Abíọ́lá Ọdẹ́jídé

Abíọ́lá Ọdẹ́jídé jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n-ágbà nínú ìmọ̀ iṣẹ́-ọ̀nà èdè àti lítíréṣọ̀ láti Yunifásítì Ìbàdàn, (University of Ibadan). Ó ti kọ́kọ́ jẹ Igbákejì ọ̀gá Yunifásítì lábala ètò ẹ̀kọ́ ní University of Ibadan, òun sìn ni obìnrin àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ dé irú ipò bẹ́ẹ̀ lọ́mọ ọdún méjìdínlọ́gọ́ta.[1]

Abíọ́lá Ọdẹ́jídé
Ọ̀jọ̀gbọ́n-ágbà nínú ìmọ̀ iṣẹ́-ọ̀nà èdè àti lítíréṣọ̀ láti Yunifásítì Ìbàdàn, (University of Ibadan)
In office
2011 – present
Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ iṣẹ́-ọ̀nà èdè àti lítíréṣọ̀ láti Yunifásítì Ìbàdàn, (University of Ibadan)
In office
1991–2011
Igbákejì ọ̀gá Yunifásítì lábala ètò ẹ̀kọ́ ní University of Ibadan
In office
November 8, 2004 – November 7, 2006
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí17 Oṣù Kẹrin 1946 (1946-04-17) (ọmọ ọdún 78)
ResidenceIbadan, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Alma materUniversity of Ibadan
(Bachelor of Arts in English)
University of Leeds
( Master of Arts in Linguistics and English Language Teaching)
University of Ibadan
(Doctor of Philosophy in English: Children Literature)

Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Abíọ́lá Ọdẹ́jídé kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ pẹ̀lú èsì ìdánwò tó dára nínú ìmọ̀ èdè òyìnbó ní University of Ibadan lọ́dún 1968. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí University of Leeds lókè òkun láti kàwé gboyè dìgírì kejì nínú ìmọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ti Lìnùngúísítì àti èdè òyìnbó pẹ̀lú èsì tó dára jù lọ lọ́dún. Ó gboyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 1986,ó sìn di ọ̀jọ̀gbọ́n yányán lọ́dún 1991 ní University of Ibadan.[2]

Àwọn ipò aṣojú tó dìmú àtúnṣe

Ọdẹ́jídé ni obìnrin àkọ̀kọ̀ tí ó k9kọ́ jẹ Igbákejì ọ̀gá Yunifásítì ní University of Ibadan.[3] A¡ṣáájú àkókò náà, ó ti kọ́kọ́ di oríṣiríṣi ipò mú, lára àwọn ipò tó jẹ ni; Olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ òkèèrè. Ó sinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní Ìbàdàn lóṣù kọkànlá ọdún 2011. [4]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Published. "People asked who’d take care of my home if I became DVC –Prof Odejide, UI ex-deputy vice-chancellor". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-28. 
  2. admin (2017-11-21). "Abiola Odejide CV" (PDF). University of Ibadan. Archived from the original (PDF) on 2019-07-01. Retrieved 2017-11-21. 
  3. admin (January 25, 2015). "UI gets new Deputy Vice-Chancellor". Vanguard (Nigeria). Retrieved 2017-11-21. 
  4. "I FELT A SENSE OF HISTORY BECOMING FIRST FEMALE DVC". Nigeria Voice. November 21, 2017. Retrieved 2017-11-21.