Olusola Idris Osolo
Oba Olusola Idris Osolo tí a tún mọ̀ sí (Otenibotemole II) Àdàkọ:Post-nominals (tí wọ́n bí lọ́jọ́ ketàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1988) ni ọba Adó-odò kọkànlélógójì àti Olofin Adimula Oodua ti Ado-Odo. Ó gorí ìtẹ́ lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kejì ọdún 2024 lẹ́yìn ikú ọba Abdul-Lateef Adeniran Akanni Ojikutujoye I tí ó jẹ́ Olofin Adimula Oodua ogójì ìlú Ado-Odo.[1]
Otenibotemole II Àdàkọ:Post-nominals | |
---|---|
Olofin Adimula Oodua
| |
Otenibotemole II | |
Reign | ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejì ọdún 2024Àdàkọ:Sndashpresent |
Coronation | Ọgbọ́n ọjọ́ oṣù kẹta ọdún 2024 |
Predecessor | Abdul-Lateef Adeniran Akanni Ojikutujoye I |
Spouse |
|
Issue | |
3 | |
Full name | |
Olusola Idris Adebowale Lamidi Osolo | |
House | Okewaye Ruling House |
Father | Late Musiliu Olatunji Lamidi |
Mother | Alhaja Azeezat Omolola Lamidi |
Born | 27 Oṣù Kẹjọ 1988 Ado-odo, Western State, Nigeria (now in Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nigeria) |
Ìran rẹ̀
àtúnṣeWọn bí Ọba Ọtẹ̀níbọ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ II ní ìdílé Ọ̀sọ́lọ̀ ti ìdílé ọba Okéwayè, ọkàn nínú àwọn ìdílé ọba mẹ́rin tí ó wà ní Adó-odò. Bàbá rẹ̀ tí ó ti kú, Músílíù Ọlátúnjí Lámídì ti ṣe igbákejì Ọ̀gá-ọlọ́pàá àgbà kí ó tó kú lóṣù kẹrin ọdún 1988, ó jẹ́ ìran Ọba Aṣádé Awòpẹ́ ti Ọtẹ̀níbọ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ tó jọba lọ́dún 1884 sí 1913.[2] Ìyá rẹ̀, Alhaja Azeezat Ọmọlọlá Lámídì (ọmọ Agbógunlórí), jẹ́ ènìyàn pàtàkì tí o ti jẹ oyè òtún ìyálọ́jà àti Ọ̀tún Ìyá Àdínnìn ti ilu Adó-odò.
Ìyànsípò àti ìgbà dé rẹ̀
àtúnṣeNí ìgbìyànjú láti yan ọmọ oyè tòótọ́ sípò In a bid to determine the rightful heir to the revered position of Ọlọ́fin Adìmúlà Oòduà, wọ́n yan Ọlọ́fin Olúṣọlá Ọsọ́lọ̀ sáàárín àwọn ọmọ oyè mẹ́rìnlá láti ìdílé oyè ọba Òkèwáyé ti Adó-odò tí àwọn náà lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtẹ́ ọba Adó-odò. Kọ́míṣánnà fún Ìjọba-ìbílẹ̀ àti ọ̀rọ̀ nípa oyè jíjẹ ní Ìpínlẹ̀ Ògùn àti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba-ìbílẹ̀ Adó-odò /Ọ̀tà, ṣe ìdìbò lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kejì ọdún 2024. Ìdìbò náà jẹ́ èyí tí kò ní èrú tí ó sì tẹ́lẹ̀ ìlànà òfin láìṣẹègbè fún ẹni kankan.[3][4]
Ó borí láàárín gbogbo àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó kó ìbò tó pọ̀jù àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ. Bíborí rẹ́ kì í ṣe iyì rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ìjẹ́rìí sí ìwà àti gbajúmọ̀ rẹ̀ àti bí ó ti ṣe ti máa ń dá sí ètò ìlú látẹ̀yìnwá. Àti bí ó ṣe mọ̀ nípa àṣà, ìṣe àti bí wọ́n ṣe ń darí ìlú náà l. Ó gbà ọ̀pá-àṣẹ lọ́jọ́ ọgbọ̀n, oṣù kẹta ọdún 2024.[5]
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeÌyàwó rẹ̀ ni Olorì Taheebat Ọmọtọ́lání Ọsọ́lọ̀, wọ́n bímọ mẹta.
Bákan náà, ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn eré-ìdárayá, pàápàá jù lọ, ó féràn ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́. Ó wà lára àwọn agbábọ́ọ̀lù-àfẹ́sẹ̀gbá, kódà, ó wà lára àwọn tó gbá ayò wọlé nígbà tí wọ́n gbá ìdíje aláfẹ́ kan tí wọ́n pè ní Adó-odò Legend, tí àwọn ọ̀dọ́ Adó-odò ṣètò lọ́dún 2023 ní pápá ìṣeré tó dára.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Excitement as Gov Abiodun presents staff of office to young monarch of ancient town". pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 30 March 2024. Retrieved 2024-03-30.
- ↑ "35-yr-old prince ascends his ancestor's throne 111 years after his progenitor's death". pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 28 February 2024. Retrieved 2024-02-28.
- ↑ "Lamidi-Osolo Elected as Olofin Adimula Odua of Ado Odo Kingdom". independent.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 February 2024. Retrieved 2024-02-10.
- ↑ "President Tinubu Congratulates Oba Olusola Lamidi–Osolo on Ascension to the Throne of Olofin of Ado–Odo". statehouse.gov.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-04-02. Retrieved 2024-03-31.
- ↑ "Abiodun presents staff of office to 35-year-old monarch". punchng.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 30 March 2024. Retrieved 2024-03-31.
- ↑ "Prince Idris Olusola Lamidi-Osolo Emerges As Elect Olofin Adimula Odua of Ado Odo Kingdom". octagonagentsofdevelopmentdirectory.com.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-10.