Abdul-Lateef Adeniran Akanni

Àdàkọ:BLP sources

Oba Abdul-Lateef Adeniran Akanni, Obaarun-Oladekan I
Reign 2 May 2009 – 7 January 2022
Coronation 2 May 2009
Predecessor Jacob Ogabi Akapo
Successor Olusola Idris Osolo Otenibotemole II
Spouse

Olori Elizabeth Akanni

Issue
Prince Gbadebo Akanni

Prince Gbadero Akanni Princess Folashade Akanni Prince Adeleke Akanni

Full name
Abdul-Lateef Adeniran Akanni
House Aafin Olofin
Father Prince Ganiyu Bolaji Akanni
Mother Madam Adijatu Akanni
Born (1958-12-03)3 Oṣù Kejìlá 1958
Ado-Odo, Federation of Nigeria
Died 7 January 2022(2022-01-07) (ọmọ ọdún 63)


Oba Abdul-Lateef Adeniran Akanni, tí a tún mọ̀ sí Obaarun-Oladekan I (wọn bí lọ́jọ́ kẹta oṣù Kejìlá ọdún 1958, ó sì kú lọ́jọ́ keje oṣù kìíní ọdún 2022) jẹ́ ọba àlàyé ní Nigerian. Òun ni was the Ọba Ado àti Olofin Adimula Oodua ti Ado-Odo bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ ọba àwọn Yorùbá ti ìlú Ado-odò. Wọ́n fi i jọba Adó-odọ àti Olofin Adimula Oodua ti Ado-Odo lọ́jọ́ kejì oṣù karùn-ún ọdún 2009 pẹ̀lú orúkọ oyè Ojikutujoye Obaarun Oladekan I, ó jọba Oba J. O. Akapo, tó kú lọ́jọ́ keje oṣù kejì ọdún 1989.[1]

Kí ó tó d'ádé

àtúnṣe

Nígbà tí Ọba J. O. Akápò kú lọ́dún 1989, ó kan ìdílé ọba Ìdóbarun láti fa ọmọ oyè kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olọ́fin tuntun. Wọ́n kò rí ọmọ oyè yàn títí di ọdún 1993 tí wọ́n fi wá yàn Abdul-Lateef Adéníran Àkànní lọ́nà tí ó tọ́ àti lọ́nà tí ó yẹ. Lẹ́yìn èyí, ọmọ oyè mìíràn, tí ó jẹ́ ọmọ obìnrin ìdílé ìdóbárun náà nífẹ̀ẹ́ sí ìtẹ́ náà fa rògbòdìyàn tí ó mú wọn dé ilé-ẹjọ́. Wọ́n rojọ́ náà láti ilé-ẹjọ́ gíga títí dé ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ. Nígbẹ̀yìn, ilé-ẹjọ́ tó gajù lọ ní Nigeria dá Abdul-Lateef Adéníran Àkànní láàre, tí wọ́n sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ-oyè yányán lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2009 l.[2]

Ìfijoyè

àtúnṣe

Abdul-Lateef Adéníran Àkànní jọba lẹ́yìn Ọlọ́fin Agùnlóyè Jacob Ọ̀gábí Akápò lọ́jọ́ kejì oṣù karùn-ún ọdún 2009, nígbà ìjọba Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọ̀túnba Gbenga Daniel lẹ́yìn ogún ọdún tí ìtẹ́ náà tí ṣófo.[3][4][5][6][7][8][9] [10] [11]

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ó fẹ́ ìyàwó méjì, Olori Fausat Adébísí Àkànní, tí ó jẹ́ Olorì-àgbà, àti Elizabeth Àkànní .Àdàkọ:Cn

Bákan náà, ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn èré-ìdárayá, pàápàá jùlọ, bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá níbi tí ó ti múyán lórí gẹ́gẹ́ bíi alámójútó ìdíje ní ìlú Adó-odò àti Badagry. Kí ó tó di Ọlọ́fin, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, èyí ló jogún lọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀.[12]

Ọlọ́fin tí ìlú Adó-odò kú lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta lọ́jọ́ keje oṣù kìíní ọdún 2022 ní the Federal Medical Center Abẹ́òkúta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lẹ́yìn àárẹ̀ díẹ̀. Ó jọba Ọlọ́fin fún ọdún méjìlá àti oṣù mẹ́rin. Ìròyìn ikú tàn káàkiri Nigeria láàárọ́ ọjọ́ tó kú. Wọn dá òkú rẹ̀ padà sí ìlú Ado fún ayẹyẹ ìsìnkú gẹ́gẹ́ bí Mùsùlùmí.[13]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe