Abul Kalam Qasmi (20 December 1950 – 8 July 2021) fìgbà kan jẹ́ onímọ̀ orílẹ̀-èdè India, alárìísí, àti akéwì ní èdè Urdu, tó fígbà kan jẹ́ díìnì Faculty of Arts ní Aligarh Muslim University. Òun ni olóòtú ìwé Tehzeeb-ul-Akhlaq àti òǹkọ̀wé àwọn ìwé bí i The Criticism of Poetry. Ó ṣe ògbufọ̀ ìwé E. M. Forster, tí ń ṣe Aspects of the Novel sí èdè Urdu gẹ́gẹ́ bí i Novel ka Fun. Wọ́n fún n ní àmì-ẹ̀yẹ ti Sahitya Akademi Award ní ọdún 2009, àti Ghalib Award ní ọdún 2013.

Abul Kalam Qasmi
Born(1950-12-20)20 Oṣù Kejìlá 1950
Darbhanga, Bihar, India
Died8 July 2021(2021-07-08) (ọmọ ọdún 70)
Aligarh, Uttar Pradesh, India
Alma mater
Notable awards

Qasmi jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Darul Uloom Deoband, Jamia Millia Islamia àti the Aligarh Muslim University. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà ní ẹ̀ka èdè Urdu ní Aligarh Muslim University láàárín ọdún 1996 wọ ọdún 1999. Ó jẹ́ òpómúléró kan pàtàkì fún àríwísí èdè Urdu.

Ìtàn ìgbésíayé rẹ̀ àtúnṣe

Ọjọ́ ogún, oṣù kẹwàá, ọdún 1950 ni a bí Abul Kalam Qasmi ní ìlú Darbhanga, Bihar.[1] Ó gboyè ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Qāsim al-Ulūm Hussainiya, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní dars-e-nizami láti Darul Uloom Deoband ní ọdún 1967.[1] Ó lọ sí ilé-ìwé Jamia Millia Islamia láti tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gboyè B.A. àti M.A. ní Aligarh Muslim University (AMU) ní ọdún 1973 àti 1975 bákan náà.[1] Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni Anzar Shah Kashmiri.[2]

Qasmi di olùkọ́ ní ìlé-ìwé AMU ní ọdún 1976, wọ́n sì yàn án gẹ́gẹ́ bí i akàwé ní ọdún 1984, ìyẹn ọdún kan náà tí ó ghoyè ẹ̀kọ́ PhD.[1] Ó ṣe àtòpọ̀ ìwé ẹ̀kọ́ fún ilé-ìwé gíga rẹ̀ ní ẹ̀ka èdè Urdu ní ọdun 1980.[1] Ní ọdún 1993, wọ́n yàn án láti jẹ́ ọ̀jọ́gbọ́n ẹ̀kọ́ comparative literature.[1] Ó jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn Aligarh láàárín ọdún 1975 àti 1976, ọ́ sì tún jé olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn Alfāz, Aligarh láti ọdún 1976 wọ ọdún 1980. láàárín ọdún 1983 àti 1985, ó tún jẹ́ olóòtú-àgbà fún ìwé ìròyìn Inkār, Aligarh. Ní ọdún 1996, ó di olóòtú fún ìwé ìròyìn Tehzeeb-ul-Akhlaq.[3] Ó jé ọ̀kan lára àọwọn ọmọ ẹgbẹ́ National Council for Promotion of Urdu Language láti ọdún 1998 wọ 2003.[4] Láti ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 1996 wọ ọjọ́ karùn-úndínlógún, oṣú kẹfà, ọdún 1999, òun ni ọ̀jọ̀gbọ́n-àgbà fún ilé-ìwé AMU, ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè Urdu.[5] Ó tún fìgbà kan jẹ́ díìnì ilé-ìwé AMU Faculty of Arts.[6] Mujawir Husain Rizvi, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè Urdu fún lítírésọ̀ Urdu ní University of Allahabad nígbá náà, máa ń pè é ní "bàbá fún gègé ìkọ̀wé" (Abul Qalam), fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀[7]

Wọ́n rí Qasmi gẹ́gẹ́ bí i ògbóǹtarìgì àti òpómúléró kan pàtàkì alárìíwísí èdè Urdu láti Gopi Chand Narang àti Shamsur Rahman Faruqi.[8] He received the Bihar Urdu Academy Award in 1980, and the Uttar Pradesh Urdu Academy Award in 1987 and 1993.[4] He was conferred with the Sahitya Akademi Award in 2009 for his book Mu'āsir Tanqīdi Rawayye.[8] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Ghalib Award ní ọdún 2013.[9] Ó di olóògbé ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún 2021 ní ìlú Aligarh.[6] Tariq Mansoor fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn, ò sì sọ ọ́ di mímọ̀ pé òǹkọ̀wé kan tó lààmìlaaka ni orílẹ̀-èdè India ti pàdánú.[10]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Qāsmi ṣe ògbufọ̀ ìwé E. M. Forster tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Aspects of the Novel sí èdè Urdu gẹ́gé bí i Novel ka Fun.[11]Òun ni òǹkọ̀wé àwọn ìwé bí i Kas̲rat-i Taʻbīr, Mashriqi She'riyāt aur Urdu Tanqīd ki Riwāyat, Mu'āsir Tanqīdī Rawayye, Shā'iri ki Tanqīd (The Criticism of Poetry) àti Takhlīqi Tajruba.[11][12] Ní ọdún 2010 Qāsmi tí ní tó àwọn àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí tó ń lọ bí i márùn-únléláàágọ̀fà (125).[13] Àwọn àtòjọ iṣẹ́ rẹ̀ ni:[11][12]

  • Azādī ke baʻd Urdū Tanz-o-Mizāḥ
  • Mashriq kī Bāzyāft: Muḥammad Ḥasan ʻAskarī ke ḥavāle se (The Recovery of the East, with Reference to Muhammad Hasan Askari)
  • Rashīd Aḥmad Ṣiddīqī, Shak̲h̲ṣīyat aur Adabī Aadr-o- Qīmat (Rasheed Ahmad Siddiqui, Life and His Literary Importance)
  • Mirzā G̲h̲ālib: Shak̲h̲ṣiyat aur Shāʻirī (Mirza Ghalib: Personality and Poetry)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

Citations àtúnṣe

Bibliography àtúnṣe

  • Sadaf, Mushtaq Ahmad (June 2006) (in ur). Abul Kalām Qāsmi: Shakhsiyat awr Adbi khidmāt. New Delhi: Kitab Numa. OCLC 72871627. 
  • Qasmi, Nayab Hasan (2013) (in ur). Darul Uloom Deoband Ka Sahafati ManzarNama. Deoband: Idara Tehqeeq-e-Islami. pp. 237–240. 

Tún ka àtúnṣe