AbdulRahman AbdulRazaq
AbdulRahman AbdulRazaq (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1960) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà, ẹni tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara láti ọdun 2019.[1] Òun ni alága télèrí ilé-isé First Fuels Limited.[2] Ó dupò gómìnà ìpínlè Ìpínlẹ̀ Kwara ní 2003, 2007 àti 2011 lábé ẹgbẹ́ òsèlú Congress for Progressive Change ṣùgbọ́n ó fìdí rẹmi, Abubakar Bukola Saraki dé ipò náà ní ọdun 2003 àti 2007, tí Abdulfatah Ahmed sì dé ipò náà ní 2011.[3] Ní ọdun 2019, ó dupò náà lẹ́kan si lábé ẹgbẹ́ òsèlú tí ó wá ìjọba, ẹgbẹ́ òsèlú All Progressive Congress, ó sì jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bi gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara.[4] Ní 2021, ó dá KwaraLEARN kalẹ̀ ní ilé ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ láti ran àwọn ògá lọ́wọ́ nínú kíkó àwọn akẹ́kọ̀ọ́.[5]
Abdulrahman Abdulrazaq | |
---|---|
Governor of Kwara State | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 29 May 2019 | |
Deputy | Kayode Alabi |
Asíwájú | Abdulfatah Ahmed |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Kejì 1960 Zaria, Northern Region, British Nigeria (now in Kaduna State, Nigeria) |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress (APC) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olufolake Davies AbdulRazaq |
Website | "Abdulrahman AbdulRazaq" |
Ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí AbdulRahman ní Ilorin West Local Government.[3] Òun nìkan ni ọmọ ọkùnrin Alhaji A. G. F. AbdulRazaq SAN., agbejọ́rò àkókò ní àríwá Nàìjíríà[6]
Ó lọ ilé-ìwé Capital School, ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàrin 1966 and 1968; ó tún lọ ilé-ìwé Bishop Smith Memorial School Ilorin láàrin ọdún 1970 àti 1971; àti Government College Kaduna níbi tí ó ti gba ìwé ẹrí West African Senior School Certificate Examination (WASSCE) rẹ̀ ní ọdún 1976.[3][7]
Òṣèlú
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú òsèlú ní ọdún 1999 nígbà tí Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa n tiwa. Ní ọdún 2003 àti 2007, ó dupò Gómìnà ìpínlè Kwara lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Congress Progressive Change(CPC) ṣùgbọ́n ó fìdí remi[8] ó tún dupò náà lábé ẹgbẹ́ òsèlú People Democratic Party (PDP) ní ọdún 2011 àti 2015.[9] Ó jáwẹ́ olúborí nígbà tí ó dupò náà ní ẹ̀kan si lábé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress ni ọdún 2019.[10][8]
Ó búra wọlé sí ipò Gómìnà ìpínlè Kwara ní ọjọ́ kandínlọ́gbọ̀n oṣù Kàrún ọdún 2019.[11]
Ìdílé
àtúnṣeÌyàwó AbdulRahman ni Olufolake Molawa Davies Abdulrazaq[3] àwọn méjèèjì sì ní ọmọ mẹ́ta.[12]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "AbdulRazaq bags Governor of the year award - The Nation Newspaper". thenationonlineng.net. Retrieved 2022-03-05.
- ↑ "Hope rising for oil mandate, AbdualRahman AbdulRazak".[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 "Support AbdulRahman AbdulRazaq for Governor of Kwara". voteabdulrahman.com. Archived from the original on 2023-02-19. Retrieved 2023-02-19.
- ↑ "APC's Abdulrahman wins Kwara Governorship election". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-10. Retrieved 2020-03-30.
- ↑ "AbdulRazaq Introduces KwaraLEARN to Revolutionise Basic Education". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-11-04. Retrieved 2021-11-19.
- ↑ "Brief History About Kwara State APC Gubernatorial Candidate". Archived from the original on 2019-05-26. Retrieved 2023-02-19.
- ↑ "Certificate scandal: School mates clarify AbdulRahman AbdulRazaq". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-08. Retrieved 2020-03-30.
- ↑ 8.0 8.1 admin. "Real reasons Abdulrahman Abdulrazaq emerged Kwara APC guber candidate | National Pilot Newspaper" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-03-15.
- ↑ "ABDULRAZAQ ABDULRAHAMAN -The new man on the block in Kwara". Vanguard News Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-13. Retrieved 2019-03-15.
- ↑ "Supporters jubilate AbdulRahman Abdulrazak's early lead". The Informant247 News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-07. Retrieved 2020-02-21.
- ↑ "INEC Announces APC's Abdulrahaman Abdulrazaq the winner of Kwara Guber' Poll". The Informant247 News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-10. Retrieved 2020-02-21.
- ↑ "ICPC summons Kwara govs wife Olufolake 8 others over corruption allegations". News Diary. 2020-02-05. Archived from the original on 2021-03-03. https://web.archive.org/web/20210303140212/https://www.newsdiary.com.ng/2020/02/05/icpc-summons-kwara-govs-wife-olufolake-8-others-over-corruption-allegations/.