Àwòrán àwọn ènìyàn tó ṣàgbákò àgbàrá òjò

Àgbàrá tó wáyé ní Nàìjíríà ti ọdún 2022 kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbègbè ní orílẹ̀-èdè náà. Láti inú dẹ́tà ti ìjọba àpapọ̀, àgbàrá náà ti sọ ènìyàn tó ń lọ bíi 1.4 million di aínìnílélórí, ó ti pa ènìyàn 603, ó ṣe ènìyàn 2400 léṣe. Àwọn ilé tó wo ń lọ bíi 82,035, àwọn ilè tó ń lọ bíi 332,327 ló sì ti bàjẹ́.[1]

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àgbàrá máa ń wáyé dáadáa ní orílẹ̀-èdè Nàijiria, àmọ́ àgbàrá ọdún yìí ló léwu jù lọ, láti ìgbà tí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2012 wáyé. [2] Ní oṣù kẹwàá, àwọn ilé tó ń lọ bíi 200,000 ni àgbàrá yìí bàjẹ́. Ní ọjọ́ keje oṣụ̀ kẹwàá, ọkọ-ojú-omi kan tó ń gbẹ́ àwọn ènìyàn tó ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn ló dojúdé, tih ó sì fa ikú ènìyàn 76, ìyẹn mẹ́rìnlélọ́gọ́rin.[3]


Ohun tó fa àgbàrá náà ni òjò wẹliwẹli kan tó pọ̀, ìyípadà tó dé bá afẹ́fẹ́, àti omi tó ṣí sílẹ̀ ní Lagodo DamCameroon, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn-án. Àgbàrá náà ṣàkóbá sí orílẹ̀-èdè Naijiria, Niger, Chad àti àwọn agbègbè rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà oòrùn ní ọdún 2022, tí ó sì parí ní oṣù kẹwàá.[4][5]

Àgbàrá náà ní agbègbè tó ti ṣẹlẹ̀

àtúnṣe

Ìpínlẹ̀ Adamawa

àtúnṣe

Ní ìparí oṣù kẹjọ, ọ̀pọ̀ àgbàrá ní ipinle Adamawa fa ikú ènìyàn mẹ́wàá, ó sì da ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé rú.[6]

Ìpínlẹ̀ Anambra

àtúnṣe

Ní ọjọ́ keje oṣụ̀ kẹwàá, ọdún 2022, ènìyàn 76 ló sì sínú omi lẹ́yìn tí ọkọ̀-ojú-omi dojúdé sínú odo.[7]Àkúnwọ́nsílẹ̀ odò Niger àti ọ̀pọ̀ òjò tó rọ̀ ló jẹ́ kí omi yẹn kún ní àkúnkù. Àwọn ìlú tó wà ní agbègbè omi ni àgbàrá bàjẹ́.[8]

Ilé-ìjọsìn alájà mẹ́ta, ìyẹn Madonna Catolic Churn ní Iyiowa dà wó látàrí àgbàrá náà, tó wáyé ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá.[9]

Awọn ibudo IDP 28 wa ni ipinlẹ Anambra, nibiti awọn olufaragba iṣan omi ti wa ni aabo ati ti itọju lakoko awọn akoko pajawiri iṣan-omi. [10] Láti dínkù wàhálà àti ìgbènijà àwọn ẹni tí àgbàrá yìí ba ilé wọn jẹ́, wọ́n gbé àwọn kám̀pù kéréje kéréje kalẹ̀ sí àwọn agbègbè lóríṣiríṣi ìpínlẹ̀ náà.

  • Crowther Memorial Primary School Camp, Onitsha, Ipinle Anambra: Ibùdó yìí ni àwọn olùfaragbá àgbàrá náà, láti oríṣiríṣi agbègbè tí ó wà pẹ̀lú Mmiata-Anam, Umudora-Anam, Nzam, Ukwala, Inoma, àti Owele láti apá Ìwọ̀-oòrùn Ìpínlẹ̀ Anambra. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní àgọ́ náà jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún [1,800]. Àwọn aláboyún márùn-ún bí ọmọ wọn ní ibùdó ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Crowther Memorial, Onitsha. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n mú wọn lọ sí ilé-ìwòsàn gbogbogbo, ní Onitsha fún ìtọ́jú tó dára lẹ́yìn ìbímọ ní ibùdó IDP.[11]
  • Agbegbe Onitsha North Council Area Internally Displaced People (IDP): Ibudo IDP ti gbe awọn eniyan bi 400 lati Umuoba Anam ati Ekpe Nneyi, Umueri ni Agbegbe Igbimọ Ila-oorun Anambra. Awọn olufaragba iṣan omi tun wa lati Ipinle Delta ni wọn gbe ni ibudó nibiti wọn ti pin awọn ohun elo iranlọwọ ati awọn ohun elo miiran.[12][13]
  • Ibudo ijoba ibile Ogbaru: Eyi wa ni agbegbe Atani. Bi o ti wu ki o ri, ikun omi de ti o si rì olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa nigba ti awọn ẹlẹwọn wa nibẹ. Awọn eniyan wa ni ayika pẹlu awọn ọkọ oju omi ati gbe awọn olufaragba iṣan omi ti o ni idẹkùn kuro. O di ajalu meji fun awọn olufaragba iṣan omi.[14]
  • IDP ibùdó Umueri[15]
  • IDP ibùdó Aguleri[16]

