṣe rere lótitọ àti l'ódodo) - Sheikh Adélabú ṣe ìtọka sí Ẹsẹ Ọrọ Ọlọ́hun nínú kúránì Orí 2:112)."

Láì kọ́ ṣe àníàní, ìdánwò nlá tí ó fi ojú hàn gbángba ní eléyìí jẹ́. Nítorí ìdí èyí ní À wa fi ṣe ìrópò (gẹ́gẹ́ bí ìràpadà) ọmọ (Ishamael) tí òun (Ibrahim) náà pẹ̀lú àgùntàn kàn bọ̀lọ̀jọ̀ (láti fi dípò ní ṣíṣe ìdúpẹ́ òòrè láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun)

"Báyìí náà sì ní À wa jẹ́ kí ó wá nílé fún un (Ibrahin) ìrántí rere tí ó sì di mánìgbàgbé fun àti láàrín àwọn àrọ́mọdọ́mọ tí òun bọ̀ lẹ́hìn Títí Láíláí.

{

(

"Sàlámùn 'alaa Ibrâhim (Abraham) i.e. Ìkẹ́ àti ìgẹ̀ (Ọlọ́hun) ní fún Ibrahim (Abraham)}[3].




  1. Diversity Calendar: Eid al-Adha Archived 2012-10-19 at the Wayback Machine. University of Kansas Medical Center
  2. [http://www.esinislam.com/Quran_And_Hadith/Arabic_Engilsh_Quran/Arabic_English_Quran_Surah_37.htm Awon Aaya yi ninu Quran se ekunrere ni Surah As-Safaat 37:100-111
  3. [http://www.esinislam.com/MediaYoruba/index.php Fun ekunrere alaiye yi ni Ede Yoruba, e wo EsinIslam.Com