Ilé-Ẹ̀kọ́ Girama, Abẹ́òkúta
Ilé-Ẹ̀kọ́ Girama, Abẹ́òkúta jẹ́ ilé - ẹ̀kọ́ gíga ní ìlú Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà. Agbègbè Ìdí-Aba ní Abẹ́òkúta ni ó wà báyìí. Wọ́n sábà máa ń pè é ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Gírámà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè láti apá Nàìjíríà, Iwọ̀-oòrùn Áfíríkà, Gúúsù-Ilẹ̀ Áfíríkà, Yúróòpù, àti ní Éṣíyà ni wọ́n ń lọ síbẹ̀
Ilé-Ẹ̀kọ́ Girama, Abẹ́òkúta | |
Iberu Oluwa Ni Ipile Ogbon (Yoruba) The Fear Of God Is The Beginning Of The Wisdom Èdè Gẹ̀ẹ́sì
| |
Location | |
---|---|
Elite Road, Idi Aba Abeokuta, Ogun State, Nàìjíríà | |
Information | |
Type | Public |
Religious Affiliation(s) | Anglican Communium |
Established | 1908 |
Faculty | 3 |
Grades | JSS1 - SSS3 |
Color(s) | Blue and gold |
Nobel laureates | Wole Soyinka |
Àjọ Ṣọ́ọ̀sì Anglican Agbègbè Abẹ́òkúta ni wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ ní ọdún 1908. Àwọn èèyàn jàkànjàkàn ni wọ́n lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn olóṣèlú Nàìjíríà àti àwọn oníṣẹ́-ọnà, bákan náà ni olùkọ́ àti olóṣèlú ajàfẹ́ẹ̀tọ́ Fúnmiláyọ̀ Ransome-Kútì àti ọmọ rẹ̀, olórin Fẹlá Aníkúlápò-Kutì.
Ní ìlànà ìmọ̀-ẹ̀kọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Girama Abẹ́òkúta lọ fún ìdánwò ní Royal College Preceptors ní 1909 tí wọ́n sì jókòó fún Ìdánwò Cambridge abẹ́lé ní 1911. Ó di ilé-ẹ̀kọ́ takọ-tabo ní 1914 nígbà tí wọ́n gba àwọn obìnrin. Ní 1939, ilé-ẹ̀kọ́ kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ fún Ìdánwò Ilé-ẹ̀kọ́ Cambridge, ní ọdún 1996 ìjọba Nàìjíríà sún ipò rẹ̀ sókè sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Aláwòkọ́ṣe.
AGSOBA jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtijọ́ (ọkùnrin àti obìnrin) tí Ilé - Ẹ̀kọ́ Gírámà Abẹ́òkúta, òun sì ni ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó dàgbà jù ní Nàìjíríà. Aláṣẹ Ìgbìmọ̀ Gíga ló darí rẹ̀ tí olú - iléeṣẹ́ sì wà ní Abẹ́òkúta, ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́ ni àwọn ẹ̀ká jákèjádò Nàìjíríà àti ní àgbáyé.
Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gírámà Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn jáwé olúborí orílẹ̀èdè níbi ipele Ètò-amúùlúdùn àti Èrò - tuntun ní Ìdíje Diamond lásìkò Ayẹyẹ National Pitch Event ní ọdún 2019. Ó wáyé ní Àjọ ìdàgbàsókè ọ̀dọ́ tí ìyára-ìkàwé Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́Ìtàn Ile-eko naa ni ipilẹ ni ọdun 1908 nipasẹ Igbimọ Ijo Agbegbe ti Abeokuta (Anglicans).
Ni ẹkọ, awọn ọmọ ile-eko ti Ile-iwe Girama Abeokuta wọ inu idanwo nipasẹ Royal College of Preceptors ni ọdun 1909 wọn si joko fun Ayẹwo Agbegbe b9 jí kambiriji ni ọdun 1911. O di ile-iṣẹ adalu ni ọdun 1914 pẹlu gbigba awọn ọmọbirin. Ni ọdun 1939, ilé-ẹ̀kọ́ gbekalẹ awọn ọmọ ile-eko fun Idanwo Ijẹrisi Ile-eko kambiriji ati ni ọdun 1996 ni igbega si ipo Ile-eko awokose nipasẹ ijọba Naijiria.
AGSOBA jẹ ajọṣepọ ti awọn ọmọ ile-eko arugbo (ọmọkunrin ati ọmọdebinrin) ti Ile-iwe Girama Abeokuta ati pe o jẹ ẹgbẹ awọn ọmọ ile-iwe ti o dagba julọ ni Nàìjíríà Ti o jẹ olori nipasẹ ẹgbẹ ti orilẹ-ede ti a mọ ni Igbimọ Alakos gbogbogboo pẹlu olu-ilu rẹ ni Abeokuta, ajọṣepọ naa n ṣiṣẹ nipasẹ awọn ẹka ni gbogbo orilẹ-ede Naijiria ati ni agbaye.
Orúkọ àwọn ènìyàn tó lààmìlaaka tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ìwé yìí
àtúnṣe- Wole Soyinka
- Hezekiah Oluwasanmi
- Beko Ransome-Kuti
- Fela Anikulapo Kuti
- Okunade Sijuade
- Tunde Kelani
- Funmilayo Ransome-Kuti
- Dotman
- Fireboy DML
- Kizz Daniel
- Iziaq Adekunle Salako