Abdul-Azeez Olajide Adediran
Abdul-Azeez Olajide Adediran tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Jandor, jẹ́ olóṣèlú Nàìjíríà, oniroyin, oníṣòwò àti onímọ̀-ẹ̀rọ.[1] Òun ni alága ẹgbẹ́ Lagos4Lagos àti olùdíje ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party pẹ̀lú olùdíje àti igbákejì rẹ̀, Funke Akindele .[2][3][4] Ó gba Doctorate Honorary nínú ètò ìdarí àti ìṣèjọba ní South American University, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà.[5]
Jandor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kọkànlá 1977 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Ẹ̀kọ́ |
|
Iṣẹ́ | Journalist Politician |
Olólùfẹ́ | Maryam Olajide Adediran |
Parent(s) | Alhaji Adeniran and Late Mrs Ruth Oluwafunmilayo |
Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Jandor sí ìdílé Alhaji Adeniran àti olóògbé Ruth Oluwafunmilayo Adeniran ni ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1977 ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.[6] Jandor jẹ́ akékọ̀ọ́-gboyè láti ilé-ìwé gíga ti polytechnic ti ilú Ìbàdàn, Modul University, Vienna, Howard University School of Business, Washington DC, ní Orílẹ̀ èdè America àti Oxford University, United Kingdom .
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeJandor bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́-ìròyìn, tí ó sì jẹ́ akọ̀ròyìn fún bíi ogún ọdún. Ó padà wọ inú òṣèlú, ó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC. Òun ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbìmọ̀ ti Lagos4Lagos, ẹgbẹ́ kan lábẹ́ APC.[7] Níkẹyìn, ó padà lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ PDP, ó sì jẹ́ olùdíje ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó tó kọjá.[8][9][10]
Ayé rẹ̀
àtúnṣeMaryam Ọlajide Adediran ni ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì bí ọmọ méji; Fareedah Oluwamayokun Amoke àti Fadhilulah Oluwamurewa Adedayo Akanniade Olajide-Adediran.[11]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Olajide Adediran (Jandor): Biography, Wife, Children, Political Career, and Source of Wealth". NewswireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Jonathan, Oladayo (2022-07-13). "Lagos 2023: How Funke Akindele and I will defeat Sanwo-Olu, APC — PDP gov candidate - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Informant247, The (2022-07-13). "Olajide Adediran Jandor Net Worth, Biography, Age, PDP, Wiki". The Informant247 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Lagos4Lagos Visioner Jandor Wins PDP Guber Primary Election | Channels Television". www.channelstv.com. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Abdul-Azeez Olajide Adediran Biography and Detailed Profile". Politicians Data (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-06-05. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Olajide Adediran Jandor Biography, Net Worth, Age, Family, Wife" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Lagos4Lagos Movement fires chairman over alleged N100 million bribe from Tinubu". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-20. Archived from the original on 2022-07-27. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Olajide Adediran (Jandor): Biography, Wife, Children, Political Career, and Source of Wealth". NewswireNGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-13. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ "Adediran defeats Vaughn, emerges Lagos PDP gov candidate". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-26. Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Report, Agency (2022-05-26). "Jandor clinches PDP guber ticket in Lagos - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.
- ↑ Informant247, The (2022-07-13). "Olajide Adediran Jandor Net Worth, Biography, Age, PDP, Wiki". The Informant247 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-14.