Ìbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ọdún 2023 yóò wáyé ní rẹpẹtẹ, ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì àti ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ́ta ọdún 2023. Ìdìbòyan Ààrẹ àti igbá-kejì Ààrẹ yóò wáyé ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, Ààrẹ lọ́wọ́ lọ́wọ́, Muhammad Buhari kò le díje, nítorí gbèdéke àkókò rẹ̀ ti tó.[1] Láfikún, ìdìbòyan àwọn aṣojú-ṣòfin náà yóò wáyé bákan náà ní ọjọ́ kan náà àti àwọn ti ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin. Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ́ta, gómìnà méjìdínlọ́gbọ̀n ni wọn yóò dìbò yàn pẹ̀lú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.[1] Àwọn àfikún ìdìbò gómìnà mẹ́ta yóò wáyé nígbà mìíràn nínú ọdún yìí Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn àtúndì ìbò fún àwọn ìdìbò tí wọ́n ti máa ń ṣètò fún àwọn ìbò tí wọ́n fagilé ní bẹ̀rẹ̀ ọdún yìí.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Jimoh, Abbas (26 February 2022). "INEC Sets New Dates For 2023 General Elections". Daily Trust. Retrieved 26 February 2022.