Ìpínlẹ̀ Jigawa

àtúnṣe

Àgbàrá náà ti kọlu Ipinle Jigawa láti oṣù kẹjọ sí oṣù kẹsàn-án, níbi tí àwọn ènìyàn bíi méjìléláàádọ́rùn-ún (92) ti kú.[17]

Ìpínlẹ̀ Kano

àtúnṣe

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, Nigerian Meteorological Agency fún àwọn ènìyàn ní ìkìlọ̀ nípa àgbàrá omi tó máa ṣẹlẹ̀ ní ìpinlẹ̀ náà.

Ìpínlẹ̀ Kogi

àtúnṣe

Lokoja, tí ó wà ní ibi ìpàdé àwọn odò Benue àti Niger, wà láàrin àwọn agbègbè tí ó ní ipa tí ó burú jù látàrí ìṣàn omi.[18]

Ìpínlẹ̀ Niger

àtúnṣe

Mariga, ipinle Niger, òkú tí omi ṣàn lọ kúrò níbi ìtẹ́ òkú jú 1,500 lọ.[19] Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sọ pé òkú 650 ni wọ́n rí padà, tí wọ́n sì padà sin.[20]

Ìpínlẹ̀ Yobe

àtúnṣe

Àgbàrá omi ńlá wáyé ni Ipinle Yobe ní oṣù keje tí ó sì pa ènìyàn mẹ́rin.[21]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Oguntola, Tunde (2022-10-17). "2022 Flood: 603 Dead, 1.3m Displaced Across Nigeria – Federal Govt" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-11-07. 
  2. Maclean, Ruth (17 October 2022). "Nigeria Floods Kill Hundreds and Displace Over a Million". The New York Times. https://www.nytimes.com/2022/10/17/world/africa/nigeria-floods.html. 
  3. "Nigerian boat accident death toll rises to 76, president says". The Guardian. 9 October 2022. 
  4. "Nigeria floods: 'Overwhelming' disaster leaves more than 600 people dead" (in en-GB). BBC News. 2022-10-16. https://www.bbc.com/news/world-africa-63280518. 
  5. "Nigeria floods 80 times more likely with climate change" (in en). AP NEWS. November 16, 2022. https://apnews.com/article/floods-science-africa-nigeria-climate-and-environment-7972ff1cba1134cc80219acff1a51d42. 
  6. Davies, Richard (26 August 2022). "Nigeria – 10 Dead After Severe Flash Floods in Adamawa State". FloodList. 
  7. "Nigerian boat accident death toll rises to 76, president says". The Guardian. 9 October 2022. 
  8. "Anambra, Delta Deadly Floods: 70-yr-old killed while sleeping in submerged home". Vanguard. 16 October 2022. https://www.vanguardngr.com/2022/10/anambra-delta-deadly-floods-70-yr-old-killed-while-sleeping-in-submerged-home/. 
  9. Obianeri, Ikenna (9 October 2022). "Conflicting figures trail Anambra boat crash, church collapses". Punch.ng. https://punchng.com/conflicting-figures-trail-anambra-boat-crash-church-collapses/. 
  10. Agency Report (2018-02-18). "No killing at IDP camps in Anambra – Official". Premium Times. Archived on 2023-02-26. Error: If you specify |archivedate=, you must also specify |archiveurl=. https://www.premiumtimesng.com/news/more-news/458098-no-killing-at-idp-camps-in-anambra-official.html?tztc=1. 
  11. "Five women give birth in Anambra IDP camp". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-10-24. Retrieved 2023-02-26. 
  12. "Deltans flood IDP camps in Anambra – The Sun Nigeria". sunnewsonline.com. Retrieved 2023-02-26. 
  13. "Soludo visits IDP camps, seeks support for displaced persons". The Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Nigeria. 2022-10-06. Archived from the original on 2023-02-26. Retrieved 2023-02-26. 
  14. Maduforo, Okey (2022-10-20). "Lamentations of flood victims in Anambra IDP camps". New Telegraph (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-02-26. 
  15. "Flood: Metchie Decries Absence of NEMA, SEMA in Anambra IDP Camps – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-02-26. 
  16. "Flood: Metchie Decries Absence of NEMA, SEMA in Anambra IDP Camps – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-02-26. 
  17. Davies, Richard (22 September 2022). "Nigeria – 300 Dead, 100,000 Displaced as Government Warns of Worsening Floods". FloodList. 
  18. Jones, Mayeni (14 October 2022). "Nigeria floods: Braving the rising waters in Kogi state". BBC News. https://www.bbc.com/news/world-africa-63262391. 
  19. Ibrahim Garba Shuaibu (22 September 2022). "Floods sweep away 1,500 corpses from cemetery in northern Nigeria". Anadolu Agency. 
  20. Empty citation (help) 
  21. Davies, Richard (20 July 2022). "Nigeria – Floods Wreak Havoc in Yobe State". FloodList.